Kàyéfì! Tọkọ-taya bímọ pẹ̀lú ọlẹ̀ tó lo ọgbọ̀n ọdún nínú yìnyín

Ọmọ tuntun

Oríṣun àwòrán, AFP/Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Tọkọtaya kan niluu Ohio, nilẹ Amerika ti bi ọmọ tuntun pẹlu ọlẹ ti wọn gbe sinu yinyin lati ọgbọn ọdun sẹyin.

Tọkọ-taya naa ti wọ inu iwe itan gẹgẹ bii mọlẹbi akọkọ ti yoo ṣe irufẹ nnkan bẹẹ.

Ọjọ Abamẹta ni Lindsey, to jẹ ẹni ọdun marundinlogoji, ati Tim Pierce, to jẹ ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn ki ọmọ wọn ọkunrin tuntun ọhun, Thaddeus Daniel Pierce, kaabọ sinu idile wọn.

Thaddeus Daniel Pierce yii ni igbagbọ wa pe oun ni ọmọ akọkọ ti ọlẹ rẹ yoo wa ninu yinyin fun odidi ọgbọn ọdun ki wọn to bi.

Ọmọ akọkọ ni awọn ibeji kan ti ọlẹ wọn wa ninu yinyin lati ọdun 1992 ki wọn to bi wọn lọdun 2022.

Pierce sọ fun ileeṣẹ iroyin MIT Technology Review pe "niṣe ni ọrọ naa da bii fiimu agbelewo loju awọn."

Odidi ọdun meje gbako ni tọkọ-taya yii fi n gbiyanju lati bi ọmọ ki wọn to gba ọlẹ inu obinrin ẹni ọdun mejilelọgọta kan, Linda Archerd, ti oun ati ọkọ rẹ fi pamọ pẹlu imọ IVF lọdun 1994.

Lọdun naa lọhun, ọlẹ mẹrin ni Archerd gbe silẹ, ọkan lara wọn ni ọmọ rẹ to ti pe ẹni ọgbọn ọdun bayii, to si fi mẹta to ku pamọ.

Bo tilẹ jẹ pe ipinya waye laarin oun ati ọkọ rẹ, o kọ lati ko awọn ọlẹ naa danu tabi ko wọn fun awọn onimọ sayẹnsi fun iwadii tabi fun awọn mọlẹbi mii lai fi orukọ ara rẹ sita.

O ni o ṣe pataki si oun lati wa ninu aye ọmọ ti yoo jẹ ibatan ọmọ oun obinrin.

Ẹgbẹẹgbẹrun owo dọla ilẹ Amẹrika ni Archerd n san lọdọọdun fun inu yinyin to fi ẹyin ọhun pamọ si ko to pade ajọ Kristẹni kan to maa n gba irufẹ ọlẹ bẹẹ.

Ọlẹ inu obinrin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ajọ naa, Nightlight Christian Adoptions, n ṣeto kan ti wọn n pe ni Snowflakes.

Pupọ ninu awọn ajọ bi ti Nightlight Christian Adoptions yii ni won gbagbọ pe wọn n gba ẹmi eeyan la.

Eto ọhun ti Arabinrin Archerd lọ, lo n fun awọn to ni ọlẹ ọmọ lanfaani lati yan mọlẹbi ti wọn n fẹ ko bi ọmọ ọhun.

Eyi tumọ si pe wọn le yan ẹya, ẹsin ati orilẹede ẹni ti wọn ba n fẹ ko bi ọmọ pẹlu ọlẹ to jade lati ara wọn.

Archerd sọ fun ajọ naa pe ẹbi to jẹ Kristẹni, to tun jẹ ẹya Caucasian ti wọn tun fi ilẹ America ṣebugbe ni oun n fẹ ki wọn bi ọmọ ọlẹ oun si, gẹgẹ bii ohun to sọ fun MIT Technology Review.

Lẹyinorẹyin, ọrọ oun ati idile Pierce wọ.

Ile iwosan Rejoice Fertility, to wa niluu Tennessee ti wọn ti ṣeto naa sọ pe oun ko bikita iye ọjọ ori ọlẹ naa tabi ti ẹni to jẹ bikoṣe ki oun gbe sinu ẹni to tọ si.

Pierce sọ pe ko si ohun to kan oun ati ọkọ oun pẹlu jijẹ ẹni akọkọ ti yoo ṣe irufẹ nnkan bẹẹ lagbaye, ki awọn ṣaa ti di ọlọmọ laye ni afojusun awọn.

Nigba ti Archerd n ba MIT Technology Review sọrọ, o ni oun ko tii foju ba ọmọ naa amọ oun gbagbọ pe yoo foju jọ ọmọbinrin oun to ti pe ẹni ọgbọn ọdun.