Njẹ́ o mọ̀ pé ẹyin kò sí lára oúnjẹ́ tó n mú ni yasó? Wo òunjẹ́ mẹ́jọ tó n fa isó

Ẹni to n yaso

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, BBC Food
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Yiyaso kii ṣe nnkan to ṣe ajoji si ara - koda, eeyan ti ara rẹ da pe le so laarin igba marun un si mẹdogun lojumọ.

Njẹ ẹ tun mọ pe, yiya iso fun ọpọ igba lojumọ jẹ apẹẹrẹ ilera to peye, yatọ si ti ojuti to ma n mu ba ni lawujọ.

Nipa ti ojuti, awọn kan ti ẹ ma n sọ pe Ọlọrun ko da akitan fun iso.

Idi gbogbo alaye oke yii ni pe, awọn ounjẹ to n mu ni so, n ṣe anfaani fun ọkan. Wọn kun fun eroja ti a mọ si carbs, eyi to mu ko ṣoro fun ara rẹ lati dà awọn ounjẹ naa, amọ kokoro aifojuri to wa ninu ifun rẹ le ṣe iṣẹ naa.

Ounjẹ wo gan-an wa ni irinṣẹ iso? E wo lo ma n fa iso to n run oorun buruku, ati pe igba wo lo yẹ ki o ri dokita nitori iso?

Akojọpọ rẹ re e:

1. Ounjẹ ọlọraa

Awọn ounjẹ ọlọra kii tete dà ninu ara, eyi to le mu ki wọn o lo igba pipẹ ninu ifun, ti wọn o si bẹrẹ si i run oorun ti ko dara.

Ni ti ẹran ọlọraa, o nira tiẹ lati sọ nipa wọn. Idi ni pe, wọn ni ọpọlọpọ eroja ti a mọ si amino acid methionine, to tun ni sulphur ninu.

Eroja sulphur yii ni awọn kokoro aifojuri 'bacteria' to wa ninu ara rẹ ma n sọ di hydrogen sulphide - iyẹn oorun bi i ti òbu ẹyin - to si ma n fi kun iso ti awọn ounjẹ mii bi ẹran ma n pese.

2. Ẹwa

Oriṣirisi ounjẹ to jẹ Legumes

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn ounjẹ ti wọn n pe ni 'Legumes', bi ẹwa, jẹ gboogi lara awọn nnkan to n mu iso jade ninu ara nitori eroja faiba to wa ninu wọn

Ẹwa ati ounjẹ kan to jọ ọ, eyi ti wọn n pe ni lentil, ni ọpọlọpọ fibre, amọ wọn tun ni eroja raffinose, ṣuga kan ti ara kii ṣe atupalẹ rẹ daadaa.

Awọn ṣuga yii ma n wa ọna de inu ifun, nibi ti ara ti ma n sọ wọn di okun fun ara, eyi to n pada di eroja hydrogen, methane ati oorun sulphur.

3. Ẹyin

Tako igbagbọ ọpọ eeyan, ẹyin kii mu wa so.

Ṣugbọn wọn ni eroja sulphur to ni methionine. Nitori naa, ti o ko ba fẹ ya iso ti oorun rẹ le wu oku, ma jẹ ẹyin lasiko kan naa pẹlu awọn ounjẹ to n mu ni so bii ẹwa tabi ẹran ọlọraa.

4. Alubosa

Obinrin to di inu rẹ mu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn ounjẹ oni koro ati wiiti dara fun ara lootọ, amọ wọn tun le mu ọ ya iso

Alubosa, galiiki, ati awọn ounjẹ mii bi artichokes ati leeks ni eroja fructans – carbs ninu, eyi to n fa ki inu kun ati iso

5. Wara ẹranko

Awọn ounjẹ wara lati ara maalu ati ewurẹ, ni eroja ti wọn n pe ni lactose, iyẹn ṣuga to le mu ki iso korajọ ninu ara.

