Wo ìtàn tó rọ̀ mọ́ àyájọ́ ọ̀rẹ́bìnrin tó ń wáyé lónìí àti pàtàkì rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ní gbogbo ọjọ́ Kìíní, oṣù Kẹjọ, ọdún 2025 ni wọ́n yà sọ́tọ̀ láti fi ṣàmì àwọn ọ̀rẹ́bìnrin èyí tí wọ́n pè ní National Girlfriends Day.
Ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà ni wọ́n ti ṣe ìdásílẹ̀ ọjọ́ yìí pẹ̀lú èròńgbà láti máa ṣe ìmọrírì ìbáṣepọ̀ tó wà láàárín àwọn obìnrin yálà ọ̀rẹ́sọ́rẹ̀ẹ́, ìyá sí ọmọ, ẹ̀gbọ́n sí àbúrò tàbí òṣìṣẹ́ kan sí èkejì.
Àwọn ọ̀rẹ́bìnrin síra wọn fẹ́ràn láti máa lo àkókò papọ̀, ṣeré, sọ̀rọ̀ àṣírí fúnra wọn, tí wọ́n sì máa ń jọ ń wà fúnra wọn yálà nígbà tí nǹkan bá dùn tàbí lásìkò ìṣòro.
Ní ọdún 1859 ni ọ̀rọ̀ tó ń jẹ́ "girlfriend" èyí tó túmọ̀ sí ọ̀rẹ́bìnrin kọ́kọ́ jẹ jáde gẹ́gẹ́ bí Merriam-Webster èyí tó sì túmọ̀ sí ọ̀rẹ́ láàárín obìnrin sí obìnrin.
Ọdún 1920 ni ìtumọ̀ rẹ̀ gba ọ̀nà mìíràn nígbà tí ìbáṣepọ̀ láàárín ọkùnrin àti obìnrin ti bẹ̀rẹ̀ sí ní wọ́pọ̀ tó sì tún ń mọ́ sí ìbáṣepọ̀ láàárín ọkùnrin àti obìnrin.
Títí di àsìkò yìí ni ìtumọ̀ "girlfriend" ti ní ìtumọ̀ méjì tó fi mọ́ ìtumọ̀ láàárín obìnrin sí obìnrin tí wọ́n kàn jọ ń ṣe ọ̀rẹ́ àti obìnrin sí ọkùnrin tí wọ́n jọ ń ní ìbáṣepọ̀ láàárín ara wọn.
Kí ni pàtàkì àyájọ́ yìí?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ọjọ́ ni wọ́n ti yà kalẹ̀ láti ṣe ìmọrírì àwọn obìnrin yálà tó jẹ́ ọmọdé tàbí àgbà, àrà ọ̀tọ̀ tún ni ti ọjọ́ ti ọ̀rẹ́bìnrin.
Àyájọ́ ọjọ́ ọ̀rẹ́bìnrin kò ní nǹkankan ṣe pẹ̀lú níní olólùfẹ́ tàbí ẹni tí èèyàn ń bá ṣeré ìfẹ́ nìkan bíkòṣe láti mọ rírì àwọn obìnrin tí èèyàn ń bá ṣe ọ̀rẹ́.
Ó jẹ́ ọjọ́ láti ṣe ìmọrírì àwọn àtìlẹyìn, ìfẹ́, ẹ̀rín àti ayọ̀ tí àwọn obìnrin ń fún ara wọn.
Ó le jẹ́ ọ̀rẹ́bìnrin tó mọ ohun tó tọ́ láti sọ sí èèyàn lásìkò tí èèyàn bá ń la ìṣòro kan kọjá tàbí òmiràn tàbí alábàáṣiṣẹ́ ẹni tí ìbáṣepọ̀ yín ti sọ yín di ọmọ ìyá.
Bákan náà ló tún le jẹ́ obìnrin kan tó máa ń mú ọwọ́ ẹni dání nígbà ayọ̀ àti ìṣòro láti ri pé èèyàn kò kojú ohunkóhun fúnra ẹni.
Àyájọ́ òní gan ni wọ́n yà sọ́tọ̀ láti ṣe ìmọrírì àti kóríyá fún àwọn ọ̀rẹ́ tó jẹ́ pé wọ́n máa ń dìde síni ní gbogbo ìgbà.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn olólùfẹ́ ti ń lo àyájọ́ òní láti fi ṣe ìmọrírì àwọn obìnrin tó wà ní ìgbésẹ̀ ayé wọn, àwọn obìnrin sí obìnrin tí wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ ni àyájọ́ òní wà fún gangan.
Ta lo ṣe ìdásílẹ̀ ọjọ́ yìí?
Ní ọdún 2006 ni Allie Savarino Kline àti Sally Rodgers ṣe ìdásílẹ̀ ọjọ́ yìí.
Bákan náà ni àwọn obìnrin yìí tún ṣe ìdásílẹ̀ ojú òpó ayélujára kan tí kò ṣiṣẹ́ mọ́.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Báwo ni èèyàn ṣe lè ṣe àyájọ́ náà?
Gẹ́gẹ́ bí ìdí tí wọ́n ṣe ṣe ìdásílẹ̀ ọjọ́ yìí láti mọ rírì àwọn obìnrin tó wà ní ìgbé ayé èèyàn, ó ṣe pàtàkì láti jẹ́ kí àwọn ọ̀rẹ́bìnrin rẹ mọ bí wọ́n ṣe pàtàkì tó.
Tó bá ṣeéṣe ó lè gbé ọ̀rẹ́ rẹ jáde ní àyájọ́ yìí láti lọ jẹun, ṣeré, wo eré sinimá lọ́nà tó jẹ́ pé ọ̀rẹ́bìnrin ló le ṣe bẹ́ẹ̀ fúnra wọn.
Àwọn ọkùnrin náà le gba àwọn olólùfẹ́ wọn láàyè láti ṣe ayẹyẹ pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ mìíràn lójúnà àti lè ní ìbáṣepọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.















