Wo bí àwòrán ìkọ̀kọ̀ ṣe tú àṣírí àwọn ìyá ìsàlẹ̀ tó ń fi àwọn ọmọdé ṣe owó nàbì ní Kenya

- Author, Njeri Mwangi
- Role, BBC Africa Eye in Maai Mahiu
- Author, Tamasin Ford
- Role, BBC Africa Eye
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7
Iwadii BBC Africa Eye ṣafihan bii awọn obinrin kan, ti wọn n pe ara wọn ni 'madam' ṣe lọwọ ninu fifi ọmọde ti wọn wa ni ọmọ ọdun mẹtala se iṣẹ asẹwo ni Kenya.
Ninu ọkọ to n lọ niluu Maai Mahui, ni Kenya, awọn ọkọ nla ati ajagbe n pariwo ni ilu, lọsan loru bi wọn se n ko ẹru ati eeyan wọle jade lọ si orilẹede Uganda, Rwanda, South Sudan ati Democratic of Congo.
Irinajo yii, ni o jẹ 50km ila oorun si olu ilu, Nairobi, ni ọpọ ti n lo fun iṣẹ asẹwo ati lilọ fun okowo fifi awọn ọmọde se iṣẹ asẹwo.
Awọn oniwadii BBC meji, dibọ bii asẹwo, ni wọn lọ lati fẹ kọsẹ bii wọn ṣe n ṣe madam, lo ọpọ oṣu ṣaaju ọdun yii lati itan imọlẹ si gbogbo ohun to ṣokunkun nipa karakata fifi ọmọde ṣe isẹ asẹwo niluu ọhun.
Fọnran ti wọn fi ọgbọn ka silẹ ṣafihan obinrin meji ọtọọtọ ti wọn ni awọn mọ pe iwa yii lodi si ofin, ti wọn si tọka awọn ọmọde ti ọjọ ori wọn kere si awọn oniwadii ti wọn wa ninu iṣẹ asẹwo.
BBC fun ileeṣẹ ọlọpaa ni gbogbo ẹri ti wọn kojọ ninu oṣu kẹta. BBC gbagbọ pe awọn madam yii ti parọ agbegbe lati igba naa. Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn obinrin ati ọdọmọbinrin ti a ka fọnran wọn silẹ ni awọn ko le ṣawari. Titi wọ asiko yii, wọn ko ti mu ẹnikẹni.
Fifi ofin mu eeyan jẹ nnkan ti ko wọpọ ni Kenya. Ti wọn to le gbe afurasi lọ si ile ẹjọ, ileeṣẹ ọlọpaa nilo ijẹri lati awọn ọmọde. Ni ọpọ igba, ọpọ awọn ọdọ ni ẹru ma n ba lati jẹri.
Fọnran ti BBC ka lori titi ṣafihan obinrin kan, to pe ara rẹ ni Nyambura, to n rẹrin bi o ṣe n sọ: "Ọmọde si ni wọn, o rorun lati ko si wọn lọkan ti ẹ ba ti fun wọn ni pongila.
"Iṣẹ asẹwo da bi eso ni Maai Mahiu.
Bayii ni a ṣe n jere. O jẹ nnkan ti ko ki n ṣe tuntun ni Maai Mahiu," o ṣalaye, fikun pe oun ni ọmọ kan, to kere bi ọmọ ọdun mẹtala, to n sisẹ fun oṣu mẹfa bayii.
"O ti n lẹyin bayii ti o ba n da nnkan pọ pẹlu ọmọde. O kan le gbe wọn sita. Mo ma n fi ọgbọn gbe wọn jade ni alẹ." Nyambura sọ.
Siṣẹ asẹwo ti o ba jẹ agbalagba ni ko lodi si ofin labẹ ofin orilẹede Kenya, ṣugbọn awọn ofin agbegbe kan lodi si eyi. Ko lodi si ofin ni Maai Mahiu, to jẹ apa kan Nakuru.
