Ẹgbẹ́ àwọn nọ́ọ̀sì Naijiria ti fagilé ìyanṣẹ́lódì wọn

Àkọlé fídíò, Ìyanṣẹ́lódì àwọn Nọ́ọ̀sì ń tẹ̀síwájú, àwọn aláìsàn ń ké gbàjarè sí ìjọba ní ìpínlẹ̀ Oyo
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Iyanṣẹlodi ikilọ ọlọjọ meje ti ẹgbẹ́ àwọn nọ́ọ̀sì àtàwọn agbẹ̀bí ní Nàìjíríà, National Association of Nigeria Nurses and Midwives (NANNM), gunle ti wa si opin.

Oni ọjọ Abamẹta, ọjọ keji, oṣu Kẹjọ ọdun 2025 ni ẹgbẹ awọn nọọsi ati agbẹbi ṣegile iyanṣẹlodi ikilọ naa.

Aarẹ apapọ fun ẹgbẹ NANNM, Kọmureedi Haruna Mamman, fidi ẹ mulẹ fun BBC ni ọsan ọjọ Abamẹta naa pe awọn ti dẹkun iyanṣẹlodi ọhun.

Mamman ṣalaye pe lẹyin ipade pẹlu awọn alẹnulọrọ ninu ijọba, ijọba gba lati ṣe ọpọ ohun ti awọn n beere fun.

''Ṣe ẹ mọ pe a ṣepade pẹlu awọn aṣoju ijọba lanaa (ọjọ Ẹti), pupọ ninu awọn nnkan ti a n beere fun ni ijọba ti gba lati ṣe fun wa.

''To ba di Ọjọruu, a tun maa pade lati tẹsiwaju ninu ajọsọ. Nigba ti ijọba ti dahun, o daa ka fopin si iyanṣẹlodi, ka si tẹsiwaju pẹlu ọrọ ajọsọ''

Bẹẹ ni Aarẹ awọn nọọsi ati agbẹbi ni Naijiria, Haruna Mamman ṣalaye.

Ninu adehun to waye nibi ipade ori ayelujara naa ni wọn ti fi ẹnu ko, pe ki awọn nọọsi bẹrẹ iṣẹ pada lọgan.

Wọn fi kun un pe ko gbọdọ si ifiyajẹni fun awọn to kopa nibi iyanṣẹlodi ikilọ naa.

Bakan naa ni awọn alabojuto lẹka kọọkan ni wọn ti rọ lati bojuto bi ipada si ẹnu iṣẹ naa ṣe n lọ.

Aworan nọọsi obinrin kan ni yara itọju pẹlu ẹni to n gba itọju

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Aworan iwe ti wọn fi kede opin iyanṣẹlodi naa

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán, Iwe ti wọn fi kede opin iyanṣẹlodi naa
Aworan iwe ti wọn fi kede opin iyanṣẹlodi naa

Oríṣun àwòrán, Others

Kí ló ti ṣẹlẹ̀ ṣíwájú?

'A ò tíì fẹnukò láti padà sẹ́nu iṣẹ́' - Ẹgbẹ́ àwọn nọ́ọ̀sì tako ìkéde ìjọba

Nọ́ọ̀sì tó ń tọ́jú aláìsàn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ẹgbẹ́ àwọn nọ́ọ̀sì àtàwọn agbẹ̀bí ní Nàìjíríà ìyẹn National Association of Nigeria Nurses and Midwives (NANNM) ti jiyàn ìròyìn tó gba orí ayélujára pé wọ́n ti ṣẹ́wélé ìyanṣẹ́lódì tí wọ́n gúnlè.

Ẹgbẹ́ náà sọ fún àwọn èèyàn wọn láti ṣe sùúrù láti gbọ́ àbọ̀ ohun tí àwọn adarí ẹgbẹ́ náà máa fẹnukò lé lórí lkyìn tí wọ́n bá ṣèpàdé lọ́jọ́ Àbámẹ́ta.

