Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí àgọ́ ara rẹ tí èèyàn kò bá jẹun fún ọjọ́ pípẹ́?

Awọn aṣatipo to fẹ gba ounjẹ

Oríṣun àwòrán, Anadolu/Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọpọ eeyan kaakiri agbaye lo n kọminu lori ipo ti awọn eeyan wa ni Gaza
    • Author, Rebecca Thorn and Angela Henshall
    • Role, BBC WS Health
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Nnkan bii eeyan kan ninu mẹta awọn to wa ni Gaza lo n gbe fun ọpọ ọjọ lai ri ounjẹ kankan je.

Gẹgẹ bii Aarẹ Donald Trump ṣe sọ, ebi ọpagba n ba ọpọ eeyan finra ni Gaza lẹyin ti olootu ijọba Israel, Benjamin Netanyahu sọ pe ko si nnkan to jọ bẹẹ.

Laarin ọjọ diẹ sẹyin ni Israel to sọ pe ko si ebi ni Gaza kede pe oun ti bẹgi dina ohun iranwọ to n wọ agbegbe naa.

Adari ẹka to n ri si ọrọ ọmọniyan ninu ajọ UN, Tom Fletcher ti sọ pe wọn nilo ọpọ ounjẹ lati wọ Gaza lọna ati koju ebi to n kou awọn eeyan nibẹ.

Ajọ United Nation's Palestinian refugee agency (Unrwa) sọ pe ọmọ kan ninu ọmọde marun un ni ko ri ounjẹ jẹ ni Gaza.

Ajọ UN ni ọpọ eeyan lo tu dero ile iwosan latari ibi ti ebi pa wọn de, ti awọn mii si n daku rọgbọnda laarin igboro.

Bo tilẹ jẹ pe UN ko tii kede iyan nilẹ naa, ajọ IPC ni iyan ti n kan ilẹkun awọn eeyan agbegbe ọhun.

Ki ni iyan, ati pe igba wo ni wọn le kede iyan?

Ajọ Integrated Food Security Phase Classification (IPC) ni ajọ agbaye ti wọn n lo lati ṣe idinwọn bi awọn eeyan lagbaye ṣe lanfani si ounjẹ aṣaraloore si.

Ipele to ga julọ ninu idinwọn wọn ti wọn n pe ni - Phase 5 Famine – ni igba ti ti irufẹ nnnkan bayii ba waye.

  • Igba ti ida 20% awọn idile ko ba ri ounjẹ jẹ
  • Igba ti o kere tan, 30% awọn ọmọde ko ba ri ounjẹ jẹ
  • Igba ti o kere tan, agbalagba meji tabi ọmọde mẹrin ninu ẹgbẹrun mẹwaa eeyan ba n ku lojojumọ latari pe wọn ko ri ounjẹ jẹ tabi ti wọn n ku nitori arun

Atẹjade IPC nipa Gaza lọjọ kejila, oṣu Karun un, ọdun 2025 sọ pe gbogbo awọn eeyan Gaza lo n gbe ni ipele 'Phase 3' tabi ju bẹẹ lọ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ 459,500 eeyan ni ko ni ri ounjẹ jẹ, iyẹn IPC Phase 3 laarin oṣu Karun un si oṣu Kesan an, ọdun 2025.

Ni kete ti ọrọ ba ti de ipele yi, ajọ UN yoo kede iyan, lọpọ igba, pẹlu ajọsẹpọ ijọba orilẹede ti iyan n ja, nigba mii wọn tun maa n kede pẹlu awọn ajọ mii lagbaye.

Awọn eeyan Palestine ti wọn n gbe apo ounjẹ rekoja si ariwa Gaza

Oríṣun àwòrán, Majdi Fathi/NurPhoto/Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn eeyan Palestine ti wọn n gbe apo ounjẹ rekoja si ariwa Gaza

Ki ni yoo ṣẹlẹ ninu agọ ara ẹni ti iyan ba n ja?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Iyan yoo ṣẹlẹ ti agọ ara ko ba ri ounjẹ eyii ti yoo fun ni iwọn kalori to nilo lai ṣiṣẹ daadaa.

Ti ara ba ri ounjẹ, yoo pin ara rẹ si awọn gulukosi, amọ ti ko ba ri ounjẹ, ara yoo pin ara rẹ si awọn 'glycogen' ninu ifun ati iṣan ara lọna ati le ri gulukosi sinu ẹjẹ.

