Àwọn jàǹdùkú ya bo àgọ́ ọlọ́pàá l’Eko, iléṣẹ́ ọlọ́pàá ní àwọn ọlọ́kadà ló wà nídí ẹ̀

Oríṣun àwòrán, screenshot
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti sọ pe awọn ọlọkada lo ya bo ago ọlọpaa kan ni agbegbe Ipaja ni ilu Eko ti wọn si gbiyanju ati gba ijọba ni agọ ọlọpaa naa.
Ọrọ di boo lọ yago lọjọ Aje nigba ti awọn janduku kan kọlu ileeṣẹ ọlọpaa kan to wa lagbegbe Ipaja nilu Eko.
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe awọn janduku to le ni ọgọrun ya bo agọ ọlọpaa pẹlu awọn nnkan ija oloro loriṣiriṣi lati kọlu awọn ọlọpaa to wa nibẹ.
A gbọ pe nṣe ni iro ibọn n dun lakọ-lakọ lasiko naa, eyi to ko ibẹrubojo sọkan awọn ara agbegbe ọhun, to si mu ki awọn eeyan sa asala fun ẹmi ara wọn nipa nina papa bora.

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Bi awọn tọọgi ọhun ṣe ya bo ẹnu ọna abawọle teṣan yii ni wọn lawọn ọlọpaa ti sare ranṣẹ fun aabo lati ọdọ awọn ọga wọn.
Ko si pẹ rara ti wọn ni awọn ọlọpaa lati teṣan miran kaakiri fi sare debẹ lọpọ yanturu lati le awọn tọọgi naa danu.
A gbọ pe bi awọn ọlọpaa ṣe debẹ, ni awọn naa ti dabọn bọlẹ lati fi le awọn tọọgi yii danu.
Bo tilẹ jẹ pẹ titi di asiko yii ni a ko tii le fidi iye awọn to ku nibi ikọlu ọhun mulẹ, ṣugbọn sibẹ a gbọ pe diẹ lara awọn tọọgi ti ibọn ba ku loju ẹsẹ ti awọn miran si farapa yannayanna.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fun BBC YORUBA, agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin sọ pe otitọ ni ikọlu naa waye.
Bo tilẹ jẹ pe ko ṣalaye ohun to ṣẹlẹ lẹkunrẹrẹ fun BBC, sibẹ, Hundeyin sọ pe awọn ọlọkada lo da wahala ọhun silẹ.
Bẹẹ lo fi kun ọrọ rẹ wi pe gbogbo wahala naa lo ti lọ silẹ pẹlu iranlọwọ awọn ọlọpaa to lọ lati daabo bo awọn ọlọpaa ẹgbẹ wọn ati araalu.















