Ẹ̀gbọ́n gé orí abúrò rẹ̀ l‘Ondo, aráàlú dá àjọ ìyà fun, ọ̀rọ̀ bá bẹ́yìn yọ

Oríṣun àwòrán, Ondo Connect
Ọkunrin ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn kan ti ge ori aburo rẹ niluu Odigbo, nipinlẹ Ondo.
A gbọ pe agbegbe odo Origbara ni iṣẹlẹ naa ti waye lọjọ Aje.
Awọn fidio kan lori ayelujara ṣafihan bi awọn araalu ṣe n din dundu iya fun afurasi naa to gbe ori aburẹ rẹ to pa naa lọwọ.
Iroyin ni ọmọ ọlọpaa kan ti ọpọ eeeyan mọ si 'Awilo' lagbegbe naa, ni tẹgbọn-taburo ọhun.
A ti bẹrẹ iwadii – Ọlọpaa
Nigba ti BBC Yoruba kan si ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo lori iṣẹlẹ naa, alukoro ileeṣẹ ọhun, Ayanlade Olayinka Olusola fidi rẹ mulẹ.
O ni "Lootọ ni iṣẹlẹ naa waye, kọmiṣọna ọlọpaa, Lawal Adebowale ti paṣẹ ki iwadii bẹrẹ ni kankan lati mọ kulẹlulẹ ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ naa.
"Kọmiṣọna tun ti paṣẹ ki wọn taari ẹjọ naa si ẹka to n ṣewadii iwa ọdaran, CID, fun iwadii ni kikun."
Alukoro ọlọpaa naa ṣalaye siwaju si pe ọmọ baba kan naa ni afurasi ati ẹni to ge ori rẹ.
Bo tilẹ jẹ pe o kọ lati fi orukọ awọn mejeji lede, o ni ọmọ ọdun marundinlogun ni aburo ti wọn ge ori rẹ, ti ẹgbọn to ge ori aburo rẹ si jẹ ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn.
"Afurasi jade laye lẹyin ti awọn eeyan lu u nilu bara"
Ayanlade ni afurasi naa ti jade laye lẹyin ti awọn araalu lu u ni ilu bara lẹyin ti wọn ka ori aburo rẹ mọ lọwọ.
O ni "ile iwosan lo ku si, nigba ti awọn araalu ka ori aburo rẹ mọ lọwọ, wọn din dundu iya fun titi to fi daku rọgbọndan.
"Asiko naa ni awọn ọlọpaa doola rẹ lọwọ awọn araalu ti wọn si gbe lọ sile iwosan ṣugbọn ile iwosan naa lo dakẹ si."
Ọlọpaa pari ọrọ rẹ pe bo tilẹ jẹ pe awọn mejeji ti jade laye, eyii ko di iwadii awọn lọwọ.















