Àlàyé rèé lórí ìlú kan ní Kwara tí wọ́n ló di ahoro nítorí ìkọlu àwọn agbébọn

Aworan abule to daharo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ilu kan wa ti wọn n pe ni Ganmu Ahileri, nipinlẹ Kwara, awọn kan si sọ pe abule ni, ṣugbọn ni bayii, iroyin to gbode ni pe ko ṣẹku ẹyọ ẹnikan ṣoṣo nibẹ mọ, wọn ni wọn ti sa lọ nitori ikọlu awọn agbebọn.

Ijọba ibilẹ Ifelodun ni Ganmu Ahileri wa, ko si jinna si ilu kan ti a mọ si Baba nla.

Laipẹ yii ni fidio kan gun ori ayelujara, to ṣafihan gbogbo ilu Ganmu Ahileri bo ṣe da paroparo.

Ẹyọ ẹni kan ṣoṣo bayii ko si ninu awọn ile ninu fidio iroyin naa, bẹẹ ni gbogbo titi paapaa gbẹ lai si ẹnikan.

Awọn ọlọpaa to gbe ibọn dani, ti wọn n yipo ilu naa nikan lo han ninu fọnran ọhun.

Ṣaaju ni iroyin kan ti sọ pe awọn agbebọn n da ilu Ganmu Ahileri laamu pupọ.

Iroyin naa sọ pe wọn n wọlu pa awọn eeyan, wọn si n ji awọn mi-in lọ, ni gbogbo araalu ṣe tete juba ehoro.

Ṣugbọn ṣe bẹẹ ni eyi ri loootọ.

Èyí ni àlàyé iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Kwara lórí ilú Ganmu Ahileri tí wọ́n ló ti túká

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lati tako fidio to ṣafihan ilu ti ko si eeyan nibẹ mọ naa, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara, fi atẹjade kan sita l'Ọjọbọ, ọjọ keje, oṣu Kẹjọ ọdun 2025.

Ninu atẹjade naa ti Alukoro ọlọpaa Kwara, SP Adetoun Ejire-Adeyemi, fi sita ni wọn ti ni:

'' Ileeṣẹ ọlọpaa Kwara ti gbọ nipa fidio kan to ni awọn ara abule Ganmu Ahileri, nitosi Babanla ti fi ilu silẹ nitori ikọlu gbogbo igba awọn agbebọn.

" Wọn ni ilu naa ti di ahoro.

"Ileeṣẹ ọlọpaa Kwara fi n da yin loju pe iroyin aṣinilọna to le ko ipaya ti ko nidii ba awọn eeyan ni iroyin naa.

"Bo tilẹ jẹ pe loootọ ni iṣẹlẹ aburu kan waye lọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Keje ọdun 2025, nibi ti awọn agbebọn kan ti kọlu Abule Ganmu ti wọn si pa eeyan meji.

" Wọn ji awọn mẹta gbe lọ, ileeṣẹ ọlọpaa ti gbe igbesẹ lori ẹ kia.

"Awọn to lugbadi naa n rin irinajo lati Eko lọ si Babanla ni, taya ọkọ wọn to jo ni wọn duro ni Ganmu lati tunṣe.

" Nibi ti wọn ti n tun un ṣe ni awọn agbebọn marun-un to ti dena de wọn ti jade si wọn.

"Ikọlu naa lo fa iku Alhaji Abdulrazak Ewenla, ọmọ Abule Ajia ati Jimoh Audu lati Ganmu.''

Ọlọpaa ni alaafia ti wa ni Ganmu bayii, iwadii ko si duro lati gba awọn to wa nigbekun kalẹ lai jẹ pe kinni kan ṣe wọn

Atẹjade ọlọpaa ṣọ pe awọn agbofinro to wa ninu fidio naa jẹ ikọ ti ijọba ran lọ sibẹ lati ri i pe alaafia jọba.Ki wọn si gba awọn ti wọn ji gbe kalẹ ninu igbekun.

Bakan naa ni wọn ni alaafia ti wa ni Ganmu bayii, iwadii ko si duro lati gba awọn to wa nigbekun kalẹ lai jẹ pe kinni kan ṣe wọn.

Ileeṣẹ ọlọpaa Kwara ni oun yoo mu awọn oniṣẹ ibi naa pẹlu.