Bàbá kú nígbà tó gbọ́ pé wọ́n fún ọmọ rẹ̀ ní májèlé nítorí àgbàdo tó jí l'Osun

Oríṣun àwòrán, Others
Ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Ebenezer Ayeni ni oun padanu baba oun lẹyin to gbọ pe agba oye kan fun oun ni majele jẹ nitori o ya agbado meji jẹ ninu oko.
Ayẹni sọ fun BBC pe ebi lo n pa ọmọ ati iyawo rẹ, ni o ṣe yaa agbado meji ti ọmọ ati iyawo yoo jẹ.
Ni agbegbe Ireti-Ayo niluu Ilesa ni Oloye Gbenga Ajibade, to Ayeni Ebenezer majele n gbe.
Ayeni ba BBC News Yoruba sọrọ lori Isẹlẹ naa, pe ọjọ Kẹtala osu Keje ọdun 2025 yii ni Isẹlẹ naa sẹlẹ si oun.
O ni ile ti oun n gbe tẹlẹ ni o dawo ti oun si lọ gba ile miran.
O fikun pe oun lọ gbe ẹru oun to ku nibi ile ti oun n gbe tẹlẹ ni oun ba ri agbado lẹgbẹ oju ọna, bi oun ṣe yaa meji nibi agbado naa
"Bi mo ṣe ya agbado jẹ tan ni awọn ara adugbo ya bo mi, ti wọn si ri agbado lọwọ mi.
"Eleyi lo mu awọn ara adugbo naa lọ pe Oloye Gbenga Ajibade jade ẹni to ni oko agbado ti mo yaa meji ni bẹ.
"Nigba ti Oloye Ajibade ri mi lo sọ fun awọn ara adugbo wi pe, ki wọn fa oun le lọwọ.
"Lẹyin naa ni Oloye Ajibade wọ inu ile rẹ to si gbe ogun ti wọn mọ fí pa oko jade ati ada lọwọ rẹ, to si sọ fun mi pe ki mu ogun oko naa ti mo si mu lamu yo."
Arakurin Ebenezer, sọ wi pe, lẹyin naa ni Oloye Ajibade ni ki oun ko mọ lọ, o si gba agbado meji naa pada lọwọ oun. Sugbọn ki oun to de ile ni inu oun ko ti ní alaafia mọ rara.
O ni bi iyawo oun ṣe ri oun lo sare pade oun ti oun si ṣalaye ohun to sẹlẹ fun. Bẹẹ ni iyawo oun sare n gbe oun lọ si ile iwosan. Eyi lo jẹ oun ti oun mọ. Lẹyin ọjọ kẹta ni oun to mọ ohun n to sẹlẹ.
Arakurin Ebenezer, ní bi baba oun ṣe gbọ Isẹlẹ naa wi pe oloye Ajibade ti fun oun ni mọjele jẹ, ni baba oun subu lulẹ to sì gba ibẹ di ero ọrun, eyi to mu ki iya rẹ di opo ọsan gangan bayii.
BBC News Yoruba ba iyawo Ebenezer sọrọ lori iru eeyan ti ọkọ rẹ jẹ.

Arabirin Abiola Ayeni to jẹ iyawo si Ayeni Ebenezer, sọ wi pe, lati igba ti oun ti mọ ọkọ oun ki huwa ole tabi iwa buruku kankan rara.
Arabirin Abiola, salaye pe, otitọ ni pe ebi lo pa oun ati ọmọ oun ni ọjọ naa ti ko si si owo kankan lọwọ oun ati ọkọ oun lati le fi ra ikan jẹ nitori gbogbo owo ti oun ati ọkọ oun ni, ni awọn fi gba yara kan ti awọn sẹsẹ gba si adugbo ireti ayo niluu Ilesa.
Arabirin Abiola, ni Isẹlẹ jẹ ohun ibanujẹ fun oun latari wi pe, Isẹlẹ naa lo gba ẹmi baba ọkọ oun. Nitori Isẹlẹ yii yoo wa ninu iwe itan ẹbi ọkọ oun wi pe, wahala ọkọ oun lo pa baba rẹ.
Arakurin Ebenezer ati iyawo rẹ wa bere fun idajọ ododo lori ohun ti Oloye Gbenga Ajibade ṣe.
Ileesẹ Ọlọpaa Osun fidi iṣẹlẹ naa mulẹ.
Agbẹnusọ Ileesẹ Ọlọọpa ipinlẹ Osun, Abiodun Ojelabi, ni pe ki se wi pe ẹnikan lo mu Isẹlẹ naa wa fun awọn, ṣugbọn awọn ṣawari rẹ ninu fidio kan to wa lori ayelujara ni awọn, ti awọn si bẹrẹ lati ṣe iwadi lati le ri oloye Gbenga Ajibade ati Ebenezer.
Arakurin Abiọdun Ọjẹlabi ̣ṣalaye pe ṣe ni Oloye Ajibade, ẹni ọdun mejilelọgọta ka Ebenezer, ẹni ọdun marundinlọgbọn mọ inu oko rẹ nibi to ti ji agbado meji yaa.
O ni lẹyin ti baba yii lu Ebenezer tan lo tun fun un ni ogun ti wọn mọ fi pa oko mu, gẹgẹ bii gbogbo eeyan ṣe mọ pe awọn ogun oko naa ni o jẹ mọjele, ṣugbọn nigba ti ọmọ yii pada de ile wọn lawọn araadugbo sare gbe e lọ si ile iwosan, ti awọn dokita si tete ba agbara mọjele naa jẹ lara rẹ.
Ọjẹlabi sọ siwaju pe bi iroyin ṣe de ọdọ baba to bi Ebenezer pe wọn ti fun ọmọ rẹ ni majele mu nibi to ti lọ ji agbado yaa, bi baba náà ṣe jadi mọlẹ o si gbabẹ ku.
O sọ siwaju pe ọwọ awọn ti tẹ oloye Ajibade bayii, o si ti wa ni kolo awọn ati wi pe, o si ti n ran awọn Ọlọọpa lọwọ ninu iwadi wọn.
Bakan naa ni Ebenezer ti gba itọju tan nile iwosan o si ti pada de ile. Sugbọn awọn yoo iransẹ si bi ara rẹ ba ti le daada lati bere irinajo Isẹlẹ naa.















