Ètò gbígbé ọ̀pá-àṣẹ fún Soun Ogbomoso Ọba Ghandi Olaoye ti bẹ̀rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Olaleye Olawuyi Peter/Facebook
Awọn olugbe ilu Ogbomoso lo ti n gbaradi fun gbigba ọpa aṣe Oba Ghandi Olaoye gẹgẹ bii Soun lọjọ kọkandilogun oṣu kejila ọdun yii.
Alaga igbimọ ipalẹmọ eto naa, Ọjọgbọn Adesola Adepoju, fi lede pe oriṣiriṣi eto ni wọn ti la kalẹ fun ayẹyẹ naa.
Lara awọn alakalẹ eto naa ni ironilagbara to waye laafin Soun lana, Ọjọbọ, ati irun Jimọ ti yoo tun waye ninu aafin naa loni ọjọ Ẹti.
Ọjọ Abamẹta, ọjọ kẹrindinlogun ni idije ‘golf’yoo waye atawọn eto miran lojoojumọ titi di ọjọ Iṣẹgun ọjọ kọkandinlogun ti Gomina Seyi Makinde yoo gbe ọpa aṣẹ le ọba Olaoye lọwọ.
Ọba Olaoye ni yoo jẹ Soun kọkanlelogun nilu Ogbomoso.
Ẹwẹ, oniruuru awuyewuye lo ti n waye lati igba ti wọn yan ọba Ghandi Afolabi Olaoye bii Soun ti ọrọ naa si ti de ileẹjọ kotẹmilọrun bayii.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tako ìdájọ́ tó rọ Soun Ogbomosho tuntun lóyè

Oríṣun àwòrán, Free World TV
Ijọba ipinlẹ Oyo ti pe ẹjọ kotẹmilọrun tako idajọ ile ẹjọ to rọ Soun ilu Ogbomosho, Oba Ghandi Afolabi Olaoye, loye.
Yatọ si ẹjọ kọtẹmilọrun yii, ijọba tun bẹbẹ pe ki ile ẹjọ maṣe gba ki wọn yọ ori ade ọhun loye titi ti yoo fi gbọ ẹjọ ti awọn pe.
Olupẹjọ naa tun n bere pe ki awọn to pe ẹjọ akọkọ, eyii ti ile ẹjọ da lare maṣe ṣe ohunkohun lati yọ Ghandi loye lasiko yii.
Ti ẹ ko ba gbabe, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun 2023 yii ni Adajọ K. A. Adedokun da ẹjọ naa laarin ọmọba Muhammed Olaoye ati ijọba ipinlẹ Oyo atawọn mọkanla mii, ninu eyii to ti ni kudiẹkudiẹ wa ninu iyansipo ọba Ghandi Olaoye, nitori naa ko fi ipo naa silẹ.
Lẹyin idajọ ọhun ni Akin Onigbinde, SAN, pe ẹjọ kotẹmilọrun lorukọ gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde atawọn mii ti ọrọ naa kan nipinlẹ lori idajọ to gba ade Ọba lori Soun tuntun.
Ipẹjọ yii ni agbẹjọro ijọba ti fa koko mẹfa yọ ninu eyii to ti tako idajọ ile ẹjọ akọkọ.
O ni awọn ẹri to wa nilẹ tako idajọ to waye pe Ghandi ko yẹ loye Soun ilu Ogomosho.
Lara awọn ti ijọba pe lẹjọ kotẹmilọrun yii ni agbẹjọro Oladapo Atanda, ijọba ibilẹ ariwa Ogbomosho ati igbimọ afọbajẹ Ariwa Ogbomosho.
Awọn to ku ni agbẹjọro S.A. Mohammed, ileeṣẹ Mohammed & Mohammed & Co., Mobolaji Chambers, Kola Fatoye, Oloye Samuel Otolorin, Oloye Salawu Ajadi, Oloye Tijani Abioye, Oloye David Adeniran Ojo, atawọn mii.
Bí ilé ẹjọ́ gíga ṣe rọ̀ mí lòyè kò tọ̀nà, ẹ yí ìdájọ́ náà padà - Soun Ogbomoso rọ ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn

