Ilé ẹjọ́ tó ń gbọ́ awuyewuye lórí ètò ìdìbò ní Ododo àti Diri ló wọlé ìbò gómìnà ní Kogi àti Bayelsa

Aworan Gomina Diri ati Gomina Ododo

Oríṣun àwòrán, Others

Ileẹjọ to n gbọ awuyeawuye lori ọrọ idibo nipinlẹ Kogi ati Bayelsa ti fi ontẹ lu eto idibo to gbe Usman Ododo ati Dounye Diri gẹgẹ bii ẹni to bori ninu eto idibo Gomina nipinlẹ Kogi ati Bayelsa.

Ileẹjọ nipinlẹ Kogi ni oludije sipo labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progress Congress lo jawe olubori, to si wọgile ipe Muritala Ajaka ti ẹgbẹ oṣelu Social Democratic Party.

Igbimọ ẹlẹni mẹta ti Adajọ Ado Birnin-Kudu lewaju fun ni ẹgbẹ oṣelu SDP ati oludije wọn kọ lati fi ẹri le lẹ pe otitọ ni pe magomago waye.

Adajọ BirninKudu ni eto idibo naa waye ni ilana ti ofin gbe kalẹ.

Ajọ eleto idibo lorilẹede Naijiria, INEC kede Ododo, oludije ẹgbẹ oṣelu APC gẹgẹ bii Gomina lẹyin eto idibo Gomina to waye ni oṣu kọkanla ọdun 2023.

Apapọ ibo to jẹ 446,237 ni Ododo fi na Ajaka, ẹni to ni apapọ ibo 259,052.

Dino Melaye ti ẹgbẹ oṣelu PDP ni apapọ ibo to jẹ 46,362.

Bakan naa nipinlẹ Bayelsa, ileẹjọ to n gbọ awuyewuye lori eto idibo fi ontẹ lu Gomina Douye Diri gẹgẹ bii Gomina ipinlẹ Bayelsa.

Adajọ Adekunle Adeleye to lewaju igbimọ ẹlẹni mẹta naa wogile ipe ẹgbẹ oṣelu APC ati oludije rẹ, Timipre Sylva.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, ileẹjọ ni awọn olupẹjọ kọ lati fi ẹri kalẹ pe magomago wa ninu esi eto idibo naa.

Ile ẹjọ ni ẹjọ ti APC ati oludije rẹ gbe wa siwaju ile ẹjọ ni ko koju osuwọn to pẹlu gbogbo ẹri ati awọn ẹlẹrii pata.

Bakan naa ni ile ẹjẹo tun wogile ẹjọ to ni ayederu iwe ẹri fasiti ati ayederu iwe ẹri agunbanirọ ni igbakeji Gomina, Lawrence Ewhrudjakpo fi kalẹ fun ajọ eleto idibo to fi ni anfani lati le jade dupo.

Ileẹjọ ni iṣẹlẹ nipa ayederu iwe ẹri lo jẹ awọn iṣẹlẹ to ti waye saaju eto idibo, ti o si yẹ ki wọn gbe lọ siwaju ile ẹjọ giga