Labẹ ofin naa, o lodi si ofin lati ma na owo lati di iṣẹ aṣewo, boya o jẹ asẹwo tabi alarinna to gbe asẹwo fun awọn olubara.
Sisẹ karakata awọn ọmọde fun ibalopọ ti wọn wa labẹ ọdun mejidinlogun ni ijiya rẹ jẹ ọdun mẹwaa si ayeraye lọgba ẹwọn.
Nigba ti wọn bi, boya awọn awọn onibara wọn ba n lo ọra idabobo, Nyambura ni oun ma n ri daju pe wọn lo idabobo sugbọn awọn miiran ma n yari.
"Awọn ọmọde kan fẹ ri owo nla [fun idi eyi, wọn ko ki n lo]. Awọn mii lo jẹ tipatipa [pe ki wọn ma lo wọn]," o sọ.
Ninu ipade miiran, o lewaju awọn oniwadii lọ si ile nibi ti awọn ọdọmọbinrin mẹta wa, ti wọn si ri wọn ti wọn jokoo sori aga.
Nyambura wa kuro niluu yara, to si fun awọn oniwadii ni anfani lati bi awọn ọdọmọbinrin naa ni ibeere ni awọn nikan.
Wọn ni ojoojumọ ni awọn n koju ifipabanilopọ.
"Ni igba miiran, o le ni ibalopọ pẹlu ọpọ eeyan. Awọn onibaara mii ma fi tipatipa mu eeyan ṣe awọn nnkan ti ko ṣe ro," ọkan ninu ọdọmọbinrin ọhun sọ.
Ko si iwadii to fidi rẹ mulẹ iye awọn ọdọmọbinrin ti wọn n fi tipatipa mu ṣe iṣẹ asẹwo ni Kenya. Ni ọdun 2012, ẹka ijọba lati orilẹede US State Department Country Report on Human Rights Practices in Kenya to n ja fẹtọ ọmọniyan ni o to 30,000 ọmọ to lọwọ ninu iṣẹ asẹwo lorilẹede Kenya.
Oniwadii keji ni anfani lati jẹri ọkan obinrin kan to pe ara rẹ ni Cheptoo, to si ni ọpọ ipade pẹlu rẹ.
O ni tita awọn ọdọmọbinrin yii le fun ọpọlọpọ owo ti yoo si ma gbe igbeya irọnu.
"O le ṣe iṣẹ yii ni ikọkọ nitori o lodi si ofin,: o sọ.
"Ti ẹnikẹni ba ni awọn fẹ ọdọmọbinrin, mo ma ni ki wọn san owo fun mi . A ni awọn ti wọn ma n wa lorekore lati wa ra wọn."
Cheptoo mu oniwadii wa lọ si kilọọbu lati lo pade awọn ọdọmọbinrin merin . Eyi to kere ju lo jẹ ọmọ ọdun mẹtala. Awọn yooku ni awọn jẹ ọmọ mẹdogun.
O sọrọ nipa iye ere to ma n lati ọwọ wọn, pe ninu ẹgbẹrun mẹta Kenyan ($23; £17) owo ti ọmọ kọkan n pa wọle, ti ipin rẹ si jẹ 2,500 shillings ($19; £14).
Ni ipade miiran, ni ile Maai Mahiu, Cheptoo fi oniwadii silẹ pẹlu awọn ọdọmọbinrin meji.
Ọkan ninu wọn sọ fun un pe oun ma n ba o kereju ọkunrin marun un sun lojumọ.
Nigba ti wọn bi pe se o ma n kọ jalẹ ti wọn ko ba lo ọra idabobo, o ni ko si aye fun oun lati sọ eyi.
"Mo ma n ni ibalopọ lai si ọra idabobo. Wọn ma le mi danu, n ko si ni ibikibi lati lọ."
Ileeṣẹ asẹwo lorilẹede Kenya le gidigan, tọkunrin ti obinrin ni wọn lọwọ ninu iṣẹ to ni ṣe pẹlu lilo ọmọde.
