Olubadan ti ilẹ̀ Ibadan, Ọba Owolabi Olakulehin ti wọ káà ilẹ̀ sùn

Ọba Owolabi Olakulehin, Olubadan ti ilẹ Ibadan, ti wọ kaa ilẹ lọ.
Ọjọ Ẹti ni eto isinku naa waye ni ile ijọsin St. Peter Cathedral, Aremo, niluu Ibadan.
Ṣaaju ni eto kikọ orin onigbagbọ ti waye lọjọbọ niluu Ibadan fun Ọba Owolabi Olakulehin, Olubadan.
Lati igba ti ọba alaye naa ti waja, ni awọn ẹbi, ara, ọrẹ ati ojulumọ ti n kora jọ lati ṣe ẹyẹ ikẹyin fun Olubadan kẹtalelogoji to waja naa.
Lara awọn to wa nibi isinku naa ni gomina ipinlẹ Oyo bii Seyi Makinde, Igbakeji Gomina; Adebayọ Lawal, Akọwe ijọba ipinlẹ Ọyọ; Ọjọgbọn Olanike Adeyemo ati awọn aṣoju ileeṣẹ Ologun orilẹede Naijiria naa lo ti wa nikalẹ.
Awọn aṣoju lati ileeṣẹ ologun Naijiria si lo ṣe amojuto eto isinku naa, idi si ni pe Ajagunfẹyinti ni Ọba Ọlakulẹhin nigba aye rẹ.

Ọba Owolabi Ọlakulẹhin papoda lọjọ keje, oṣu Keje ọdun 2025, lẹyin to ṣe akoso ilẹ Ibadan gẹgẹ bii Olubadan ikẹtalelogoji fun ọdun kan ati ọjọ diẹ.
Lẹyin naa si ni igbimọ afọbajẹ Olubadan kede gomina tẹlẹri n'ipinlẹ Ọyọ, Sẹnetọ Rashidi Ladọja gẹgẹ bii Olubadan ikẹrinlelogoji.
Nigba ti eto isinku Olubadan ana ba pari ni ijọba ipinlẹ Ọyọ yoo kede ọjọ iwuye fun Olubadan tuntun.
Àwọn ọlọ́jà ti ọjà pa láti bu ọlá fún Olubadan tó wàjà


Lati bu ọla fun Ọba Owolabi ti isinku rẹ n waye lonii, ẹgbẹ awọn ọlọja nilẹ Ibadan ti kede pe ọja yoo jẹ titi pa lati bu ọla fun ọba ti yoo wọ kaa ilẹ sun lonii naa.
Babalọja apapọ n'ipinlẹ Oyo, Alhaji Yekeen Abass, to ṣe ikede naa, fi kun ọrọ rẹ pe awọn kan an nipa fun awọn ontaja lati ti isọ wọn pa, nitori pe o pọn dandan fun wọn lati bu ọla fun Olubadan ana.
O tẹsiwaju pe aṣẹ ti wọn fi ti awọn ọja naa yoo waye laarin aago marun un idaji si aago mejila ọsan ọjọ Ẹti, ọjọ kẹjọ oṣu Kẹjọ ọdun yii.
Abass rọ awọn to n ṣe karakata lati tẹle aṣẹ naa.
Awọn aworan lati ibi isinku Olubadan


