Igbákejì akọ̀wé ẹgbẹ́ NANNM, Ofere Oluwatoyin nínú àtẹ̀jáde kan tó fi síta lọ́jọ́ Ẹtì lẹ́yìn tí wọ́n ṣèpàdé pẹ̀lú mínísítà fún ètò ìlera, Ọ̀jọ̀gbọ́n Ali Pate.

"Lẹ́yìn ìpàdé tí a ṣe, láti jíròrò pẹ̀lú àwọn mínísítà fún ètò ìlera, iṣẹ́ àti ìgbaniṣẹ́, àtàwọn lóókọ lóókì lẹ́ka ètò ìlera míì.

"A ò ní fẹnukò àyàfi tí a bá ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn aláṣẹ ẹgbẹ́, èyí tó máa wáyé lọ́jọ́ Kejì, oṣù Kẹjọ."

Ṣáájú ni ìjọba àpapọ̀ ti kọ́kọ́ kéde pé ẹgbẹ́ náà ti ṣẹ́wélé ìyanṣẹ́lódì wọn àmọ́ tí ẹgbẹ́ náà ti jiyàn ìròyìn náà báyìí.

Mínísítà fún ètò ìlera, Ọ̀jọ̀gbọ́n Ali Pate ló kéde bẹ́ẹ̀ tí agbẹnusọ mínísítà náà sì sọ fún BBC pé àwọn ti fẹnukò pẹ̀lú àwọn nọ́ọ̀sì náà.

Ó ní "a ṣẹ̀sẹ̀ parí ìpàdé pẹ̀lú àwọn nọ́ọ̀sì ni, wọ́n sì ti gbà pé àwọn máa ṣẹ́eẹ́lé ìyanṣẹ́lódì náà lẹ́ṣẹ̀kẹsẹ̀."

Ní ọjọ́rú, ọjọ́ ọgbọ̀n ọjọ́ oṣù Keje ni àwọn nọ́ọ̀sì náà bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì, tí wọ́n sì fẹ̀sùn kan ìjọba àppapọ̀ pé wọn kò náání gbèdéke ọjọ́ mẹ́ẹ̀dógún tí àwọn fún wọn láti dáhùn àwọn nǹkan tí àwọn ń bèèrè fún.

Ìyanṣẹ́lódì àwọn Nọ́ọ̀sì ń tẹ̀síwájú, àwọn aláìsàn ń ké gbàjarè sí ìjọba ní ìpínlẹ̀ Oyo

Ẹgbẹ awọn Nọọsi ati Agbẹbi ipinlẹ Ọyọ naa ti darapọ mọ awọn akẹgbẹ wọn jakejado orilẹede Naijiria ninu iyanṣẹlodi olojọ meje ti wọn fi n kilọ fun ijọba apapọ.

Alaga ẹgbẹ naa nile iwosan UCH ilẹ Ibadan, Arabinrin Olufunmilola Faminu ṣe alaye fun akọroyin wa wi pe awọn nnkan ti ẹgbẹ naa n ja fun kii ṣe ẹtọ awọn Nọọsi ati Agbẹbi ipinlẹ Ọyọ nikan bikoṣe ẹto gbogbo ọmọ ẹgbẹ naa jakejado orilẹede Naijiria.

Faminu ni, "Ọrọ to wa nile yii kii ṣe ọrọ Nọọsi ati Agbẹbi n'ipinlẹ Ọyọ nikan, ṣugbọn gbogbo awọn ti wọn pe ara wọn ni Nọọsi to jẹ ọmọ Naijiria.

Niwọn igba ti eeyan ba sọ pe Nọọsi ni mi ti mo si kọṣẹmọṣẹ, gbogbo wa ni ọrọ naa kan."

A beere awọn koko nnkan ti ẹgbẹ naa n beere lọwọ ijọba, alaye ti alaga ẹgbẹ naa nile iwosan UCH ṣe fun wa ni pe, nnkan ti awọn fẹ lọdọ ijọba pọ, akọkọ nibẹ ni pe wọn fẹ ki ijọba gba awọn oṣiṣẹ Nọọsi si ẹnu iṣẹ nitori ọpọlọpọ awọn Nọọsi to "japa" lọ si ilu Oyinbọ ti mu ki iṣẹ wọ awọn ti wọn n bẹ ni Naijiria lọrun.

