Èèyàn mẹ́ta jóná kú nínú ìjàmbá ọkọ̀ tó wáyé l’Eko

Aworan ijamba ọkọ to waye ni opopona Oshodi-Apapa

Oríṣun àwòrán, LASEMA

Iṣẹlẹ ibanujẹ yii waye ni ọjọ Aiku nigba ti awakọ ọkọ ayọkẹlẹ Mercedes Benz SUV kan ti gende kunrin mẹta wa ninu rẹ kọlu ọkọ ajagbe kan.

Eeyan mẹta to wa ni ninu ọkọ ayọkẹlẹ naa ni wọn jona kọja ala .

Isẹlẹ naa waye ni agbegbe Mandilas, Iyana Isolo lopoona marose Oshodi-Apapa.

Ọkunrin kan, AbdulFatia Wasiu, ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ ṣalaye fun awọn akọroyin pe, ijamba naa waye nitori ere asapajude ti awakọ ayọkẹlẹ naa sa to fi lọ kọlu ọkọ ajagbe naa.

Aworan

Oríṣun àwòrán, LASEMA

Akọwe agba fun ajọ to n risi iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Eko, Femi Oke Osanyitolu fidi iṣẹlẹ naa mulẹ.

“Nnkan bi ago mọkanla kọja ọgbọn iṣeju ni a de si ibi iṣẹlẹ naa, ti a si ri iṣẹlẹ ijamba ọkọ to waye.

“Iwadii wa fihan pe ere abadi ni ọkọ ayọkẹlẹ naa n saa lo jẹ ko lọ kọlu ọkọ nla.

“Ki kọlu to kọju ọkọ nla to jẹ ki ina sẹyọ,” Oke-Osanyitolu ṣalaye.

O ni oku awọn oloogbe naa ni ajọ to n ri si ayika SEHMU ti gbe lọ si ile igbe oku si.

Aworan

Oríṣun àwòrán, LASEMA