Àràmàǹdà ọmọ ọdún kan gé ejò Ọká jẹ tó fi kú

Oríṣun àwòrán, Aloka Kumar
- Author, Situ Tiwari
- Role, BBC Reporter
- Reporting from, Bihar, India
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3
Ọmọ ọdun kan lorilẹede India ti di olokiki ni ilu rẹ lẹyin to fi eyin rẹ ṣekupa ejo oloro, Ọka ni ọjọ Kẹrinlelogun Oṣu keje.
Govind Kumar ni o n ṣe ere ni agbala ni ile awọn obi rẹ ni abule Mohchi Bankatwa ni ila oorun ipinlẹ Bihar to sunmọ ẹnu ibode Napal, nigba to fi oju kan ejo ọhun.
"Iya rẹ n sisẹ ni ẹyinkule," Iya iya Govind, Matisari Devi sọ. "O mu ejo naa, to si fi eyin rẹ bujẹ.
Nigba ti a sunmọ ni a ri pe ejo ọka ni," o fikun.
Lasiko yii ni Govind daku, ti awọn mọlẹbi rẹ si saare gbe lọ si ile iwosan.
"Nigba ti wọn gbe ọmọ wa si ile iwosan, a ri pe oju rẹ wu, paapa ẹnu rẹ,"
Dokita Kumar Saurabh, to ṣe itọju Govind ni ile iwosan ijọba ni olu ilu Bihar, Bettiah sọ.
O fikun pe lọjọ ti iṣẹlẹ naa waye, oun ti kọkọ ṣe itọju ọmọde, ti ejo bu jẹ. Ṣugbọn, awọn ọmọde mejeeji wa alaafia.

Oríṣun àwòrán, Aloka Kumar
Dr Saurabh ṣalaye pe iṣẹlẹ mejeeji lo lewu pupọ ṣugbọn ọkan ju ara wọn lọ.
"Ti Ọka ba bu eeyan jẹ, oro rẹ ma n lọ sinu ẹjẹ, ti eyi si le ja si iku", o sọ fun BBC.
"Ti eeyan ba bu ọka jẹ, oro yoo lọ sinu iku. Ara wa petu si oro naa, ti yoo si gba ile igbẹ sita,"
Dokita Saurabh fikun pe, iṣẹlẹ naa le e le ju agbara lọ to ba jẹ pe egbo wa, ti ẹjẹ n jade lasiko ti eeyan bu ejo jẹ.
India jẹ ile fun o le ni 300 orisiris ejo, to si jẹ pe ọgọta ninu wọn ni wọn jẹ ejo oloro.
Orilẹede naa ni wọn ti ṣapejuwe gẹgẹ bi olu ilu fun ikọlu ejo lagbaye, to si jẹ pe afikun n ba iye eeyan to n padanu ẹmi wọn sọwọ ikọlu ejo.
Ajọ eleto ilera lagbaye ni o le ni eeyan 81,000 si 138,000 ti ikọlu ejo n ṣekupa lọdọọdun.
Laarin ọdun 2000 si 2019, o le ni eeyan 58,000 ti wọn padanu ẹmi wọn nitori ikọlu ejo lọdọọdun ni orilẹede India.
Ṣugbọn iye eeyan to padanu ẹmi wọn sọwọ ikọlu ejo ni o pọju iye ti wọn n gbe sita nitori bi eto ilera ko ṣe de awọn agbegbe kan ti iṣẹlẹ ọhun ti n waye, gẹgẹ bi ajọ eleto ilera India ṣe ṣalaye.