'A fẹ ki ijọba gba oṣiṣẹ sii nitori pe ibi to jẹ pe Nọọsi kan lo yẹ ki o tọju alaisan mẹrin ni a ti rii pe ẹnikan lo n tọju ogun, ko si yẹ ko ri bẹẹ.'

O ni, "Ẹ ẹ rii wi pe ọpọlọpọ awọn oṣiṣẹ wa to n ṣiṣẹ nile iwosan paapaa julọ awọn Nọọsi, wọn ti kuro, wọn ti japa. Wọn ti lọ si ilu Oyinbo, wọn ti wa iṣẹ lọ nibi ti wọn ti mọ iyi wọn, nibi ti wọn si ti n san owo wọn dede.

A wa fẹ ki ijọba gba oṣiṣẹ sii nitori pe ibi to jẹ pe Nọọsi kan lo yẹ ki o tọju alaisan mẹrin ni a ti rii pe ẹnikan lo n tọju ogun, ko si yẹ ko ri bẹẹ."

Faminu tẹsiwaju wi pe awọn tun fẹ ki ijọba pese awọn ohun elo ti wọn o maa fi ṣiṣẹ fun wọn nitori ni ọpọlọpọ igba ti awọn alaisan ba de, awọn kii ni ohun to yẹ ki wọn fi tọju wọn. O ni ọjọ ti lọ lori awọn ohun elo ti awọn n lo, ijọba si kọ lati ra tuntun.

Nnkan mii ti wọn tun n beere lọwọ ijọba ni anfani si ipo adari ni ẹka eto ilẹra orilẹede Naijiiria, gẹgẹ bi wọn ṣe n fẹ ki aṣoju Nọọsi wa ni gbogbo ibi ti wọn ba ti n ṣe ofin to niiṣe pẹlu eto ilera ki awọn naa le ni ohun to gbopọn lati pe fun ẹtọ ẹgbẹ naa.

Bakan naa ni wọn fẹ ki ijọba apapọ ṣe agbekalẹ ajọ ti yoo maa ṣe eto bi awọn Nọọsi to ba ṣẹṣẹ kẹkọọ pari yoo ṣe maa ni anfani lati ṣe amulọ awọn nnkan ti wọn ti kọ ni awọn ile iwosan to n bẹ layika wọn ki wọn to lọ ṣe agunbanirọ.

O tẹsiwaju wi pe ijọba ni lati maa san owo to kaju wahala ti awọn Nọọsi n ṣe lẹnu iṣẹ wọn, nitori ko si akoko ti ẹ de ile iwosan ti ẹ ko ni ri Nọọsi nibẹ.

Ki ni yoo ṣẹlẹ bi ijọba ba kọ lati da wọn lohun laarin ọjọ meje?

Awọn nọọsi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Laarin Ọjọru, ọgbọn ọjọ oṣu keje si ọjọ kaarun oṣu kẹjọ ni iyanṣẹlodi ọlọjọ meje naa yoo fi waye. Bi ijọba ba kọ lati da awọn ẹgbẹ naa lohun lẹyin ọjọ meje akọkọ yii, wọn o tun gunle iyanṣẹlodi ọlọjọ mọkanlelogun lati kilọ fun ijọba.

Ti nnkan ko ba ṣe ẹnure lẹyin ọjọ mọkanlelogun, ẹgbẹ naa yoo bẹrẹ iyanṣẹlodi ọlọgbọnrangandan ti ko ni gbendeke.

Saaju asiko yii ni ẹgbẹ awọn Nọọsi ati Agbẹbi orilẹede Naijiria ti maa fi iyanṣẹlodi beere eto wọn lọwọ ijọba. Laarin ọdun 2021 si ọdun yii, bii igba mẹrin ọtọọtọ ni ẹgbẹ naa ti gunlẹ iyanṣẹlodi lati beere ẹtọ wọn lọwọ ijọba.

