Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́, NLC yarí lórí òfin tí kò nìí jẹ́ kí wọ́n o le máa yanṣẹ́lódì mọ́

Aworan ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ẹgbẹ oṣiṣẹ lorilẹede Naijiria, Nigeria Labour Congress (NLC), ti koro oju si ilana kan ti ijọba Naijiria tẹwọgba lati ọdọ National Industrial Relations Policy (NIRP).

Ofin naa ti ẹgbẹ oṣiṣẹ sọ pe yoo maa dari awọn lasiko iyanṣẹlodi, ni ijọba Naijiria ni awọn tẹwọgba l'Ọjọbọ, lẹyin ipade igbimọ alaṣẹ Naijiria.

Minisita eto iroyin ati ikede, Mohammed Idris, lo kede ofin naa lẹyin ipade ọhun.

Mohammed ṣalaye pe ofin tuntun yii yoo maa ṣe atọna fun awọn adari okowo, awọn agbanisiṣẹ, ijọba ati awọn ajọ kaakiri Naijiria.

Yoo tun fi aaye gba ajọsọ nilana ti wọn n lo lagbaaye, bi Mohammed ṣe sọ.

Ṣugbọn ẹgbẹ NLC yari, wọn ni "ete lati ma jẹ ki oṣiṣẹ yanṣẹlodi mọ ni ofin tijọba tẹwọgba yii".

Ilana ti yoo maa dari ipinnu awon oṣiṣẹ naa ni NLC yari pe awọn ko ni i fi aaye gba.

Ó yà wá lẹ́nu pé irú òfin yìí ni ìjọba fọ́wọ sí nínú gbogbo èyí tó wà níbẹ̀'

Ninu atẹjade kan ti Aarẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ, Joe Ajaero, buwọlu, lo ti ni ijọloju gidi lo jẹ, pe ninu gbogbo ilana ti ajọ to ṣe agbekalẹ ilana fun awọn oṣiṣẹ, National Industrial Relations Policy, la kalẹ, eyi to ni i ṣe pẹlu iyanṣẹlodi ni ijọba ri mu.

Wọn ni eyi to n fọ wọn lori ninu rẹ ni wọn mu yẹn.

"Atẹjade buruku ti wọn fi sita naa ti tu aṣiri ohun ti awọn ti a yan sipo n ro nipa awa oṣiṣẹ ati araalu.

"Ẹtọ ni fun oṣiṣẹ tabi ẹgbẹ oniṣowo lati yanṣẹlodi, ko si sẹni to le yọ ọ kuro labẹ ofin."

Bẹẹ ni atẹjade awọn NLC wi, to si tako ti ijọba.

Bakan naa ni ẹgbẹ oṣiṣẹ fi aidunnu wọn han si bi ijọba ṣe lo ọwọ agbara lati yi adehun ẹlẹni mẹta to da awọn pọ pada.

Adehun naa to wa laaarin ijọba, agbanisiṣẹ ati awọn oṣiṣẹ lo ni awọn ti jọ fẹnuko le lori.

NLC ṣalaye pe igbeṣẹ ti yoo sọ iṣe awọn NIRP di iwa ọdaran ni ijọba Naijiria n gbe, bẹẹ ẹgbẹ to ṣẹṣẹ n dide bọ ni.

Atẹjade ẹgbẹ oṣiṣẹ tẹsiwaju, pe awọn lodi si igbesẹ yii latari pe o tako ofin ọdun 1999, abala owo ṣiṣẹ to fi aaye gba igbimọ ọlọja lati daṣẹ silẹ labẹ ofin.

Kí ló dé ti ìjọba rántí òfin yìí?

Gẹgẹ bi alaye NLC, ofin yii ti wa tipẹ, o si wa fun awọn nnkan mi-in nipa iṣẹ ni.

Wọn ni ṣugbọn o wulẹ wu ijọba Naijiria lati mu abala to tako iyanṣẹlodi yii nikan ni.

Iroyin sọ pe iyanṣẹlodi ikilọ ọlọjọ meje ti ẹgbẹ awọn nọọsi ati agbẹbi gunle l'Ọjọruu ọsẹ to kọja, lo mu ijọba bẹrẹ igbese tuntun yii.