Ti ara ko ba ri awọn eroja yii, agọ ara yoo bẹrẹ si n lo awọn ọra ati iṣan ara lati le fun ni agbara.

Airi ounjẹ jẹ le maa mu ki ifun, ẹdọforro atawọn ohun to wa ninu eeyan miran ma kere si, eyii si le ṣakoba fun ọpọlọ, to le jẹ ki eeyan maa ri irikuri.

Bo tilẹ jẹ pe iyan le gbẹmi eeyan, awọn mii maa n ku latari oniruru akoba ti airi ounjẹ ti ṣe sinu agọ ara wọn ṣaaju.

Oniruru ọna ni airi ounjẹ fi n da agọ ara eeyan laamu.

Onimọ nipa ounjẹ kan ni fasiti Glasgow, nilẹ Gẹẹsi, Charlotte Wright, sọ pe oniruru aisan lo le ṣe awọn ọmọde ti iyan ba n ja.

O ni "awọn ọmọde ti ara wọn le koko tẹlẹ amọ ti iyan ti n ja bayii yoo ṣi ni okun lati jẹun ki ounjẹ naa si ṣiṣẹ ninu agọ ara wọn ti wọn a ri ounjẹ. Niṣe ni awọn to ku yoo ṣofo danu.

Ohun to le ṣẹ si agọ ara ti eeyan ko ba jẹun fun igba pipẹ
Àkọlé àwòrán, Ohun to le ṣẹ si agọ ara ti eeyan ko ba jẹun fun igba pipẹ

Bawo ni airi ounjẹ jẹ ṣe le daamu awọn ọmọ wẹwẹ?

Ti ọmọde ko ba ri ounjẹ jẹ lati kekere, o le ṣe akoba fun igbasoke rẹ.

Ajọ WHO sọ pe o ṣeeṣe ki ọmọde ti ko ri ounjẹ to tọ je ni kekere kuru ju ọjọ ori rẹ lọ.

Awọn eeyan ti ebi n ba finra le bi ọmọ ti ko lokun daadaa gẹgẹ bii ọrọ ti ajọ United Nations Foundation, sọ.

Ni ti ajọ Unicef, o ni ti obinrin ko ba jẹun to lasiko to wa ninu oyun, o le ṣakoba fun ọmọ inu rẹ ati pe to ba bi ọmọ naa tan, o le da ẹmi irufẹ iya bẹẹ legbodo.

Awọn alaboyun ti wọn ko ri ounjẹ to tọ jẹ yoo ni iṣoro lati pese omi ọmu fun ọmọ ti wọn ba bi.

Nuradeen Alibaba lati ajọ Médecins Sans Frontières to gbajumọ itọju ọmọde ti wọn ko ri ounjẹ to tọ jẹ sọ pe atubọtan rẹ le ṣakoba fun awọn ọmọde bẹẹ titi aye.

O ni "wọn ko ni dagba daadaa, to n tumọ si pe wọn yoo kuru ju ọjọ ori wọn lọ koda ti wọn ba pada bẹrẹ si n jẹun.

"Fun awọn mii, yo ṣoro fun wọn lati kawe ati lati mọwe ti wọn bẹrẹ ile ẹkọ tan.

Ounjé ti wọn n pin fun awọn eeyan Palestine ni Gaza

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ounjé ti wọn n pin fun awọn eeyan Palestine ni Gaza

Itọju airi ounje to tọ jẹ

Awọn onimọ ti sọ pe ọna abayọ si isọro yii ni ki wọn ko ọpọlọpọ ounjẹ atawọn ounjẹ aṣaraloore lọ si Gaza.

Ọjọgbọn Wright sọ pe "wọn gbọdọ ko ounjẹ lọ fun awọn ọmọde atawọn iya wọn ni kankan.

"Omi ọmu lo dara julọ fun awọn ọmọ tuntun amọ a gbọdọ fun iya wọn lounjẹ to daa ki wọn to le fun awọn ọmọ wọn lọmu to yẹ.

"Iṣoro ti a n koju bayii ni bi ounjẹ naa yoo ṣe kan awọn iya wọn awọn ọmọ wọnyi lara.

"Koko ọrọ mi ni pe ati iya, atawọn ọmọ wọn ni ounjẹ to tọ gbọdọ to lowọ ni kiakia."

O pari ọrọ rẹ pe "ki n kan n ṣe ki a fun wọn lounjẹ nikan amọ a gbọdọ fun wọn ni ounjẹ ti yoo ṣe agọ ara wọn loore."