Iléẹjọ́ Supreme bẹ̀rẹ̀ ìkéde ìdájọ́ rẹ̀ lórí èsì ibo Ààrẹ

Oríṣun àwòrán, Others
Loni Ọjọbọ, ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu Kẹwaa ọdun 2023 ni aarẹ to wa lori oye ni Naijiria, Bola Ahmed Tinubu yoo mọ boya yoo si tẹsiwaju lati maa jẹ aarẹ orilẹede Naijiria tabi bẹẹ kọ.
Idi ni pe ile ẹjọ to ga julọ ni orilẹede Naijiria yoo gbe idajọ rẹ kalẹ lori ẹjọ ti Oludije fun ipo aarẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar ati ti ẹgbẹ oselu Labour, Peter Obi pe aarẹ Bola Tinubu ti ẹgbẹ oṣelu APC.
Awọn oludije aarẹ mejeeji naa lo n tako esi ibo aarẹ to kọja, ti wọn si ni Tinubu kọ lo wọle ibo aarẹ to waye lọjọ kẹẹdọgbọn oṣu Kejì ọdun yii.
Alakoso eto iroyin fun ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria, Ọmọwe Festus Akande lo fi ọrọ yii sita.
O ni Ọjọru pe ile ẹjọ to ga julẹ naa ti pinnu lati gbe idajọ kalẹ lori ẹjọ yii.
Lọjo Aje to kọja lọ ni ẹgbẹ oṣelu PDP ati LP sọ awijare nile ẹjọ nigba ti ile ẹjọ sí yi ẹjọ ti oludije ibo aarẹ f'ẹgbẹ oṣelu APM, Ọgbẹni Chichi Ojei danu lẹyin to ni oun o ṣe ẹjọ mọ.
Lọjọ kẹfa oṣu kẹsan an ni ile ẹjọ kotemilorun fagile ẹjọ ti Atiku ati Obi pe Tinubu pe ko wọlé ibo aarẹ.
Ile ẹjọ kotemilorun ni ẹjọ ti wọn pe ko l'ẹsẹ nlẹ.
Koda ile ẹjọ tun ni ki wọn san ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu owo naira gẹgẹ bi faini.
Ọpọ ọmọ Naijiria nile ati káàkiri àgbáyé lo n ti n foju sọna fun idajọ yii ti yóò waye lonii.

Oríṣun àwòrán, Photoshot













