Ẹnìkan kọlu Oba Odidiọmọ Oladimeji tílùú Igbokoda , ó tún gé ọba létí jẹ

Àwòrán Oba Odidiomo Afolabi Oladimeji

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Níṣe ni àwọn èèyàn ìlú Igbokoda ní ìjọba ìbílẹ̀ Ilaje ní ìpínlẹ̀ Ondo ya sí ojú pópó, tí wọ́n sì ń ṣe ìwọ́de láti ṣe ìfẹ̀hónúhàn.

Ohun tí wọ́n ṣe ìfẹ̀hónúhàn lé lórí kò ṣẹ̀yìn báwọn kan ṣe kọlu ọba wọn, Olu ti ìlú Igbokoda, Ọba Odidiomo Afolabi Oladimeji.

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́, níbi ètò kan tí wọ́n ti fẹ́ ṣe ìfilọ́lẹ̀ sísọ ọ̀nà Igbokoda sí Okitipupa di alábala méjì ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé lọ́jọ́ Ajé.

Gẹ́gẹ́ bí amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ ọba náà ṣe sọ, níṣe ni ara ń kan àwọn èèyàn ìlú náà báyìí, tí wọ́n sì ń bèèrè pé kí ẹni tó ṣe ìkọlù sí ọba náà tọrọ àforíjì ní ìta gbangba.

Àwọn olùfẹ̀hónúhàn náà tó fi mọ́ àwọn ọ̀dọ́ àtàwọn obìnrin ya sí ojú pópó láti pè fún ìdájọ́ òdodo àti ìbọ̀wọ̀ fáwọn orí adé àti ọrùn ìlẹ̀kẹ̀ látọwọ́ àwọn aráàlú.

Níṣe láwọn obìnrin náà ṣe ìwọ́de káàkiri ìlú níhòhò láti fi ṣàfihàn bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe bí wọn nínú tó.

Kí ló ṣẹlẹ̀?

Ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kejì, oṣù Kẹfa, ọdún 2025 ni ìròyìn sọ pé olórí agbègbè kan ṣe ìkọlù sí Ọba Odidiomo Afolabi Oladimeji, Olu ti ìlú Igbokoda lásìkò ayẹyẹ ọ̀hún.

Wọ́n ní olórí agbègbè náà ṣe ìkọlù sí Oba Odidiomo nígbà tí Ọba náà ṣo fun pé kó kúrò ní ààyè iwájú tó jókòó sí, láti lè jẹ́ kí àwọn ọba aláyé wà níbẹ̀.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Wọ́n sọ pé ọba náà sọ fún ẹni náà láti bọ́ sí ààyè míràn ṣùgbọ́n ẹni náà kọ̀ tó sì dúnkokò láti na ọba.

Ọba Odidiomo ṣàlàyé pé ẹni náà kọ̀ láti dìde, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní bú òun, dúnkokò láti na òun, tí ọ̀rọ̀ náà sì di iṣu ata yánnayànna.

Ó sọ pé onítọ̀hún tí wọ́n kò darakọ gé òun létí jẹ èyí tó mu kí òun nílò ìtọ́jú nílé ìwòsàn lójú ẹsẹ̀.

Olùrànlọ́wọ́ fún ọba aláyé náà tún fẹ̀sùn kàn pé ẹni náà hùwà àfojúdi sí ọba náà nítorí ó ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn tó wà ní ìjọba, tó sì jẹ́ ìgbìyànjú láti tàbùkù ọba.

Ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti fa ìfẹ̀hónúhàn àti awuyewuye ní ìlú ọ̀hún, táwọn èèyàn sì ń ké pe ìjọba láti fojú ẹni náà winá òfin.

"Gẹ́gẹ́ bí Ọba, mi ò ní jẹ́ kí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí lọ láì gbé àwọn ìgbésẹ̀ tó tọ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Mo máa rip é mo ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn aláṣẹ tó tọ́ láti fojú ẹni náà winá òfin.

Kí ni iléeṣẹ́ ọlọ́pàá sọ?

BBC News kàn sí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ondo láti fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀.

Agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ondo, Ayanlade Olayinka Olushola, sọ pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn gbọ́ nípa ìròyìn náà, kò sí ẹni tó fi ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó iléeṣẹ́ ọlọ́pàá létí.

Ó sọ pé iléeṣẹ́ ọlọ́pàá kò lè gbé ìgbésẹ̀ kankan lórí rẹ̀ níwọ̀n ìgbà tí wọn kò mú ẹjọ́ náà lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá kankan.