Mo fún Hafot Yetunde Lawal lọ́rùn pa lásìkò tí mò ń bá a ní àjọṣepọ̀ lọ́wọ́ - Abdurahman Bello

Oríṣun àwòrán, BBC/Others
Igbẹjọ Abdurahman Bello ati awọn mẹrin mii ti wọn n jẹjọ lọwọ lori isekupa Hafsot Yetunde Lawal tẹsiwaju loni ni ile ẹjọ giga ipinlẹ kwara.
Abdurahman Bello ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara fẹsun ipaniyan ati ifipabanilopo kan lori iku akẹkọ ile ẹkọ olukọni agba ilu Ilọrin.
Bẹẹ ba gbagbe, igbẹjọ to re kọja ṣafihan awọn ẹlẹri marun un ti wọn jẹri tako Abdurahman Bello, ti wọn si safihan fọnrán fido ibi ti Abdurahman Bello ti jẹwọ fun awọn ọlọpaa pe lootọ oun loun pa Hafsot Yetunde Lawal.
Eyi ni ohun to sẹlẹ ni ile ẹjọ lonii lẹyin ti igbẹjọ naa bẹrẹ laago mẹsan kọja isẹju mẹfa ni ile ẹjọ giga ipinlẹ kwara labẹ adajọ Christiana Ajayi.
Ayọọla Akande ati Isa Bakare lo soju Kọmisona feto idajọ ipinlẹ Kwara to tun jẹ amofin agba, Senior Ibrahim.
Chukwudi Maduka ni agbẹjọro olujẹjọ kinni, ti A S Oseni, Suleiman Alamonyọ soju olujẹjọ keji, M A Yusuf, soju olujẹjọ kẹta.
Abdurahman Adelodun soju fun olujẹjọ kẹrin.
Ayọọla Akande, agbẹjọro ijọba ni, awọn ni ẹlẹri meji mi ni yoo jẹri loni ni ile ẹjọ.
Adajo si ni ki wọn pe awọn ẹlẹri naa wọle.
Ẹlẹri kinni Ayọdeji Joshua to wa lati ẹka to n se iwadii lati ọfisi ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ kwara.
O ni ohun jẹ ọkan lara awọn ọlọpaa to se iwadii ọrọ naa.
O salaye pe lọjọ kẹwa oṣu Karun ọdun yii ni ile iṣẹ eto idajọ ipinlẹ kwara kọ iwe ẹsun sọwọ sí awọn ni ibi ti wọn ti fẹsun kan Abdulrahman Bello ati awọn mẹrin mi lori iku Hasfot Yetunde Lawal.
Nigba ti wọn bẹrẹ ibeere lori iwadii ọrọ naa, o ni awọn se iwadii si akoto owo rẹ ati ẹrọ ayelujara Facebook rẹ, bẹẹ ni awọn ri aṣẹ gba ni ile ẹjọ lati wo ero ibanisọrọ rẹ.
Ninu iwadii awọn, o tẹsiwaju pe awọn ri pe Abdurahman Bello pe Hafsah Lawal fun igba akọkọ lọjọ kẹsan oṣu keji ọdun yii.
Abdurahman Bello jẹwọ pe lootọ ni oun pa Afsot Yetunde Lawal.
Lọjọ kẹwaa oṣu Keji ọdun yii, Abdurahman Bello pe oloogbe naa nigba mẹrin laarin ago kan ọsan si ago mẹrin irọlẹ.
Akande ni awọn ranṣẹ pe awọn marun un naa, ti ṣe ìya Barakat alagbo ati jimọh Ibrahim fun ifọrọwanilenu wo, ti awọn si ri pe Abdurahman Bello ba wọn sọrọ lori Isegun ibilẹ, to si n bi wọn ni ibeere bi ewe ajẹ-ọ-bale, atare ati bẹẹ bẹẹ lọ.
O ni awọn bi Abdurahman Bello lere ki ni o fẹ fi awọn nnkan yii se, o ni oun fẹ lo ni.
Ẹni keji ti Abdurahman Bello pe, iwadii fihan pe, o fi owo sọwọ si i lati ba ra egbogi oloro.
Lọjọ Kọkanla osu keji ọdun yii, o tun pe jimọh Mahmud to jẹ alapata, pe oun nilo ọpọlọ maalu.
Lẹyin alaye naa, ẹlẹri naa sagbekalẹ iwe akọsilẹ iwadii wọn fun ile ẹjọ gẹgẹ bii ẹri, adajo si gbaa wọle.
Ẹlẹri tun sagbekalẹ fọnran fídíò ibi ti Abdurahman Bello ti jẹwọ pe, lootọ ni oun pa Afsot Yetunde Lawal.
Ninu fidio naa, Abdurahman ni lasiko ti oun ba Hasfot Yetunde Lawal lo pọ lọwọ ni oun fun lọrun pa.
O ni lẹyin eyi ni Bello ni oun jade lọ ra igo oti lile ti oun si mu u de idaji igo ki oun to bẹrẹ si kun oku rẹ wẹlẹwẹlẹ pẹlu aada ati ọbẹ.
'Lẹyìn ti mo kun oku rẹ wẹlẹwẹlẹ tan ni mo lọ da eyi to ku si orita'
Abdurahman Bello tun sọ pe, lẹyìn ti oun kun oku rẹ wẹlẹwẹlẹ tan ni oun lọ da eyi to ku si orita.
