Ta ni Temidayo Oniosun, ọmọ ìpìnlẹ̀ Oyo, tó sọ ẹ̀gúsí di èso àkọ́kọ́ tí wọ́n rán lọ sínú òfurufú?

Oríṣun àwòrán, Temidayo Oniosun/Instagram
Dókítà ọmọ Nàìjíríà tó fi orílẹ̀èdè America ṣe ibùjókòó, Dókítà Temidayo Oniosun ti ṣíwájú ìwádìí kan láti gbé ẹ̀gúsí lọ sínú òfurufú, tí a tún le pè ní agbedeméjì ayé àti ọ̀run, ìyẹn International Space Station.
Ẹ̀gúsí yìí ni èso àkọ́kọ́ láti ẹkùn Iwọ̀ Oòrùn Africa àti ní Nàìjíríà ti wọ́n máa gbé lọ sí inú òfurufú.
Oniosun sọ fún BBC pé kò sí ọbẹ̀ tó ṣe àfihàn ọmọ Nàìjíríà tó Ẹ̀gúsí.
Ẹ̀gúsí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn oúnjẹ Nàìjíríà tí a lè ṣàwárí ní gbogbo ẹkùn tó wà ní Nàìjíríà, tó sì jẹ́ oúnjẹ ti èèyàn le bá pàdé láàrin gbogbo ẹ̀yà.
Ìrìnàjò rẹ̀ ló sí ojú òfurufú jẹ́ àrà ọ̀tun ní ẹ̀ka ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì.
Èròńgbà láti gbé oúnjé náà lọ sí inú òfurufú jẹ́ ọ̀nà láti ṣe àfihàn àwọn oúnjẹ tó jẹ́ ti ilẹ̀ Africa, nínú ìwádìí ojú òfurufú àti láti mú ìgbòòrò bá ìwádìí lórí àwọn ohun ọ̀gbìn.
Ìwádìí náà máa ṣe àfihàn bí gbíngbin oúnjẹ ṣe lè máa wáyé láwọn àyíká tí ojú ọjọ́ wọn kò fi bẹ́ẹ̀ fararọ, tó fi mọ́ inú òṣùpá àti Mars.
Ní ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n, oṣù Keje, ọdún 2025 ni ẹ̀gúsí náà ti lọ sí ojú òfurufú báyìí láti Cape Canaveral, Florida, America.
Wọ́n sọ pé àyẹ̀wò tó lágbára máa wáyé sí ẹ̀gúsí náà ní kété tí èso rẹ̀ náà bá ti padà sí orílẹ̀ ayé pẹ̀lú àjọṣepọ̀ Ọ̀jọ̀gbọ́n Wagner Vendrame ti ilé ẹ̀kọ́ gíga University of Florida.
Lára àwọn ìwádìí tí yóò wáyé sí ẹ̀gúsí náà tó bá padà sí orílẹ̀ ayé ni "vitro germination" láti ṣe àyẹ̀wò àwọn àyípadà tó ti bá ẹ̀gúsí náà gẹ́gẹ́ bí Oniosun ṣe ṣàlàyé.
Oniosun sọ pé ìwádìí yìí kọjá ètò ọ̀gbìn lásán, ó jẹ́ ìwádìí nípa bíi oúnjẹ yóò ṣe máa wà ní ọ̀pọ̀ yanturu.
"Tí ẹ̀gúsí bá fi lè ṣe é lò lẹ́yìn tí ó ti kojú àwọn ohun tó wà ní ojú òfurufú, ó máa ṣi ilẹ̀kùn fún gbígbé àwọn èso míì lọ sí ojú òfurufú."
Láti Okaka lọ sí ojú òfurufú

Oríṣun àwòrán, Temidayo Oniosun/Instagram
Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo ti kan sáárá sí ìgbésẹ̀ gbígbé èso ẹ̀gúsí ìpínlẹ̀ Oyo lọ sí ojú òfurufú.
Àtẹ̀jáde kan tí ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo fi sójú òpó Facebook kan sáárá sí Dókítà Temidayo Oniosun fún àjọṣepọ̀ tó ní pẹ̀lú iléeṣẹ́ ìwádìí NASA láti ran ẹ̀gúsí pẹ̀lú ọkọ̀ òfurufú SpaceX Crew-11 lọ sí ojú òfurufú.
"Ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tí èso láti Nàìjíríà yóò lọ sí inú òfurufú tó sì jẹ́ pé láti ìpínlẹ̀ Oyo ni wọ́n ti mú ẹ̀gúsí náà.
"Bí èso náà ṣe ń lọ sí ojú òfurufú lọ́jọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n, oṣù Keje, ọdún 2025, a rọ gbogbo àwọn ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Oyo láti kópa níbi ṣíṣe àyẹ̀wò ìgbésẹ̀ náà."
Ta ni Dókítà Temidayo Oniosun?

Oríṣun àwòrán, Temidayo Oniosun/Instagram
Onímọ̀ nípa ojú òfurufú ni Temidayo Isaiah Oniosun.
Òun ni olùdásílẹ̀ Space of Africa tó sì tún fìgbà kan rí jẹ́ alákòóso fún Space Generation Advisory Council fún Africa.
Ọmọ bíbí ìlú Okaka ní ìpínlẹ̀ Oyo ni, tó sì dàgbà ní ìlú Oyo níbi tó ti kẹ́kọ̀ọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti girama.
Ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Federal University of Technology, Akure, FUTA ni Oniosun ti kẹ́kọ̀ọ́ jáde lọ́dún 2016 nínú ìmọ̀ ẹ̀kọ́ Meteorology.
Ó kẹ́kọ̀ọ́ onípò kejì níní ìmọ̀ "Satelite applications" ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì University of Strathclyde, Glasgow, tó sì gba oyè ọ̀mọ́wé ní ilé ẹ̀kọ́ gíga University of Delaware.
Nígbà tó wà ní akẹ́kọ̀ọ́ FUTA lọ́dún 2015 ló ṣaájú àwọn ẹgbẹ́ space club ilé ẹ̀kọ́ náà láti fi fèrè lọ sójú òfurufú nínú ìdíje kan.
Ọdún 2016 ló gba àmì ẹ̀yẹ International Astronautical Federation Emerging Space Leadership Award fún àwọn iṣẹ́ takuntakun tó ń ṣe lẹ́ka òfurufú.
Ọdún 2017 ni wọ́ yàn-án gẹ́gẹ́ bí alákòóso Space Generation Advisory Council fún ilẹ̀ Africa tí wọ́n sì tún dìbò yàn-án fún sáà kejì lọ́dún 2019.












