Lawal Adefalu, bàbá Hasfot Yetunde sọ̀rọ̀, nípa ìdájọ́ lórí ikú ọmọ rẹ̀

Adefalu baba Yetunde ati Yetunde
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Lawal Adefalu, tii se baba oloogbe Hafot Yetunde Lawal, ti Abdulrahman Bello sekupa, ti kan sara si idajọ to waye ni ile ẹjọ giga ipinlẹ Kwara ni ilu Ilọrin.

Ọjọru ana ni ile ẹjọ giga ilu Ilorin gbe idajọ kalẹ pe ki wọn lọ yẹgi fun Abdulrahman Bello tori o jẹbi ipaniyan ti wọn fi kan-an.

Adajọ ni ọdaran naa lo mọọmọ pa Hafsot nile rẹ ni osu keji ọdun yii.

Adefalu to ba aṣoju BBC News Yorùbá sọrọ lẹyin idajọ naa, fi idunu rẹ han si bi idajọ naa se lọ amọ o ni ọkan oun gbọgbẹ lati igba ti iṣẹlẹ iku ọmọ oun ti wáyé.

Baba Hafsot sọ pe idajọ gidi to waye lori iku ọmọ oun naa jẹ ko di mimọ pe ireti ti wa ninu ẹka eto idajọ bayii fún idajọ ododo.

"Iku ọmọ mi jẹ ọgbẹ ọkan fun emi ati iya rẹ lati igba ti iṣẹlẹ naa ti waye.

Yetunde ọmọ mi kii se oniwa palapala rara.

Mo kan saara si adajọ ile ẹjọ giga naa ati awọn agbẹjọro pẹlu awọn ọlọpaa ti wọn jọ ṣiṣẹ pọ.

Amọ titi laelae ni maa ma se ranti ọmọ naa."

Adefalu wa dupẹ lọwọ gbogbo ọmọ Naijiria fun aduroti ati ifẹ ti wọn fihan si oun lati igba ti iṣẹlẹ naa ti waye.

Abdulrahman ati awọn afurasi yoku
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Bakan naa, nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, agbẹjọro fun awọn olujẹjọ, Suleiman Alamonyọ, ni inu oun dun pupọ fun idajọ naa.

O salaye pe awọn mẹrin to ku ko mọ kankan nípa iṣẹlẹ naa sugbọn nitori pe wọn jẹ ọrẹ Abdulrahman Bello, ni wọn fi mu wọn.

Agbẹjọro naa kan sara si adajọ ile ẹjọ giga ọhun fun bi igbẹjọ naa se ya kiakia.

Ẹsẹ o gbero ni ile ẹjọ giga naa lasiko ti idajọ n waye, bi awọn eeyan se wa wo ibi ti igbẹjọ naa yóò yọri si.

Ti a ko ba gbagbe, ọjọ kẹsan oṣu keji ọdun 2025 ni wọn mu Abdulrahman Bello atawọn mẹrin mii lori ẹsun sisekupa Hasfot Yetunde Lawal.

Isẹlẹ naa waye nigba ti Hafsot di await fun ọpọ ọjọ lai wa sile, ti awọn obi rẹ si lọ fi ẹjọ sun ọlọpaa.

Iwadi ileesẹ ọlọpaa safihan pe ipe Abdulrahman Bello ni Hafsot Yetunde naa gba kẹyin ko to di ẹni ti wọn n wa.

Idi ree ti wọn se lọ sile rẹ, ti wọn si ba ori obinrin naa ati ẹjẹ rẹ ninu ile Abdulrahman.

Lati igba naa si ni igbẹjọ ọhun ti bẹrẹ, ti ileejọ si gbe idajọ kalẹ pe Abdulrahman jẹbi iku, tori o fi tipa ba obinrin naa lopọ, ki o to seku pa.