Akande ni, "Bello ni lẹyin eyi ni awọn ọlọpaa wa mu oun ti wọn si ranṣẹ pe awọn obi Hasfot, igba ti awọn obi rẹ de agọ ọlọpaa, wọn ni kilode ti oun fi gbe ọmọ awọn pamọ, ti oun si tun ba sun,
"O ni oun sọ fun Baba oloogbe pe, ọrọ yii ti kọja bibasun tori oun ti pa ọmọ wọn."
Olujẹjọ keji Abdulwasiu sọrọ ninu fọnran fídíò ti ẹlẹri mu wa ile ẹjọ.
Abdulwasiu ni ọrẹ ni oun ati Abdurahman Bello, ọdọ oun lo sí ti n gba kewu amọ oun ko mọ nípa ẹsun isekupa ni ti wọn fi kan an, awọn kan jẹ ọrẹ lasan ni.
Olujẹjọ kẹta Muyideen Suleiman naa ni oun n ko mọwọ mẹsẹ lori ẹsun naa, ati pe akoba lo jẹ fun oun.
Olujẹjọ kẹrin Usman Muhammed ni oun kan mọ Abdurahman ni, oun o mọ nípa iwa ọdaran to wu.
Bakan naa ni olujẹjọ karun sọ pe, ibi adua lawọn ti pade, oun o si lọwọ si ẹsun isekupa ti wọn fi kan.
Ẹlẹri keji Dr Kunle Adewale ti se igbakeji alaga ẹgbẹ ajafẹtọ-ọmọniyan, salaye pe lọjọ kẹjọ oṣu Kẹrin ọdun yii ni awọn oṣiṣẹ eleto abo ọtẹlẹmuyẹ pe oun lori ọrọ Abdurahman Bello ti wọn fẹsun ipaniyan kan.
O ni gẹgẹ bi agbẹjọro ajafẹtọ-ọmọniyan oun da wọn lohun .
Oju oun ni gbogbo awọn ti wọn fẹsun kan se kọ oun ti wọn mọn nipa iṣẹlẹ naa.
Adajọ Christiana Ajayi gba iwe akọsilẹ olujẹri wọle gẹgẹ bi ẹri.
Awọn agbẹjọro bẹbẹ fun gbigba oniduro awọn toku ṣugbọn adajọ kọ jalẹ.
Adajọ sun igbẹjọ Siwaju di ọjọ kọkanla osu yii, to si ni titi opin osu Keje oun yoo pari ẹjọ naa.
Ki lo sẹlẹ ṣaaju?

Oríṣun àwòrán, Others
Igbẹjọ Abdulrahman Bello ati awọn mẹrin mii ti wọn fẹsun kan pe wọn ṣekupa ọdọmọbinrin kan, Haffsot Yetunde Lawal n waye lọwọ niluu Ilorin, nipinlẹ Kwara.
Amofin agba fun ipinlẹ Kwara, to tun jẹ kọmisanna fun eto idajọ, Senior Ibrahim lo n ṣiwaju awọn agbẹjọro bii F. B Alaya, D.T Adeleke lati ṣoju ijọba ipinle Kwara nibi igbẹjọ naa.
Ojọ kọkanlelogun, oṣu Karun un ni igbẹjọ waye kẹyin.
Tẹ o ba gbagbe, Isipẹtọ ọlọpaa, Ayodele Azeez to n ṣe amojuto iwadii ọhun ṣalaye fun ile ẹjọ lọjọ kejidinlogun, oṣu Keji, ni ikọ oluwadii lọ sile Abdurahman Bello ti wọn si ba yẹti to jẹ ti Hasfot Yetunde Lawal, bata, iwe oogun, pẹlu ẹrọ ibanisọrọ Hasfot Yetunde Lawal.
Inspector Azeez ṣagbekalẹ fọnran ọrọ ti wọn gba lẹnu Abdurahman Bello lasiko iwadii ti agbẹjọro ijọba to tun jẹ Kọmisanna feto idajọ, Senior Ibrahim rọ adajọ lati gba fọnran naa wọle gẹgẹ bi ẹri, adajọ si gba a wọle.
Lẹyin naa ni wọn ṣafihan fọnran ti wọn fi gba ohun ati aworan Abdurahman Bello kalẹ fun ile ẹjọ.
Ninu fọnran naa ti wọn ṣafihan nile ẹjọ, Abdurahman Bello sọ pe oun ati Hasfot Lawal pade lori ẹrọ ayelujara, tawọn si jọ n sọrọ lati fẹra awọn.
"O ti pẹ ti Hasfot ti maa n ṣeleri fun mi pe oun maa wa ki mi nile.
O ni lọjọ ti iṣẹlẹ naa waye, Hasfot wa si ile oun, to si sọ pe ebi n pa oun bo ṣe de ti oun si lọ ra ounjẹ fun-un.
O sọ pe lẹyin to jẹun tan ni awọn lajọsepọ amọ to daku lẹyin ibalopọ naa.
"Nitori pe mi o le da oku rẹ gbe jade ni mo fi kun oku rẹ wẹlẹwẹlẹ, mo si ge ọwọ rẹ mejeeji lati fi ṣe aajo owo."
Azeez tun sọ fun ile-ẹjọ pe idi ti awọn ọlọpaa fi mu awọn mẹrin to ku ti wọn jọ n jẹjọ ni pe iwadii fi han pe wọn ni ibaṣepọ pẹlu Abdurahman ati pe awọn lo n pe e julọ lori ẹrọ ibanisọrọ.