Ìdí rèé táwọn nọ́ọ̀sì fi bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì yíká Naijiria, táwọn dókítà sì ń múra tiwọn

Ẹgbẹ awọn nọọsi lawọn ile iwosan ijọba apapọ ni Naijiria ti bẹrẹ iyanṣẹlodi kaakiri awọn ile iwosan lonii Ọjọru.

Awọn nọọsi naa labẹ asia ẹgbẹ National Association of Nigeria Nurses and Midwives (NANNM), ti apapọ wọn le ni ẹgbẹrun marundinlọgbọn sọ pe iyanṣẹlodi naa yoo waye fun ọjọ meje gbako.

Iyanṣelodi yii ni wọn fi n fa ijọba apapọ leti lati ṣe awọn ohun ti wọn n fẹ, bii bẹ kọ wọn ni awọn yoo bẹrẹ iyanṣẹlodi ọlọjọ gbọọrọ.

Ṣaaju ni NANNM ti kọkọ fun ijọba apapọ ni ọjọ marundinlgun ko to gunle iyanṣelodi ọlọjọ meje yii.

Ohun to fa iyanṣẹlodi yii

Ohun to fa iyansẹlodi naa ko ṣẹyin ọwọ ti ijọba Naijiria fi n mu itọju awọn oṣiṣẹ eto ilera ọhun.

Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ, alaga NANNM-FHI, Morakinyo Rilwan, sọ pe awọn nọọsi naa ko ni da si iṣẹ kankan lawọn ile iwosan ijọba kaakiri Naijiria lasiko ti iyanṣẹlodi ọhun ba n lọ lọwọ.

Morakinyo sọ pe "ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Keje, ọdun 2025 ni gbedeke ọjọ marundinlogun ti a fun ijọba pe laago mejila oru, bẹrẹ lati aago mejila oru kọja iṣẹju kan, ni a o bẹrẹ iyanṣẹlodi naa.

"Iyanṣẹlodi yii ko kan awọn nọọsi nile iwosan aladani nitori awọn ileewosan aladani ko kari gbogbo Naijiria."

Gẹgẹ bo ṣe sọ, wọn gunle iyanṣelodi naa latari owo ti ko to nnkan ti ijọba n san, oṣiṣẹ ti ko to, owo ti ijọba jẹ awọn ati eto abo ti ko si fun awọn lẹnu iṣẹ.

Wayi o, ikilọ lasan ni iyanṣelofi ọlọjọ meje yii jẹ ki wọn to bẹrẹ iyanṣẹlodi ọlọjọ gbọrọ laipẹ.

Ẹgbẹ dokita yoo bẹrẹ iyanṣẹlodi tiwọn lẹyin ọjọ mọkanlelogun

Ẹgbẹ awọn dokita, NMA naa ti sọ pe awọn yoo bẹrẹ iyanṣẹlọdi wọn lẹyin ti wọn fun ijọba apapọ ni ọjọ mọkanlelogun lati da si ohun ti wọn n bere lati ọpọ ọdun sẹyin.

Nibi ipade pajawiri kan ti ẹgbẹ naa ṣe niluu Abuja, wọn ni ijọba ti ja awọn kulẹ pẹlu bo ṣe kọ lati mu awọn ileri rẹ to ti ṣe fun awọn ṣe lẹyin ọpọ ọdun.

Ninu atẹjade kan ti Aarẹ ẹgbẹ ọhun, Bala Audu ati akọwe rẹ, Jamin Egbo buwọlu, wọn ni iyanṣelodi awọn yoo pada gberasọ laipẹ.

Lara awọn ohun ti awọn dokita naa bere fun ni atunṣe ilana sisan owo oṣu wọn, iyẹn National Salaries, Income and Wages Commission, NSIWC, ati Consolidated Medical Salary Scale, CONMESS.