Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́

Lẹyin ti mo ba Hasfot Lawal ni ibalopọ tan ni mo fun lọrun pa

Iwọ kẹ? Nibo lo ti laya iru ẹ?

Abdulrahman Bello, afurasi to n jẹjọ lori iku Hafsot Lawal, akẹkọọ ti wọn ba oku rẹ nile rẹ niluu Ilorin lo sọ bẹẹ

Ninu fidio kan ti wọn gbe kalẹ nile ẹjọ lonii ni wọn ti ṣafihan bi Abdurahman Bello

Ṣe n jẹwọ fawọn ọlọpaa pe lẹyin ibalopọ loun pa ọmọbinrin naa

Toun si mu ogogoro koun to bẹrẹ kikun oku rẹ wẹlẹwẹlẹ.

xxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxx

Awọn araalu Igbokoda nipinlẹ Ondo ṣe iwọde ifẹhonuhan

Lori ẹsun pe ẹnikan ṣe ikọlu si ọba wọn to si tun ge ọba jẹ leti

Awọn eeyan naa sọ pe iwa afojudi ni ẹni naa hu, to si nilo lati tọrọ aforiji

Ileeṣẹ ọlọpaa ni wọn ko tii fẹjọ iṣẹlẹ naa sun lagọ ọlọpaa

xxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxx

Awọn alaṣẹ ni ipinlẹ Benue ti sọ pe ko din ni aadọta eeyan

To ti pàdánù ẹ̀mí wọn si ìkọlù táwọn afurasi darandaran ṣe sáwọn èèyàn ni ìjọba ìbílẹ̀ Gwer West àti Apa ní ìpínlẹ̀ Benue

Awọn alaṣẹ ìjọba ìbílẹ̀ mejeeji ni ọpọ eeyan la wọn ṣi n wa bayii

Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́