Àgbàrá òjò gba ọ̀pọ̀ àdúgbò ní ìpínlẹ̀ Eko, aráàlú ń kígbe, ìjọba ní kí wọ́n ṣe sùúrù

Ọpọ awọn olugbe ipinlẹ Eko lo ti n kọminu lori ojo lemọlemọ to n rọ lẹnu ọjọ mẹta yii.
Oniruru awọn fidio lori ayelujara lo n ṣafihan bi awọn eeyan naa ṣe n daro ipo ti adugbo wọn wa latari agbara ojo to gba ọpọ oju popo.
Lara awon agbegbe ti ọrọ naa kan gbọgbọn ni Ijede, ni Ikoorodu, Ogudu, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ninu ọkan lara awọn fido naa ni obinrin kan ti n ke gbajare pe "agbegebe Oko Ope ni a wa yii o, ẹ ṣaanu wa o. Adugbo wa ree o, a ko le wọ inu ile wa mọ o, ojo ti gba gbogbo ọna.
"Mi o tilẹ wọ bata paapaa, ẹ gba wa o, oni ni ọjọ kẹrin ninu oṣu Kẹjọ, ọdun 2025."
Ninu fidio mii, ọkunrin kan sọ pe, "ohun ti oju mi n ri ree lagagbe mi ni Ijede.
Lati aarọ ọjọ kẹta si ọjọ kẹrin oṣu Kẹjọ ni ojo ti gba gbogbo inu ile mi. Ẹ wo gbogbo awon ọkọ ninu omi.
Ẹ lọ fọkan balẹ, a ti bẹrẹ iṣẹ lori omiyale naa – Ijoba Eko

Ẹwẹ, ijọba ipinlẹ Eko ti rọ awọn eeyan ipinlẹ naa ki wọn ṣe suuru nitori ijọba ko kawọ gbera lori ọrọ omiyale ọhun.
Ninu atẹjade kan loju opo X rẹ, kọmiṣọna fun ọrọ ayika ipinlẹ naa, Tokunbo Wahab ni lootọ ni ojo rọ fun nnkan bii wakati mejila gbako.
O fi kun pe ajọ to n ri si ọrọ oju ọjọ ni Naijiria NiMET ti sọ pe ojo ati ara yoo rọ fun ọjọ mẹta si amọ ijọba Eko n ṣiṣẹ takuntakun lati koju rẹ.
O ni "lati nnkan bii wakati mejila sẹyin ni ojo ti n rọ, ojo ṣi maa rọ fun ọjo mẹta si gẹgẹ bii ohun ti ajọ NiMET sọ.
"Ṣugbọn mo rọ gbogbo araalu ki wọn ṣe suuru."
Wahab sọ pe bo tilẹ jẹ pe ipinlẹ naa ti ṣe awọn eto lati gbogun ti iṣẹlẹ omiyale lasiko ojo, o ṣeeṣe ki omi pọ ju ọka wọn lọ latari bi ipinlẹ ọhun ṣe sunmọ omi.
Kọmiṣọna ọhun sọ siwaju si pe "gẹgẹ bii ilu to wa lẹba omi okun, o ṣeeṣe ki omi maa ya wọ ilu lasiko ti okun ba kun akunju, ọrọ naa tun wa buru jọjọ pẹlu ayipada oju ọjọ."
O tun fi akoko naa kilọ fun awọn obi ki wọn tọju awọn ọmọ wọn daadaa ki wọn ma baa jade lasiko omiyale.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Awọn eeyan n fi ile wọn silẹ ni Ikorodu latari omiyale

Wayi o, awọn eeyan kan ti n fi ile wọn silẹ ni Ikorodu latari bi omi ṣe gba gbogbo ile wọn.
Amọ ijọba ti ni ijọba mọ nipa rẹ, ijọba ko si dake.
Gẹgẹ bi Wahab ṣe sọ, awọn gọta kan ti wọn n gbẹ lọwọ ni Ikorodo yoo mu adinku ba iṣẹlẹ naa ti wọn ba ti ti pari rẹ.
Lẹyin naa tọrọ aforijin lọwọ awọn eeyan agbegbe naa fun idojukọ wọn lasiko yii.
O wa ṣeleri pe gbogbo iṣẹlẹ omiyale lagbegbe Ikorodu ni yoo di ohun igbagbe laipẹ ni kete ti ijọba ba ti pari awọn gọta to n la lọwọ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2














