Ọkọ̀ tó ń bọ̀ láti ètò ìsìnkú yà bàrá sínú igbó, èèyàn 25 jáde láyé

Awọn oṣiṣẹ iṣẹlẹ pajawiri

Oríṣun àwòrán, Ministry of Health Kenya

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Eeyan marundinlọgbọn lo ti jade laye lẹyin ti bọọsi kan to ko awọn abanikẹdun lati ibi eto isinku kan ti dojude ni iha iwọ oorun Kenya.

Asiko ti wọn n bọ lati ibi eto isinku naa ni ọkọ ja ara rẹ gba lọwọ awakọ to si kuro loju popo ko to ja sinu koto kan loju ọna marosẹ Kisumu si Kakamega.

Akọsilẹ ọlọpaa kan ti BBC foju ri fi han pe lọpọ igba ni ijamba ọkọ maa n waye lagbegbe naa.

Ọlọpaa sọ pe obinrin mẹwaa, ọkunrin mẹwaa ati ọmọdebinrin kan lo ku lẹṣekẹsẹ nigba ti ogun eeyan mii farapa, ninu eyii ti marun un wa ni ẹsẹ kan aye ẹsẹ kan ọrun.

Ile iwosan ni awọn mẹrin mii ti pada dagbere faye.

Iroyin ni iboji ti wọn sin oku kan si lawọn eeyan naa ti n bọ, ti gbogbo wọn si jẹ eeyan inu mọlẹbi kan naa.

Ọlọpaa ni awọn ko tii le sọ ohun to ṣokunfa ijamba naa lasiko yii.

Ọkọ awọn akẹkọọ ile ẹkọ kan ni ọkọ ti ijamba naa kan amọ ko si akẹkọọ kankan ninu rẹ nigba ti ijamba baa waye.

Ilu Nyahera ni ọkọ naa ti n rinrinajo lọ siluu Nyakach to jẹ nnkan bii kilomita mejilelọgọta ṣaaju iṣẹlẹ ọhun.

Lẹyin iṣẹlẹ naa ni ileeṣẹ eto ilera Kenya ke si awọn araalu lati wa da ẹjẹ jọ fun awọn ti ijamba ọhun pa lara, lẹyin naa lo ba awọn ti ọrọ naa kan kẹdun.

Ileeṣẹ ọhun tun ke si awọn awakọ ki wọn maa ṣe jẹjẹ loju popo latari oniruru ijamba ọkọ to n waye lẹnu lọlọ yii.

Aarẹ William Ruto ti pe fun iwadii lori awọn to ṣeeṣe ki iwa aibikita wọn yọri si ijamba ọkọ naa, o tun ke si araalu lati maa tẹle gbogbo ofin irinna oju popo.

Ileeṣẹ to n ri si eto irinna oju popo nibẹ ti sọ pe oun yoo ṣe iwadii ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ naa.

Ijamba ọkọ yii lo n waye lẹyin ti ọkọ baalu ajọ eto ilera ti kii ṣe ti ijọba kan ja lulẹ niluu Nairobilọsẹ to kọja.

Eeyan mẹfa lo ba ijmaba ọkọ ofurufu naa lọ.