Ẹni tí kò bá tì lè kópa nínú ìṣẹ̀ṣe kò yẹ nípò ọba Yorùbá - Ọba Yakoyo

Olulamokun ìlú Yakoyo, Oba Oyewole Oyediran

Oríṣun àwòrán, Oba Oyewole Oyediran/X

Olulamokun ti ìlú Yakoyo ní ìpínlẹ̀ Osun, Ọba Meshach Oyewole Oyediran ti ní gbogbo ẹni tó bá ti gbà láti jẹ oyè ọba ní Nàìjíríà yàlá ẹlẹ́sìn mùsùlùmí tàbí kírísítẹ́ẹ̀nì gbọ́dọ̀ mọ̀ wí pé òun máa ṣe àwọn ojúṣe òun gẹ́gẹ́ bí ọba Yorùbá.

Ọba Oyediran nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ́rọ̀ ní kíkópa nínú àwọn ọdún ìṣẹ̀ṣe jẹ́ ojúṣe tí ọba Yorùbá gbọ́dọ̀ ṣe.

Ọba alayé náà ní gbogbo ìlú ní ilẹ̀ Yorùbá ló ní ìṣẹ̀ṣe tí wọ́n fi da sílẹ̀, nítorí náà gbogbo àwọn ọba, láì fi ẹ̀sìn ṣe gbọ́dọ̀ bọ̀wọ̀ fún àṣà àti ìṣe ilẹ̀ wọn.

Ó tẹmpẹlẹmọ pé Ifá ló máa ń yan ọba ní ilẹ̀ Yorùbá, bó ṣe wòye pé jíjẹ onígbàgbọ́ òdodo tàbí mùsùlùmí òdodo kò yẹ kó jẹ́ ìpèníjà fún àwọn ọba láti máa ṣe àtìlẹyìn fún ọdún àṣà àti ìṣẹ̀ṣe ilẹ̀ wọn.

“Kò sí ohun tó burú nínú kí ẹlẹ́sìn ìgbàgbọ́ tàbí mùsùlùmí di ọba ìlú àmọ́ ó ní nígbà tí èèyàn bá ti gbà láti jọba ni ó yẹ kí onítọ̀hún ti kọ́kọ́ gba àdúrà sí Ọlọ́run kó sì ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ọdún ìṣẹ̀ṣe tí wọ́n bá ń ṣe ní ìlú náà.

“Ẹni tó bá ti jọba nílẹ̀ Yorùbá gbọ́dọ̀ mọ̀ pé òun máa ṣe àwọn ojúṣe tó rọ̀ mọ́ ipò rẹ̀ tó fi mọ́ kíkópa nínú àwọn ọdún ìṣẹ̀ṣe.”

Ó ṣàlàyé pé ọ̀pọ̀ ọdún ni wọ́n ń ṣe ní ìlú Yakoyo bíi Orò, Egúngún àti bíbọ Ọ̀ṣun àti pé bí òun ṣe jẹ́ ẹlẹ́sìn onígbàgbọ́, òun kò lè dá àwọn tó ń ṣe ọdún náà dúró nítorí ọ̀pọ̀ ìṣẹ̀ṣe náà lọ ti wà kí wọ́n tóbí òun.

“Mo máa ń sọ fún wọn nígbà tí wọ́n bá fẹ́ ṣe àwọn ọdún yìí pé ní wọ̀n ìgbà tí mo bá ṣì jẹ́ ọba ìlú yìí, mo gbọ́dọ̀ ṣe àtìlẹyìn fún wọn.

“Wọ́n máa ń wá sí ààfin fún àdúrà, mo máa ṣàdúrà fún wọn, mà á tún fún wọn ní owó. Bí mo ṣe ń ṣètò ìjọba tèmi níbi nìyẹn.”

Ó fi kun ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé bí àwọn ẹlẹ́sìn ìgbàgbọ́ àti mùsùlùmí náà ṣe gbàgbọ́ nínú Ọlọ́run náà ni àwọn oníṣèṣe gbàgbọ́ Ọlọ́run tí wọ́n sì máa ń gba àdúrà si.

Ó tẹ̀síwájú pé ọba tí kò bá lè tẹ̀lé àwọn oníṣẹ̀ṣe lọ sídìí òrìṣà tàbí ojúbọ wọn nílò láti máa ṣe àtìlẹyìn fún wọn kí àláfíànle jọba ní ìlú.

“Kí ẹnikẹ́ni tó lè jọba, Ifá ni wọ́n máa gbé janlẹ̀, kìí ṣe ṣọ́ọ̀ṣì tàbí mọ́ṣáláṣí ni wọ́n máa ń lọ. Ìránṣẹ́ Ọlọ́run ni Ifá, ẹni tó bá sì yàn fún àwọn afọbajẹ ni wọ́n máa yàn sípò."