Àlá témi àti ìyàwó mi lá nípa Nàìjíríà wà lára ìdí tí a fi jápa lọ sí Amẹ́ríkà - Sam Adeyemi

Aworan Sam Adeyemi ati iyawo rẹ

Oríṣun àwòrán, Sam Adeyemi/Instagram

Oludasilẹ ile ijọsin Daystar Christian Centre, Sam Adeyemi ti ṣalaye idi to fi kuro lorilẹede Naijiria lọ orilẹede Amẹrika.

O ṣalaye ni kikun nigba to n ṣe ifọrọwerọ pẹlu Seun Okinbaloye nibi ti wọn ti sọrọ nipa ipa to yẹ ki awọn ọdọ ko ninu idagbasoke orilẹede Naijiria.

Adeyemi ni ohun ṣokunfa bi oun ṣe kuro lorilẹede Naijiria ni itankalẹ aarun Korona, iwọde Endsars ati awọn ala to la nipa Naijiria.

“Nigba ti Korona bẹrẹ, gbogbo awọn ọmọ wa wa ni Amẹrika, ti onikaluku si wa pẹlu mọlẹbi wọn.

“A duro ti awọn ọmọ wa. Ọsẹ ti ijọsin bẹrẹ pada ni iwọde Endsars waye, ti a si gbaradi lati pada si Naijiria.

“Iyawo mi ni ala pe o rin irinajo lọ si Naijiria, to si tun pada si Amẹrika, eti to jẹ ala buruku. Mo sọ fun un pe n ko le sọ pe mo nifẹ ala naa.

“Lẹyin ọjọ mẹta, mo ni ala. A jọ rin irinajo lọ Naijiria ninu ala naa, ti mo si kopa ninu ija nla kan.

“Wọn kọlu mi, ti mo si ni lati bere lọwọ Ẹmi mimọ ninu ọkan mi pe ki ni ki n ṣe.

“O sọ fun mi pe ki n pe orukọ Jesu. Mo pariwo orukọ Jesu ninu ala, ti oun ko si mọ pe mo pariwo loju aye gan.”

Adeyemi ni igbakugba ti oun ati iyawo ba ti fẹ wa si orilẹede Naijiria, yoo ma ni awọn alakala.

Aworan Sam Adeyemi ati iyawo rẹ

Oríṣun àwòrán, Sam Adeyemi/Facebook

“Iyawo mi ji mi ago meji ooru pe ki lo n sẹlẹ. Igba naa la wa pinnu pe a mojuto ohun to n sẹlẹ paapa nipa ala ti a ni tẹlẹ.

A bẹrẹ si ni gba adura, ti a si n kefin ewu. Lẹyin wakati mẹta, mo sun pada ti mo si tun la ala, pe a wa ni Naijiria,ti mo wa ninu ija.

“Lẹyin ọjọ diẹ, a ransẹ si awọn mọlẹbi wa ni Naijiria, ti pupọ wọn si ni o ṣe awọn bakan pe a n bọ wa si Naijiria.

“Ni bayii, ti Ọlọrun ba n bami sọrọ, mo ni lati mọ pe Ọlọrun n bami sọrọ.”