Òpó iná alágbára wó, iná ọba lọ, aráàlù pàdánù dúkìá olówó iyebíye bí ilẹ̀ rírí ṣe ṣọṣẹ́

Ẹkun omi lile kan ree to n ṣan gba awọn ile to wa nitosi odo kọja, eyi waye lẹyin ilẹ riri nla to ṣẹlẹ ni Kamchatka Peninsula, ni Severo-Kurilsk, agbegbe Sakhalin orilẹede Russia, lonii ọgbọnjọ, oṣu Keje 2025.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Ẹkun omi lile kan ree to n ṣan gba awọn ile to wa nitosi odo kọja, eyi waye lẹyin ilẹ riri nla to ṣẹlẹ ni Kamchatka Peninsula
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Alagbalugbu omi Tsunami to bẹrẹ laaarọ Ọjọruu, eyi to ti ara ilẹ riri wa, bẹrẹ pẹlu iwọn ida mẹjọ le mẹjọ (8.8 magnitude) ni ẹkun-un Ila- Oorun Kamchatka Peninsula lorilẹede Russia, o si ti n de Hawaii pẹlu bayii.

Ikun omi to n ya naa ni a gbọ pe ọwọ rẹ le pupọ, giga rẹ to pọ ju si to iwọn ẹsẹ bata mẹrin 4ft (1.21m), laaarin iṣẹju mejila sira wọn lo fi n ru soke wa si Haleiwa, Oahu, gẹgẹ bi ẹka ikilọ ẹkun omi, (Pacific Tsunami Warning Center) ṣe ṣalaye.

Ninu ọrọ rẹ, Gomina Josh Green, sọ pe awọn ko ti i ri omi naa ko ga, ṣugbọn awọn n ri oye pe o ti n fà.

Bakan naa ni aṣẹ ti wa pe ki wọn maa ko awọn eeyan ati dukia kuro ni Japan ati US, nigba ti China, Philippines, Indonesia, New Zealand, Peru ati Mexico ti ranṣẹ ikilọ si awọn eeyan rẹ, pe ki wọn ṣọra fun ẹkun omi.

Pẹlu bi omi naa ṣe jin ni iwọn kilomita mejidinlogun (18km), ilẹ riri to mu wa ko jin, oun mu Tsunami iwọn mita mẹta si mẹrin dani ni Kamchatka. Minisita fun iṣẹlẹ pajawiri, Sergei Lebedev, lo ṣalaye bẹẹ.

"Ilẹ riri toni lagbara gan-an, ibugbamu rẹ lo si le ju lati ọdun gbọọrọ ta a ti gbọ iru rẹ sẹyin."

Gomina Kamchatka, Vladimir Solodov lo sọ bẹẹ ninu fidio kan to fi si oju opo Telegram .

Bi ilẹ riri naa ṣe lagbara ni onka 8.8, oye foju han pe oun ni ẹlẹẹkẹfa iru rẹ to lagbara ju ninu itan. 2010 ni ilẹ riri waye ni Biobío, Chile, ati eyi to waye ni 1906 ni Esmeraldas, Ecuador.

Ni apa Sakhalin, nilẹ Russia, wọn ti kede ilu o fararọ, bẹẹ ni wọn ṣe ni apa Ariwa Kuril Islands ati ni ẹkun-un Severo-Kurilsk .

Alakooso Kuril Islands, Alexander Ovsyannikov, ṣalaye pe "gbogbo eeyan to wa lagbegbe naa lati ko kuro. " Aaye wa fun wa lati ko wọn, odidi wakati kan. Fun idi eyi, gbogbo wọn la ko kuro, gbogbo wọn ti wa lapa ibi ti Tsunami ko le de."

Bẹẹ ni ẹka iroyin AFP royin.

Ṣaa, fidio kan ṣafihan ẹkun omi to gba agbegbe kan ti okun wa ni Severo-Kurilsk, eeyan ẹgbẹrun meji lo wa niluu naa.

Òpó iná agbára wó, iná ọba lọ

Ina mọnamọna ko si mọ ni awọn agbegbe kan bayii, eyi waye lẹyin ti ilẹ riri ba opo ina agbara kan jẹ ni Sakhalin, gẹgẹ bi ẹka iroyin RIA News Agency ṣe wi.

Ọpọ eeyan lo farapa ni Russia, ẹka iroyin TASS lo ro eyi. Awọn mi-in farapa lasiko ti wọn mura lati kuro nibẹ, titi kan obinrin kan to bẹ jade lati oju ferese.

Ṣugbọn Minisita ọrọ ilera, Oleg Melnikov, ṣalaye pe gbogbo awọn eeyan naa ni wọn wa ni alaafia, o ni awọn ko ti i ni akọsilẹ ifarapa to le ju kankan.

Bakan naa ni ileewe alakọọbẹrẹ kan ni Petropavlovsk-Kamchatsky, Kamchatka naa bajẹ, bi aworan akọkọ to ti Kamchatka ṣe ṣafihan rẹ.

Ilẹ riri Ọjọruu yii to gba agbegbe Kamchatka Peninsula kọja ni wọn lo le ju ninu itan lati 1952,bẹẹ ni awọn alaṣẹ n kilọ pe ki araalu ṣọra fun ilẹ riri mi-in to le tun waye, bi ko tiẹ to eyi.

"Ilẹ riri miran to foju han kedere le tun waye, o le to iwọn 7.5, o si le waye fun oṣu kan gbako."

Bẹẹ ni ẹka Geophysical Service ni Russia, kilọ.

