Ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ pàṣẹ pé Nnamdi Kanu gbọdọ̀ tẹ̀sìwájú ìgbẹ́jọ́ lórí àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án

Ileẹjọ giga julọ lorilẹede Naijiria ti dajọ pe Nnamdi Kanu gbọjọ tẹsiwaju igbẹjọ rẹ nile ẹjọ giga lori awọn ẹsun ti ijọba apapọ fi kan an.
Ile ẹjọ to ga julọ yi idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun to fagile awọn ẹsun ti ijọba apapọ fi kan Kanu.
Ninu idajọ rẹ, ile ẹjọ to ga julọ sọ pe Kanu to jẹ olori ẹgbẹ Ipob ajijagbara fawọn ẹya Igbo gbọdọ tẹsiwaju pẹlu igbẹjọ rẹ nile ẹjọ giga.
Ninu idajọ ile ẹjọ giga julọ eleyii ti adajọ Emmanuel Agim ṣe aadri rẹ, igbimọ igbẹjọ naa ni ile ẹjọ kotẹmilọrun kuna lati paṣẹ pe Kanu ko ni lati lọ ile ẹjọ mọ tori lilodisofin bi ijọba apapọ ṣe ya wọ ile rẹ.
Ile ẹjọ ni lootọọ ni pe ọna ti ijọba Naijiria fi gbe Kanu pada wale lati orilẹede Kenya lodi sofin, amọ iyẹn ko ni pe ki Kanu ma lọ sile ẹjọ lori ẹsun ti wọn fi kan an.
Ile ni Kanu le gbe ijọba lọ si ile ẹjọ lori bi ijọba apapọ ṣe gbe pada wa si Naijiria, amọ ko le sọ pe ki ile ẹjọ ma tẹsiwaju igbẹjọ lori ẹsun ti wọn fi kan an.
Lónìí ni ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà yóò da ẹjọ́ Nnamdi Kanu
Ileẹjọ giga julọ lorilẹede Naijiria yoo gbe idajọ rẹ kalẹ lonii lori ẹjọ ti ijọba apapọ pe tako Nnamdi Kanu, to jẹ adari ẹgbẹ IPOB tijọba fofin de, lẹyin idajo ileẹjọ kotẹmilọrun to ni ki wọn mu un kuro ni ahamọ ko maa lọọle layọ.
Ileẹjọ kotẹmilọrun naa lo wi pe ẹsun iditẹ mọ ijọba ti wọn fi kan Kanu ni ko lẹsẹ nlẹ ati pe ọna ti ijọba fi mu ọkunrin naa pada si Naijiria ni ko bofin mu.
Ijọba apapọ lo fẹẹ ki ileẹjọ to ga julọ naa o doju idajọ ileẹjọ kotẹmilọrun delẹ amọ ti Kanu wi pe ki ileẹjọ naa o ṣegbe lẹyin idajọ ileẹjọ kotẹmilọrun ki oum le maa lọle layọ ati alaafia.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Igbimọ ẹlẹnimarun ileẹjọ naa, ti Onidajọ Kudirat Kekere-Ekun n dari rẹ, nibi ijoko wọn lọjọ karun oṣu kẹwa ọdun 2023, lo fi idajọ si oni ọjọ Ẹti lẹyin atotonu Agbẹjọro-agba Tijani Gazali to duro fun ijọba apapọ ati Agbẹjọro-agba Mike Ozekhome to duro fun Kanu.
Gazali, ninu awijare rẹ, rọ ileẹjọ lati fagile idajọ ileẹjọ kotẹmilọrun to jọwọ Kanu amọ ko faaye gba idajọ ileẹjọ giga to wi pe ọkunrin naa ni lati jẹjọ lori ẹsun iditẹmọjọba ti wọn fi kan-an.
Ẹwẹ, Ozekhome, to jẹ olori awọn agbẹjọro fun Kanu, wi pe ki ileẹjọ o da ẹbẹ ijọba apapọ nu ki wọn si ni ki wọn sanwo itanran.
O ni ki ileẹjọ o wo iwe atako ti awọn kọ mọ ipẹjọ ijọba leyi ti onibara oun to ti wa ni ahamọ lati ọjọ kọkandinlọgbọ oṣu kẹfa, ọdun 2021 ti ijọba si kọti ikun si aṣẹ ileẹjọ kotẹmilọrun to ni ki wọn yọnda rẹ ko maa lọle.
Ozekhome ni kileẹjọ o lo eleyi “lati ṣe apejuwe pe ko si ijọba to lee tẹ ẹtọ araalu mọlẹ gẹgẹ bii ẹjọ Ojukwu ati ijọba ipinlẹ Eko”
Ki lo ṣẹlẹ nileẹjọ kotẹmilọrun?
Ileẹjọ kotẹmilọrun to wa nilu Abuja, ninu idajọ rẹ lọjọ kẹtala oṣu kẹwa, ọdun 2022 dẹbi ru ijọba apapọ fun ọna ti wọn gba mu Nnamdi Kanu pada wa si Naijiria, to si tun fagi le ẹsun meje to ku ninu awọn iditẹmọjọba ti wọn fi kan Kanu niwaju ileẹjọ giga kan ko to salọ soke okun.
Ileẹjọ kotẹmilọrun lo ni ijọba apapọ tẹ ofin loju mọlẹ ninu ọna ti wọn fi mu Kanu ni Kenya ti wọn si wọọ wa si Naijiria.
Bakan naa nileẹjọ naa wi pe ijọba apapọ lo tako ofin agbaye nipa ilana ti wọn fi mu Kanu lai fi ọrọ naa lọ ijọba ilẹ Kenya pe ki wọn mu ọkunrin naa ki wọn si faa le awọn lọwọ.
Igimọ ẹlẹnimẹta ileẹjọ kotẹmilọrun naa waa yọnda Kanu wọn si ni ki wọn fi silẹ ahamọ ko maa lọ sile rẹ.
Ki idajọ naa o too di mimu ṣẹ nijọba apap ti rọ ileẹjọ kotẹmilọrun naa fun idaduro idajọ naa titi di igba ti ipẹjọ rẹ tako igbẹjọ naa yo dopin, leyi ti ileẹjọ naa fọwọ si.
Ṣaaju eyi ni Onidajọ Binta Nyako ti ileẹjọ giga to n jokoo nilu Abuja ninu idajọ rẹ ti fagi le mẹjọ ninu ẹsun mẹẹdogun ti wọn fi kan Kanu to si ni ko waa jẹjọ lori meje to ku, amọ tileẹjọ kotẹmilọrun fagi lee ninu idajọ tirẹ.