Ko si ẹni to mọ bi wọn se n fi tipatipa fa ọpọ ọmọde sinu iṣẹ asẹwo ni Maai Mahiu, ṣugbọn ni ilu kekere ti o le ni ẹgbẹrun lọna aadọta, o rọrun lati ṣawari wọn.
Oṣiṣẹ asẹwo nigba kan ri, ti wọn mọ si "Baby Girl", to n pese iranlọwọ fun ọdọmọbinrin ni Maai Mahiu ti ori ti ko wọn yọ lọwọ iṣẹ asẹwo.
Ẹni ọdun mọkanlelọgọta ṣiṣẹ nidi asẹwo fun ogoji ọdun, to si ṣawari ara rẹ ni oju titi nigba to wa ni ogun ọdun. O loyun, to si ni ọmọ mẹta pẹlu ko to di pe o sa kuro ni ọdọ ọkọ rẹ nitori lilu to n waye lemọlemọ.
Ni ile rẹ, o ṣafihan BBC si awọn ọdọmọbinrin ti wọn fi tipatipa fa wọ isẹ asẹwo ni Maai Mahiu nigba ti wọn wa ni ewe.
Awọn ọmọ yii ni itan kan naa to jọ mọ ile to daru- wọn ṣa wa si Maai Mahiu, ti wọn si tun koju ikọlu.
Michelle ṣalaye pe ni ọmọ ọdun mejila, oun padanu awọn obi rẹ sọwọ aarun HIV, ti o si n gbe lori titi nibi to ti pade ọkunrin kan to fun ibi kan ti yoo ma gbe, to si tun fipa ba lo pọ.
"Mo ni lati ma fi ara mi san fun pe o n kọ mi. O de ọkan aya mi ṣugbọn n ko ni nkankan.
Lẹyin ọdun meji, obinrin kan to jẹ madam kọnu si ni Maai Mahiu, to si fa wọ iṣẹ asẹwo.

Lilian, ọmọ ọdun mọkandinlogun, naa padanu awọn obi rẹ nigba to wa ni kekere. O n gbe pẹlu ẹgbọn baba rẹ to ka fọnran bi o se n wẹ, ti o si n ta aworan naa fun awọn ọrẹ rẹ. Eyi to pada ja si ifipabanilopọ.
"Ọjọ yii lo buru ju, Ọmọ ọdun mejila ni lasiko naa."
Nigba to sa lọ, ọlọkọ nla kan naa fipabalopọ. Nibi bayii, gẹgẹ bii Michelle, oun naa ko sọwọ obinrin kan to fa sisẹ asẹwo.
Ni bayii ni ile Baby Girl, wọn ti n kọ iṣẹ ọwọ tuntun- meji n kọ iṣẹ ayaworan, meji n kọ isẹ oge.
Bakan naa ni wọn ran Baby Girl lọwọ pẹlu isẹ ladugbo.
Agbegbe Nakuru lo ni eeyan to ni aarun HIV ju ni orileede Kenya, Baby Girl pẹlu iranlọwọ orilẹede Amẹrika n da awọn araalu lẹkọ lori nini ibalopọ lia lo ida bobo.
Ṣugbọn pẹlu bii Aarẹ US, Donald Trump ṣe ti fopin si eto iranlọwọ USAID, awọn eto iranlọwọ Baby Girl ti fẹ wa sopin.
"Lati oṣu kẹsan an, a ko ni ni iṣẹ lọwọ mọ," o sọ fun BBC World Service, to fikun pe ọrọ nipa awọn obinrin ati ọdọmọbinrin n kọ oun lominu.
"Bawo ni awọn ọmọ ṣe fẹ gbe ile aye . Bawo ni wọn se ma da duro fun ara wọn. wọn si n dagba.
Ni bayii, Lilan n gbajumọ kilọ iṣẹ ayaworan, to si n gba itọju naa.
"N ko foya mo nitori Baby wa nibẹ fun mi," o sọ. "O ran lọwọ lati gbagbe ohun to ti kọja.