Iyalẹnu kan to wa nibẹ ni pe, ida marunlelọgọta, 65%, agbalagba to wa l'agbaye, ni eroja lactose ko ba lara mu, ti wọn si ma n ni inira, wọn o tun ma a so, lẹyin ti wọn ba mu miliiki tan.

Miliiki ati wara

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, 65%, agbalagba to wa l'agbaye, ni eroja lactose ko ba lara mu,

6. Wiiti ati ounjẹ onikoro

Eroja to ma n fa iso wa ninu awọn ounjẹ onikoro bii oats ati wheat - nitori naa awọn ounjẹ bii burẹdi, pasta (spaghetti) ti wọn fi wọn ṣe, ma n mu ni so.

Yatọ si eyi, awọn ounjẹ onikoro bii wheat ati barley, tun ni gluten ninu.

Ti gluten ko ba ba ọ lara mu, o ṣe e ṣe ki o ma a so lẹyin ti o ba jẹ ounjẹ to ni i.

On top of this, some wholegrains, such as wheat, barley and rye, contain gluten.

7. Broccoli, cauliflower ati cabbage

Cabbage, broccoli ati cauliflower, sprouts, kale ati awọn ewebẹ mii ni eroja faiba to pọ ninu, eyi to ma n mu ko nira fun ara lati fọ wọn si wẹwẹ.

Ṣugbọn kokoro aifojuri bacteria to wa ninu ifun rẹ fẹran lati ma a lo wọn fun okun, ti eyi si ma n yọri si iso.

Pupọ ninu awọn ewebẹ yii lo tun ni sulphur, ti oorun rẹ si ma n ni agbara.

Cauliflower pupa ati funfun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn ewebẹ to ba ni sulphur ninu ma n mu eeyan so

Eso

Ọpọlọpọ eso bii apu, mangoro ati pia, ni ṣuga ti a n pe ni fructose ninu. Awọn apu kan ati pia tun ni faiba pẹluu.

Awọn eeyan kan wa to ma n ṣoro fun ara wọn lati fọ fructose si wẹwẹ, ti inu wọn si le kun lẹyin ti wọn ba jẹ awọn eso aladun yii nitori pe, awọn ṣuga naa ko fọ si wẹwẹ.

Amọ, iru awọn eeyan yii ko wọpọ to awọn ti miliiki tabi wara ko ba lara mu.

Njẹ o ṣe e ṣe ki o ma so o?

Eso ati ewebẹ le fa iso, amọ jijẹ wọn daadaa lojumọ ṣe pataki ju fifi opin si iso lọ. Ti o ko ba ki n jẹ awọn ounjẹ to ni faiba ninu tẹlẹ, bibẹrẹ si ni jẹ wọn ni ọpọlọpọ le mu inira ba ọ.

Diẹdiẹ ni ko fi bẹrẹ jijẹ wọn titi yoo fi ba ọ lara mu.

Obinrin to n mu omi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn onimọ sọ pe o dara lati mu omi fun idena inu kikun

Omi mimu jẹ nnkan pataki to n dena inu kikun - inu kikun ma n ṣe atọna fun iso. Ti igbọnsẹ ba ṣẹku sinu ifun rẹ, yoo bẹrẹ si ni ira, eyi ti yoo mu ki o ma a ya iso to ni oorun buruku.

Gbiyanju lati ma a mu omi lẹyin ounjẹ, ati nigba ti o ko ba jẹun.

Ajọ eto ilera nilẹ Gẹẹsi, NHS, sọ pe mimu tii to ni peppermint ninu, ma n tu eeyan lara fun iso ati inu kikun.

Awọn nnkan mimu ẹlẹrindodo ni gaasi ninu, ti o ba si mu wọn, o le ma a gufẹ tabi so leralera.

Nigba wo ni yiya iso lewu?

Ni ọpọ igba, iso kii ṣe nnkan to le fa ifoya tabi to nilo itọju nileewosan.

Iso to n run tun le jẹ nitori awọn oogun kan ti o n lo lọwọ.

Ṣugbọn o, apọju iso le jẹ apẹẹrẹ awọn aisan to l'agbara. To ba ru ọ loju, lọ ọ ri dokita rẹ.