Aworan ileewe alakọọbẹrẹ kan ti ilẹ riri dawo ni Petropavlovsk-Kamchatsky Petropavlovsk-Kamchatsky, Kamchatka Krai, Russia, ni ọgbọnjọ, oṣu Keje ọdun, 2025

Oríṣun àwòrán, Handout via Reuters

Àkọlé àwòrán, Aworan ileewe alakọọbẹrẹ kan ti ilẹ riri dawo ni Petropavlovsk-Kamchatsky.

Ẹ̀kún omi líle gba Japan

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ẹkun omi alakọkọ iru rẹ ti kọlu orilẹede Japan.

Bi wọn ṣe foju inu wo o, yoo to iwọn ọgbọn sẹntimita 30cm (12in), agbegbe kan ti a mọ si Nemuro, ilu naa to ni ibudokọ oju omi ni ẹkun -un Hokkaido lo kan.

Ṣaaju ni awọn alaṣẹ Japan si ti kilọ pe ẹkun omi naa le ga ni iwọn mita mẹta( 3m high).

Ikilọ Japan naa ti de kilomita ọgọrun-un loju ọna agbami okun Pacific, lati Hokkaido, eyi to wa ni Ariwa Wakayama. Eeyan to to miliọnu meji ni wọn ti kilọ fun pe ki wọn fi ibẹ silẹ lọgan.

Gẹgẹ bi ileeṣẹ TEPCO to n bojuto ẹka Fukushima Daiichi nuclear powerplant, ṣe wi, gbogbo awọ oṣiṣẹ ibẹ ni wọn ti ko kuro. Wọn fi kun un pe ko si wahala to kọja agbara awọn latigba ti ẹkun omi naa ti bẹrẹ.

Ẹka Fukushima Daiichi plant ni ibudo ti nnkan ti n ro gbamu wa nigba ti Tsumami alagbara ṣẹlẹ ni 2011. Eyi to le ni iwọn mẹsan-an (9.0 magnitude) ni Japan.

Bakan naa ni wọn ṣe n kilọ iṣọra fun wọn ni US, Hawaii ati awọn apa kan Alaska, eyi to tumọ si pe kawọn eeyan tete gbe igbesẹ to le da aabo bo wọn pẹlu dukia wọn nipa kiko lọ si ilẹ giga.

California, Oregon ati Washington naa gba ikilọ, wọn ni ki wọn lọọ mọ pe iku to n pa ojugba ẹni, owe lo n pa fun ni.

"Ẹ DURO ṢINṢIN KẸ Ẹ SI RI I PE AABO WA FUN YIN!" Bẹẹ ni Aarẹ Donald Trump kọ ọ soju opo X rẹ.

Wọn ti ṣeto bayii lati ko awọn eeyan kuro ni awọn agbegba kan ni Hawaii, gẹgẹ bi ẹka iroyin Reuters ṣe ro o. "Mo rọ yin pe kẹ ẹ fi ara balẹ. Bi o ba wa ni apa ibi to sun mọ ilẹ pẹpẹ, jọwọ ko lọ si apa oke."

Ọgbẹni Green lo sọ bẹẹ ṣaaju ẹkun omi ti wọn ti mọ pe yoo ṣẹlẹ naa.

DL Scales, ẹni kan to n lo isinmi rẹ lọwọ ni Wailea, Maui, sọ fun BBC pe niṣe loun ha si sunkẹẹrẹ fakẹẹrẹ ọkọ, pẹlu ọpọ eeyan ti wọn waa lo isinmi wọn ṣugbọn to ti di dandan fun wọn bayii lati wa ilẹ giga lọ ki omi ma baa pa wọn.

"Ko fi bẹẹ le bẹẹ yẹn naa, kalulu n gbiyanju lati jade. Mi o mọ ibi tawọn eeyan n lọ. Wọn tiẹ ti fọn fere ni iṣẹju diẹ sẹyin, to tumọ si pe awọn eeyan le bẹrẹ si i wa mọto wọn lọ."

O ni awọn arinrinajo nikan lo n ko aya soke nitori ẹru to n ba wọn.

Lilọ bibọ ọkọ ati tawọn eeyan ko ja gaara mọ ni Hawaii lẹyin ikilọ Tsunami.

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán, Lilọ bibọ ọkọ ati tawọn eeyan ko ja gaara mọ ni Hawaii lẹyin ikilọ Tsunami.

Wọ́n ń dínà mọ́ omi ní àwọn apá ibì kan ni Maui

Ọpọ agbegbe ni wọn ti n dina mọ omi lati ma kọja ni Maui, eyi ti i ṣe erekuṣu Hawaiia, "wọn n ṣe bẹẹ ni ibamu pẹlu ikilọ ati iṣọra".

Onimọ nipa ilẹ riri, Dokita Lucy Jones, ṣalaye fun BBC pe ẹkun omi Tsunami yii le ba ibi ti wọn n ko awọn ọkọ oju omi si jẹ, o si le ṣakoba fun awọn bebe omi pẹlu ni Hawaii. O ni o ṣee ṣe ko kan California naa.

Dokita Lucy fi kun un pe ṣugbọn oun ko ro pe o le fa ki ẹmi eeyan sọnu tabi adanu kan lawọn apa ilẹ America.

Giga ẹkun omi Tsunami naa ni Hawaii la gbọ pe o le to iwọn ẹsẹ bata mẹta si mẹfa, nigba to le jẹ ẹsẹ bata kan si meji ni Santa Barbara.

Jones sọ pe ni 2011, iwọn ẹkun omi naa ni ẹsẹ bata mejilelogoji ( 42 feet).

"Ki i ṣe bi omi ṣe n ru, bi gbogbo odo yẹn ṣe n dide lẹẹkọọka ni"

Dokita Lucy Jones lo sọ bẹẹ.