Àwọn adágún odò mẹ́fà tó ń fà ìṣẹ̀lẹ̀ omiyalé jùlọ ní Naijiria

Adagun odo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ni bayii ti ojo ti bẹrẹ si n rọ kaakiri Naijiria, ọpọ awọn eeyan to n gbe lagbegbe to sunmọ omi lo ti bẹrẹ si n kọminu lori ọrọ omiyale to ṣe e ṣe ko waye.

Lọdọọdun ni omiyale lati awọn adagun odo maa n da wahala silẹ, eyi to maa n sọ ọpọ eeyan di alainilelori.

Lọdun to kọja, omiyale da wahala silẹ niluu Maiduguri nitori bo ṣe gbẹmi ọpọ eeyan.

Ninu ọdun yii, omiyale gba ẹmi eeyan to le ni igba niluu Mokwa, to wa nipinlẹ Niger bakan naa.

Akojọpọ awọn adagun odo to n ṣokunfa iṣẹlẹ omiyale julọ lọdọọdun ni Naijiria re e.

Lagdo dam – Cameroon

Lọdọọdun ni ibẹrubojo maa n wa sọkan awọn eeyan ni Naijiria lẹyin ti wọn ba ti ṣi adagun omi Lagdo silẹ lorilẹede Cameroon.

Omi to n ṣan lati inu adagun odo naa maa n ṣan de ipinlẹ mẹwaa ni Naijiria.

Ọpọlọpọ eeyan ni ẹmi wọn ti sọnu ni Naijiria latari bi wọn ṣe maa n ṣi adagun omi naa silẹ lọdọọdun.

Lara awọn ipinlẹ ti adagun odo Lagdo ni Cameroon yii maa n ṣe akoba fun ni Naijiria ni Adamawa, Taraba, Kogi, Nasarawa, Benue, Anambra, Bayelsa, Cross River, Delta, Edo ati ipinlẹ Rivers.

Ọdun 1982 ni wọn pari iṣẹ adagun naa pẹlu afojusun lati pese ina mọnamọna fun awọn eeyan Cameroon ati lati pese omi fun awọn nnkan ọgbin lasiko ọgbẹlẹ.

Ẹwẹ, ni gbogbo igba ti adagun omi naa ba ti kun akunju ni wọn maa n ṣi i silẹ, to si maa n ṣan de Naijiria.

Kainji Dam – Ipinlẹ Niger

Adagun odo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Aarin ọdun 1964 si 1968 ni wọn kọ adagun odo Kainji, ti wọn si n lo o fun ina ẹlẹtiriki, ipese omi fun nnkan ọgbin ati ẹja pipa.

Lọdun 2020 ni omiyale to buru julọ waye nipinlẹ Niger, eyii ti wọn di ẹbi rẹ ru adagun odo Kainji, to fi mọ adagun odo Shiroro ati ti Jebba.

Omiyale naa ṣekupa ọpọ eeyan, o wọ abule bii 150 lọ, to fi mọ ọpọlọpọ oko.

Jebba Dam – Ipinlẹ Niger

Ẹba odo Kwara ti ko jina si ilu Jebba ni aringungbun Ariwa Naijiria ni adagun odo yii wa.

Gẹgẹ bii adagun odo akẹgbẹ rẹ, wọn ṣe adagun odo naa fun ipese ina ijọba. Amọ adagun odo ọhun ti wọn kọ lọdun 1985 tun n ran awọn eeyan agbegbe naa lọwọ ninu karakata wọn.

Amọ ṣa, ni ibẹrẹ ọdun 2025 yii ni a gbọ pe omi to n aṣan lati inu rẹ ati ti Kainji wọ oko irẹsi ti iwọn rẹ to ẹgbẹrun marun un eeka lọ. Apapọ iye owo oko irẹsi naa lo le ni biliọnu mọkanla naira.

Lara awọn agbegbe ti omiyale naa ti ṣọṣẹ ni ijọba ibilẹ Moro, Patigi ati Edu ni ipinlẹ Kwara.

Shiroro Dam – Ipinlẹ Niger

Shiroro Dam

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ijọba ibilẹ Shiroro ni wọn kọ adagun odo Shiroro si nipinlẹ Niger, lẹba odo kan to n ṣan nipinlẹ Kaduna.

Ọdun 1990 ni adagun odo naa bẹrẹ iṣẹ to si n pese ina mọnamọna ti iye rẹ to 600 mẹgawaati.

Iroyin ni, ọpọ igba ni adagun odo naa n fa omiyalẹ latari akunfaya rẹ.

Alau Dam – ipinlẹ Borno

Kilomita mẹrindinlọgbọn si ilu Maiduguri to jẹ olu ilu ipinlẹ Borno ni adagun naa wa.

Eredi ti wọn fi kọ aagun naa lọdun 1986 ni lati pese omi fun awọn agbẹ.

Iwọn omi inu adagun odo naa le ni ọgọrun-un biliọnu lita.

Nigba ti yoo di ọdun 2024 ni adagun odo naa bẹ, o si fa iṣẹlẹ omiyale to buru julọ ninu itan ipinlẹ naa lati ọgbọn ọdun sẹyin.

Kashinmbila Dam – Taraba

Ẹba ilu Kashimbila ni wọn kọ adagun odo yii si nipinlẹ Taraba ni ariwa Naijiria.

Aarin ọdun 2011 si 2015 ni ijọba n mura lati pari adagun odo naa lati gbogun ti iṣẹlẹ omiyale lawọn ipinlẹ bii Benue, Rivers, Cross River ati Delta.

Yatọ si pe adagun odo ọhun yoo pese omi to mọ geere faraaalu, wọn ni afojusun pe yoo pese ina mọnamọna, yoo si wulo fun awọn agbẹ ni ipinlẹ Taraba.

Amọ ikuna ijọba lati pari iṣẹ kikọ adagun odo naa ti n fa omiyale lawọn agbegbe to yii ka ni gbogbo igba ti wọn ba ti si adagun odo Lagdo ni Cameroon.

Ki ni ọna abayọ?

Iṣẹlẹ omiyale

Oríṣun àwòrán, Ijọba ipinlẹ Borno

Nigba ti BBC kan si Umar Ibrahim Muhammad, to jẹ ọga gba ajọ Nigerian Hydrological Services Agency (NIHSA), o ni gbogbo ohun to yẹ ni ijọba apapọ n ṣe lati dena omiyale.

O ni gbogbo igba lawọn maa n ṣeto itaniji fun awọn araalu to n gbe lawọn agbegbe ti adagun omi wa ki wọn le tete sa asala fun ẹmi ara wọn ṣaju ki wọn to ṣi adagun odo kankan.

Lẹyin naa lo kilọ fun awọn araalu lati maṣe kọ eti ọgbọin si ijọba ni gbogbo igba to ba n kilọ pe ki wọn kuro lawọn agbegbe ti o ṣeeṣe ki omiyale ti waye.