Bàálù já lulẹ̀, dókítà, Nọ́ọ̀sì pẹ̀lú òṣìṣẹ́ elétò ìlera mẹ́fà kú, èèyàn méjì farapa

Aworan iṣẹlẹ ijamba to waye lorilẹede Kenya

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Eeyan mẹfa ti padanu ẹmi wọn ninu iṣẹlẹ ijamba ọkọ ofurufu to n gbe awọn eleto ilera ni olu ilu Kenya.

Ajọ Charity Amref Flying Doctors ni baalu Cessna gbera lati paapa ofurufu Wilson lọjọbọ, ti wọn si n morile Hargeisa ni orilẹede Somalia nigba to ja lulẹ, to si gba ina ni ile kan to wa ni Githurai ni Nairobi.

Kọmisana fún àgbègbè Kiambu County, Henry Wafula ni eeyan mẹfa lo padanu ẹmi wọn ninu baalu, to fi mọ́ awọn dokita, nọọsi ati awakọ baalu, pẹlu eeyan meji to kọwọrin – eeyan meji tun farapa yanayana.

Awọn oniwadii ni wọn ti fi wọn ransẹ si ibi ti iṣẹlẹ naa ti wáyé lati mọ ohun to ṣokunfa ijamba naa.

Baalu ọhun padanu redio laarin isẹju mẹta to gbera ni paapa, ajọ to n risi eto irinna òfurufú salaye.

Awọn oṣiṣẹ awakọ baalu mẹrin ati oṣiṣẹ Amref lo wa ninu baalu, ajọ to n pese iranlọwọ ṣalaye.

"Ni akoko yii, a n ṣiṣẹ papọ pẹlu ajọ to n risi irinna ofurufu," Ọga agba Stephen Gitau ninu atẹjade to fi lede fun awọn akọroyin.

Ajọ eleto aabo lorilẹede Kenya ati ileeṣẹ ọlọpaa ti balẹ sibi ti iṣẹlẹ naa ti waye lati ṣawari ohun to ṣokunfa ijamba.

Èèyàn mẹ́rin míràn kú bí ọkọ̀ akérò ṣe kọlu Reluwe ní Kenya

Oṣojumikoro, Patricia Kombo, sọ fun BBC pe oun wa ninu ọkọ pẹlu awọn ọrẹ òun, ti wọn n morile Githurai nigba ti awọn gbọ ariwo nla ati ina niwaju wọn.

"Ki n to mu foonu mi jade, ibugbamu naa ti walẹ, ṣugbọn eefin wa loke.

A gbọ ariwo, ti awọn eeyan n saare, ti a si fopin si irinajo wa.

"A ri pe ibugbamu ọkọ ofurufu lo waye, ti eefin si gba gbogbo ilẹ," o sọ

Ninu iṣẹlẹ miiran, ọkọ akero kan kọlu ọkọ reluwe to n kọja ni agbegbe Naivasha, ni arin orilẹede Kenya, to si ṣekupa eeyan mẹrin, ileeṣẹ iroyin Reuters lo gbe sita.

Ileeṣẹ Pineline lorilẹede Kenya, to ni ọkọ akero naa ni ọkọ n gbe awọn oṣiṣẹ wọn to ṣiṣẹ ni owurọ lọ sibi idanilẹkọ kan lasiko ti iṣẹlẹ naa waye, to si ni gbogbo awọn to farapa lo ti w ani ile iwosan ti wọn gba itọju.