Ajínigbé bẹ́ orí èèyàn 38, ọ̀pọ̀ èèyàn bomi lójú

Aworan ọpọ eeyan nibi ti wọn ti n sinku

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn ajinigbe agbebọn kan ti bẹ ori eeyan mejidinlogoji (38) ninu awọn mẹrindinlọgọta (56) ti wọn ji gbe ni ipinlẹ Zamfara.

Olugbe Abule Banga, nijọba ibilẹ Namoda ni awọn ti wọn bẹ lori naa.

Gẹgẹ bi iroyin ṣe wi, wọn bẹ wọn lori nitori wọn ko ri owo itusilẹ san.

Alaga ijọba ibilẹ naa, Manniru Haidara Kaura, ṣalaye fun BBC pe ọdọkunrin lo pọ ninu awọn ti wọn pa naa.

Báwo ló ṣe ṣẹlẹ̀ gan-an?

O ti pe oṣu mẹrin bayii ti awọn ajinigbe agbebọn naa ti wọ abule Banga, ti wọn si ji eeyan mẹrindinlọgọta lọ.

Nigba to n tẹsiwaju ninu alaye rẹ, Alaga ijọba ibilẹ Namoda, Manniru Haidara Kaura, sọ pe:

"Ohun ti a gbọ ni pe wọn dumbu wọn ni.

"Ohun to ṣẹlẹ ni pe awọn agbebọn beere miliọnu lọna aadọta naira owo itusilẹ (50million), a si gbọ pe wọn ti fun wọn.

"Wọn yọnda awọn mejidinlogun ninu wọn lọjọ Satide, obinrin mẹtadinlogun ati ọmọ kekere kan.

" Ṣugbọn wọn tun pinnu lati pa eeyan mejidinlogoji ninu awọn ti wọn mu si igbekun naa.

"Awọn ni wọn mọ idi ti wọn fi pa wọn, wọn o lọpọlọ lori rara. Wọn gbagbe pe awọn eeyan awọn naa lawọn n pa, ati pe a maa pade niwaju Ọlọrun."

Alaga fi kun un pe ileewosan ni awọn mẹrindinlogun ninu awọn ti wọn fi silẹ naa ṣi wa, ti wọn n gba itọju.

O ni wọn ko gbe oku awọn ti wọn pa silẹ.

'Ààbò kò sí lágbègbè wa'

Nigba to n sọrọ nipa aabo, Kaura sọ pe bo tilẹ jẹ pe oun maa n fi eti gbọ ọ pe awọn ẹṣọ alaabo n ṣiṣẹ ni awọn ibo mi-in, o ni ko ri bẹẹ lọdọ awọn.

"Ka ma parọ, awọn ẹṣọ alaabo ko ran wa lọwọ rara nibi. Awọn to n ran wa lọwọ ninu wọn ko ju awọn ṣọja lọ lati Zamfara lọ."

Ṣugbọn ninu awijare awọn ṣọja, wọn ni awọn n ṣe iwọn ti awọn le sẹ.

Ọpọ igba ni wọn ti tako awọn ti wọn n fẹsun kan wọn, pe wọn ko kapa awọn agbebọn to n ṣọṣẹ kiri agbegbe lorilẹede yii.

Wọn ni araalu ki i fi ohun to n ṣẹlẹ to awọn leti lasiko nigba mi-in.

Ati pe igba mi-in wa ti wọn ki i mọ bi igbiyanju awọn lori ki alaafia le jọba ṣe to.