Bí ẹ bá gbọ́rọ̀ sí World Bank lẹ́nu láti sọ lítà epo bẹntiróòlù di N750 wàhálà lẹ̀ ń fà lẹ́sẹ̀ - NLC kìlọ

Aworan awọn ọmọ ẹgbẹ oṣiṣẹ Naijiria

Oríṣun àwòrán, NLC

Ẹgbẹ oṣiṣẹ lorileede Naijiria ti fi ikilọ sita si ijọba apapọ lati ma ṣe tẹti si aba ajọ banki agbaye to ni ẹẹdẹgbẹrin le laadọta Naira lo yẹ ki owo jala bẹntiroo di.

Benson Upah to jẹ olori ẹka iroyin ẹgbẹ naa lo sọ bẹẹ fun ileeṣẹ iroyin Naijiria nii The Punch ninu ifọrọwerọ kan.

Upah sọ pe igbesẹ kankan lati ọdọ ijọba lati mu laekun ba iye owo bẹntiroo yoo da wahala ati rogbodiyan silẹ jakejado Naijiria.

Lọwọlọwọ bayii, owo jala bẹntiroo kan jẹ nkan bi ẹgbẹta Naira si ẹgbẹta lelogun Naira jakejado Naijiria.

Upah ninu ifọrọwerọ naa rọ ijọba apapọ lati ma ṣe tẹti si aba yi tori pe abọ rẹ ko ni da a.

Awọn oniṣowo to n gba epo wọle s pe iye to yẹ ki owo jala bẹntiro kan jẹ ni ẹgbẹrun kan Nairia bi kii ṣa ṣe pe ijọba apapọ fi ẹkunwo si.

Amọ ijọba apapọ Naijiria kii ye tako ọrọ yi ti wọn si ni ẹkunwo ti kuro lori owo bẹntiroo.

Ki ni World Bank sọ to mu ki NLC fọnmu lori ọrọ owo epo bẹntiroo

Nibi apero kan to waye nilu Abuja laarin ọṣẹ yi ni onimọ eto ọrọ aje agba ajọ naa, Alex Sienaert ti sọ pe ohun roye pe ijọba ko jawọ kuro nidi a n fi ẹkunwo si owo bẹntiroo ni Naijiria.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

O ni ti ijọba ba fẹ ki karakata ṣatọna iye owo epo lae si idasi ijọba nibẹ,iye ti jala kan gbudọ maa jẹ bayi ni ẹẹdẹgbẹrin le laadọta Naira dipo iye ti wọn n ta kaakiri.

Ni ṣoki ohun ti onimọ yi sọ ni pe ẹkunwo ni ko jẹ ki owo epo lita kan de ibi to yẹ ko wa.

Ọrọ yi ni NLC figbe ta si ti wọn si ni ki ijọba ma ṣe gbọrọ si World Bank lẹnu tori pe ajọ yi ko ni ifẹ araalu lọkan rara ati rara.

Benson Ujah ṣapejuwe ipa ti alekun to waye tẹlẹ n ni lori ọrọ aje ati igbe aye awọn araalu to si ni igbesẹ kankan lati gbe owo yi lọ soke ko le mu ki nkan dẹrun faraalu.

Ninu ọrọ ti wọn, awọn ẹgbẹ IPMAN to jẹ alagbata ọlọdanni epo sọ pe ko sootọ ninu ọrọ ijọba ti wọn sọ pe awọn ti yọ gbogbo subsidy pata nidi owo bẹntiroo.

Gẹgẹ bi alaye ti World Bank naa ṣe wọn ni ohun to foju han ni pe ijọba ko le gbe awọn igbesẹ to gbe lori Naira ko ma ṣe pe wọn ṣi n san ẹkunwo lori bẹntiroo.

Wọn ni ijọba n gbe igbesẹ subsidy sisan yi ki wahala ma ba bẹ silẹ lorileede naa ni.