Tinubu fi oyè, owó àti ilé dá àwọn agbábọ́ọ̀lù Super Falcons lọ́lá

Rasheedat Ajibade ná ife ẹ̀yẹ tí wọ́n gbà sókè
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ààrẹ Bola Tinubu ti fi ẹ̀bùn ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó, ilé àti oyè dá àwọn agbábọ́ọ̀lù Super Falcons lọ́lá láti ṣe kóríyá fún wọn látàrí bí wọ́n ṣe gba ife ẹ̀yẹ bọ́ọ̀lù 2024 Women Africa Cup of Nations.

Ní ilé ààrẹ Aso Rock tó wà ní ìlú Abuja ni ààrẹ ti gbàlejò àwọn agbábọ́ọ̀lù náà lẹ́yìn tí wọ́n padà sí Nàìjíríà láti Morocco tí ìdíje náà ti wáyé.

Níbi ètò náà ni olórí ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Super Falcons, Rasheedat Ajibade ṣe àgbékalẹ̀ ife ẹ̀yẹ náà fún Ààrẹ Tinubu, tí aṣọ́lé Super Falcons, Chiamaka Nnadozie náà ṣe àgbékalẹ̀ àmì ẹ̀yẹ rẹ̀ fún ààrẹ.

Tinubu ṣàlàyé bí òun kò ṣe fẹ́ wo ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà nítorí ẹ̀jẹ̀ rúru ṣùgbọ́n tó kan sáárá sáwọn ọmọbìnrin fún iṣẹ́ takuntakun tí wọ́n ṣe lásìkò ìdíje ọ̀hún.

"Ní orúkọ gbogbo àwọn ọmọ Nàìjíríà tó ń dúpẹ́ lọ́wọ́ yín, mo fi oyè Officer of the Order of the Niger, OON, dá a yín lọ́lá," Tinubu sọ.

"Ní àfikún, mo darí àwọn iléeṣẹ́ tó ń ṣe àkóso ilé ìgbé Renewed Hope Housing Estate láti fún ẹnìkọ̀ọ̀kan ní ilé oní yàrá mẹ́ta mẹ́ta.

Bákan náà ni ààrẹ tún kéde fífún àwọn agbábọ́ọ̀lù náà ní owó náírà tí iye rẹ̀ jẹ́ $100,000 fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn agbábọ́ọ̀lù mẹ́rìnlélógún náà àti $50,000 fáwọn akọ́nimọ̀ọ́gbá wọn.

Níbi ayẹyẹ náà ni alága àwọn gómìnà Nàìjíríà tó tún jẹ́ gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara kéde fífún àwọn agbábọ́ọ̀lù náà ní mílíọ̀nù mẹ́wàá náírà fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn àtàwọn akọ́nimọ̀ọ́gbá wọn.

Àwọn olólùfẹ́ Super Falcons rí ìjákulẹ̀ báwọn agbábọ́ọ̀lù kò ṣe ṣe ìwọ́de mọ́

Ọkọ̀ tí èròńgbà wà pé àwọn agbábọ́ọ̀lù fi máa ṣe ìwọ́de yíká Abuja
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ṣáájú ni ikọ̀ ìròyìn BBC ti wà ní pápá ìṣeré Abuja níbi tó yẹ káwọn agbábọ́ọ̀lù náà balẹ̀ sí ní nǹkan bíi aago méjìlá ọ̀sán bí wọ́n ṣe ń bọ̀ láti Morocco àmọ́ tó jẹ́ pé aago méjì ọ̀sán kọjá kí wọ́n tó dé.

Ìròyìn tó ti kọ́kọ́ gba ìgbooro ni pé àwọn agbábọ́ọ̀lù náà máa yíde gbogbo ìlú Abuja pẹ̀lú ife ẹ̀yẹ wọn tí wọ́n bá ti balẹ̀ sí Nàìjíríà.

Akọ̀wé ìjọba Nàìjíríà, George Akume àtàwọn mínísítà míì ló gba àwọn agbábọ́ọ̀lù ní àlejò bí wọ́n ṣe ń bọ́lẹ̀ nínú ọkọ̀ òfurufú wọn.

Ajibade na ife ẹ̀yẹ náà sókè bí wọ́n ṣe ń sọ̀kalẹ̀ táwọn eléré sì ṣeré pàdé wọn.

Lẹ́yìn ìpàdé ráńpẹ́ ni àwọn agbábọ́ọ̀lù náà kó sí inú ọkọ̀ tí wọ́n sì bá ojú ọ̀nà míì kúrò ní pápákọ̀ òfurufú náà.

Èyí jẹ́ ìjákulẹ̀ fáwọn olólùfẹ́ wọn tí wọ́n ti ń dúró dè wọ́n lẹ́nu ọ̀nà lójúnà àti báwọn ṣe ẹ̀yẹ lórí ìjáwé olúborí wọn.

Àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò ló padà sọ fún àwọn èèyàn náà pé àwọn obìnrin náà ti lọ.

Ìdí táwọn aláṣẹ kò ṣe jẹ́ káwọn ọmọbìnrin náà kí àwọn èèyàn kò yéni àmọ́ òjò rọ̀ láti òwúrọ̀ ní Abuja di ìgbà tí àwọn ọmọbìnrin náà fi balẹ̀.

Ikọ̀ ìròyìn BBC rí ọkọ̀ tí NFF gbé kalẹ̀ láti jẹ́ káwọn agbábọ́ọ̀lù náà ṣe ìwọ́de káàkiri Abuja kí àwọn ọmọ Nàìjíríà le yẹ́ wọn sí.