Oba Ghandi Afolabi Olaoye ti pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tako ìdájọ́ ilé ẹjọ́ gíga kan ní ìpínlẹ̀ Oyo tó rọ̀ ọ́ lóyè gẹ́gẹ́ bí Soun Ogbomoso tuntun.
Nǹkan mẹ́jọ ni Oba Ghandi pé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lé lórí níwájú ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn tó wà ní Ibadan.
Ní ọjọ́ Kẹẹ̀dọ́gbọ̀n oṣù Kẹwàá ọdún 2023 ni ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Oyo tó fi ìlú Ogbomoso ṣe ibùjókòó rọ Ọba Olaoye lóyè gẹ́gẹ́ bí Soun Ogbomoso pé ìyànsípò rẹ̀ kò tọ̀nà.
Nínú ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí Oba Olaoye pè, ó ní òun kò faramọ́ ìdájọ́ tí Adájọ́ Kareem Adeyemika Adedokun dá láti gba ẹ̀sùn tí ọmọọba Muhammed Kabir Olaoye fi kan òun wọlé.
Ó ṣàlàyé pé Adájọ́ Adedokun kò da ẹjọ́ náà dáadáa bó ṣe kéde pé ìyànsípò kò bá ìlànà jíjẹ Soun Ogbomoso mú.

Ààfin Ogbomoso ti rọ àwọn ènìyàn ìlú náà láti fi ọkàn balẹ̀ lórí ìdájọ́ ilé ẹjọ́ gíga.
Ẹnìkan ní ààfin tí kò fẹ́ kí àwọn akọ̀ròyìn dárúkọ òun ní àwọn máa pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn láti tako bí ilé ẹjọ́ ṣe yọ Ọba Ghandi Olaoye nípò Soun Ogbomoso.
Ó ní ṣáájú ni ilé ẹjọ́ ti kọ́kọ́ sọ pé ìlànà tí wọ́n fi yan Ọba Ghandi tọ̀nà nígbà tí ọmọba kọ́kọ́ pé ẹjọ́ àti pé ejò lọ́wọ́ nínú tí ilé ẹjọ́ náà bá tún yí ohùn padà.
Ó fi kun pé ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn ló máa bá àwọn tán ìmọ́lẹ̀ sí gbogbo àwọn nǹkan tó tá kókó lórí ẹjọ́ náà.
Ó wa pàrọwà sí àwọn ènìyàn láti máa bá iṣẹ́ oòjọ́ wọn lọ pé kí wọ́n fọkàn balẹ̀ àti pé dídùn ni ọsàn máa so fún àwọn ní ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn.
Iléẹjọ́ wọ́gile ìyànsípò Ọba Ghandi Olaoye gẹ́gẹ́ bíi Soun tuntun

Ile ẹjọ giga ipinlẹ Oyo to kalẹ silu Ogbomosos ti wọgile iyansipo Soun tuntun fun ilu Ogbomoso, Ọba Ghandi Olaoye.
Ijọba ipinlẹ Oyo lo kede Pasitọ Ghandi Olaoye gẹgẹ bi Soun tuntun ti awọn afọbajẹ ilu naa si fi jẹ ọba lọjọ Kẹjọ osu Kẹsan dun 2023.
Saaju asiko yii ni ọmọ oye miran, ti wọn dijọ n du ipo Soun, Kabir Laoye ti pe ẹjọ pe Ghandi Olaoye ko lẹtọ lati du ipo Soun.
Ile ẹjọ si pasẹ nigba naa pe ijọba ipinlẹ Oyo ko gbọdọ yan ẹnikẹni sipo naa, titi ti oun yoo fi gbe idajọ oun kalẹ.
Amọ ikede jade sita lẹyin naa pe ijọba ipinlẹ Oyo ti yan Pasitọ Ghandi Laoye bii Soun tilẹ Ogbomoso tuntun.
Kí ló dé tí adájọ́ fi wọ́gilé ìyànsípò Soun tuntun?
Ọmọọba Kabir Olaoye to pe ẹjọ lati tako iyansipo Ghandi salaye pe aise deede wa ninu ilana ti wọn fi yan an.
O wa n rọ ile ẹjọ giga naa lati wọle iyansipo ọba tuntun yii, ko si pasẹ fun awọn afọbajẹ lati bẹrẹ igbesẹ yiyan ọmọ oye miran.
Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Adajọ Adedokun to n gbọ ẹjọ naa wa kede pe iyansipo ọba Laoye ko bofinmu.
Bakan naa lo pasẹ pe ki awọn afọbajẹ lọ bẹrẹ ilana ọtun lati yan Soun tuntun
Saaju ni Adajọ Adedokun ti wọgile ẹbẹ mẹta ti ọkan ninu awọn olupẹjọ, Ọmọọba Adeyemi Taofiq Akorede Laoye gbe siwaju rẹ.
Awọn ẹbẹ naa loun naa fi n pe iyansipo oriade tuntun naa nija.
A maa mu ẹkunrẹrẹ iroyin naa wa fun yin laipẹ.















