Mọ̀ nípa ààrùn Chikungunya tó ti sọ èèyàn 7,000 sí ìdùbúlẹ̀ àisàn ní China

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarun kan ti orukọ rẹ n jẹ chikungunya tun ti kọlu orilẹede China bayii, ti eeyan to le ni ẹgbẹrun meje si ti lugbadi rẹ.
Aarun naa ti wọn n ko lati ara ẹfọn lo ti n milẹ titi ni gbogbo agbegbe Guangdong lorilẹede naa lati oṣu to kọja, eyi to mu ki wọn maa gbe awọn ilana idaabo bo ara ẹni kalẹ bii ti asiko Covid-19.
Niluu Foshan ti aarun naa ti milẹ julọ, awọn ti chikungunya ba n finra gbọdọ duro sile iwosan nibi ti wọn yoo ti fi awọn ẹfọn bo ibusun wọn, bẹẹ ni wọn ki n tu wọn silẹ titi ti aarun naa yoo fi tan lara wọn.
Bo tilẹ jẹ pe wọn ni aarun ọhun kii fi bẹẹ gbẹmi eeyan, o maa n fa iba o si maa n jẹ ki ara ro eeyan fun igba pipẹ lẹyin ti eeyan ba ko lati ara ẹfọn.
Awọn onimọ sọ pe aarun naa le lo ọpọ ọdun lara eeyan ti ko ba gba itọju.
Ki ni arun chikungunya ati pe ki ni awọn apẹrẹ rẹ?
Bo tilẹ jẹ ko fi bẹẹ wọ pọ ni China, aarun chikungunya pọ ni guusu ati ariwa Asia ati awọn agbegbe kan ni Afrika.
Laarin ọjọ mẹta si ọjọ meje ni awọn ti ẹfọn to ni aarun naa lara ba bujẹ yoo bẹrẹ si n fi apẹrẹ rẹ han.
Yatọ si iba ati ara ti yoo maa ro ẹni naa, awọn apẹrẹ mii ni ara yiyun, ori fifọ, iṣan ara ti yoo maa ro eeyan ati orikerike ara ti yoo maa wu.
Lọpọ igba, aarin ọsẹ kan ni alaafia yoo pada si ara awọn to ba kọlu, nigba mii, ara riro naa le wa fun ọpọ oṣu tabi ọdun.
Awọn ti aarun naa yoo ṣe ipalara to pọ ju fun ni awọn ọmọ tuntun, awọn agbalagba atawọn ti aarun ti wa lara wọn tẹle bii ito ṣuga ati aisan ọkan.
Lọwọ yii, ko tii si iwosan kankan fun aarun naa amọ kii deede gbẹmi eeyan.
Ọdun 1952 ni arun naa kọkọ ran ọmọ Tanzania kan ko to ran de awọn agbegbe mii nilẹ adulawọ ati Asia.
Lonii yii, o le ni orilẹede ọgọrun ti aarun naa ti ba lalejo.
Bawo ni aarun yii ṣe n tete tan kalẹ si ni China?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Yatọ siluu Foshan, o ti tan de awọn ilu mejila mii lagbegbe Guangdong nibi ti egbẹrun mẹta eeyan ti lugbadi rẹ lọsẹ to kọja.
Lọjọ Aje, ilu Hong Kong jabọ pe ọmọ ọdun mejila kan ni ẹni akọkọ ti yoo ni arun naa nibẹ.
Aisan naa kii ran lati ara ẹnikan si ẹlomiran, ṣugbọn eeyan le ko lati ara ẹfọn to ni aarun naa lara.
Iroyin ni ida 95% awọn to ni lo n kuro nile iwosan laarin ọjọ meje pere.
Ki ni China n ṣe lati gbogun ti itankalẹ rẹ?
Awọn alaṣẹ ni Guangdong ti sọ pe gbogbo ọna ti yoo gba lawọn yoo fun lati gbogun ti aarun naa.
Wọn ti rọ gbogbo awọn to n ri apẹrẹ aarun ọhun lara wọn ki wọn tete gba ile iwosan lọ lai fi akoko ṣofo.
Wọn tun ti ke si araalu lati mojuto omi to ba dagun lagbegbe wọn ti ẹfọn le maa gbe pẹlu ikilọ pe ẹnikẹni to ba kọ lati ṣe bẹẹ yoo san owo itanra 10,000 yuan.
Yatọ si eyii, ijọba tun ti n da awọn ẹfọn nla nla si igboro, eyii ti yoo maa jẹ awọn ẹfọn kekeke to n pin aarun naa kiri.
Ọsẹ to kọja ni won ko ẹgbẹrun marun un ẹja to maa n jẹ kororo sinu awọn odo ilu Foshan ki wọn le maa jẹ awọn kororo ẹfọn to le ṣokunfa aarun naa nibẹ.












