Fuel scarcity: NNPCL àtàwọn alágbàtà epo ń jara wọn níyàn bí àwọn aráàlú ṣe ń tò láti ra epo

Aworan awọn to to lati ra epo bẹntiroo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Fakinfa ti n waye laaarin awọn alagbata epo rọbii lorileede Naijiria ati ileeṣẹ to n ṣakoso epo rọbii lorileede yii, iyẹn Nigerian National Petroleum Company Limited (NNPCL) lori bi wọn ko ṣe ri epo bẹntiroolu ra, to si n fa ki awọn araalu lọ maa to fun epo lojoojumọ l’awọn ile-epo kaakiri.

Awọn oniṣowo sọ pe o ṣee ṣe ki bi awọn araalu ṣe n lọ n to fun epo tun peleke sii ju eyi to n ṣẹlẹ lasiko yii lọ, nitori pe awọn alagbata epo ko ri epo bẹntiroolu ra lati oṣu kan bayii.

Ṣugbọn awọn alakoso ileeṣẹ NNPCL ti sọ pe ko si otitọ kankan ninu ọrọ naa, nitori pe awọn ni epo bẹntiroolu nilẹ to to lati ta fun oṣu kan, bo tilẹ jẹ pe wọn l’awọn naa maa n ri b’awọn araalu ṣe n to fun epo kaakiri awọn ile-epo ni Naijiria.

Pupọ awọn ile-epo ti wọn tun jẹ t’awọn alagbata aladani ni wọn ti ile-epo wọn pa, nitori bi wọn ko ṣe ni epo lati ta sita, eyi to ṣẹlẹ l’awọn ilu bii Abuja, Nasarawa ati Niger.

Bakan naa lo jẹ pe iwọnba awọn ile-epo ti wọn jẹ alagbata nla ni wọn n ta epo, bo tilẹ jẹ pe niṣe ni sunkẹrẹ-fakẹrẹ n ṣẹlẹ nibẹ, bi apẹẹrẹ ile-epo Conoil to wa ladojukọ ileeṣẹ NNPCLC to wa niluu Abuja ni awọn eeyan ti to fun epo lọpọ yanturu l’Ọjọbọ.

Ọpọ ile-epo labẹ iṣakoso IPMAN wa ni titi pa

Bo ṣe ri niluu Abuja naa ni ko si iyatọ nipinlẹ Eko, Port-Harcourt ati awọn miran kaakiri Naijiria, gẹgẹ bi awọn alagbata ati awọn awakọ l’awọn agbegbe naa ṣe sọ.

Ọkan lara awọn alagbata epo labẹ aburada ẹgbẹ Independent Petroleum Marketers Association of Nigeria (IPMAN), l’Ọjọbọ ṣalaye pe lati bi oṣu kan bayii lo ti n ṣoro fun wọn lati ra epo lọdọ NNPCL, ti awọn ko si mọ idi rẹ.

IPMAN gẹgẹ bi a ṣe gbọ ni wọn n ṣakoso ida aadọrin ile-epo lorileede Naijiria, to si jẹ bi a ṣe n kọ iroyin yii, ọpọ ile-epo to wa labẹ iṣakoso IPMAN ni wọn ti wa ni titi pa nitori airi epo ra.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ohun ti a gbọ ni pe ohun ti awọn alagbata n ṣe bayii ni lati maa ra epo atọwọdọwọ, to si jẹ pe iye ti wọn n ra a bayii ti lọ soke lati N578/litre si N605/litre.

Agbẹnusọ lapapọ fun ẹgbẹ IPMAN, Oloye Chinedu Ukadike, nigba to n sọrọ ṣalaye pe “Ọpọ ibi ti wọn ti n gbe apo lo ti gbẹ tan. NNPCL saba maa n tọju awọn epo fun lilo ọjọ iwaju, ko di pe epo tuntun miran wọle. Ṣugbọn bi mo ṣe n sọrọ yii, mo lero wi pe awọn epo to wa nilẹ ti tan ni.

“Idi ni pe lati bi oṣu meloo kan sẹyin bayii ni ajọ NNPCL ti dawọ tita epo fun awọn alagbata aladani kan duro l’awọn ibi ti wọn n gbe epo si. Ni Warri ati Ekoo, iṣoro nla lo n jẹ fun awọn alagbata nibẹ lati ri epo ra lọwọ NNPCL.

“Awọn alagbata nla ti ko pọ rara nikan ni wọn ni epo lọwọ, to si jẹ pe niṣe ni wọn gbe owo le epo wọn.”

Nigba to n dahun ibeere nipa iye ti wọn n ta awọn epo naa fun awọn alagbata aladani, Ukadike sọ pe “laaarin N601 ati N605/litre ni wọn n ta, eyi to si lodi si eyi ti wọn bu ọwọ lu, to jẹ N577 and N578/litre.

“Ki ijọba apapọ gbe igbesẹ to yẹ lati rii daju pe gbogbo awọn ibi ifọpo orileede yii pada bẹrẹ iṣẹ. Owo ti ko din ni biliọnu mẹjọ dọla ($8bn) ni wọn yoo lo lati fi kọ ibi ifọpo tuntun ti igbalode, ti yoo si tun fun wọn ni epo rọbii.

“Ṣiṣe paṣipaarọ epo ati lilo owo lọwọ ti ijọba gbe jade ko ṣe iranwọ kankan, bi ko ṣe pe niṣe ni yoo tun maa mu ki ọwọngogo ṣẹlẹ. Eto ọrọ aje wa ti n lọ soko iparun, ti a a si gbọdọ tete wa nnkan ṣe sii.”

Iya to n jẹ araalu pọju lori airi epo ra

Akọwe ẹgbẹ IPMAN niluu Abuja si Suleja, Mohammed Shuaibu nigba toun naa n kin ọrọ agbẹnusọ lẹyin, o ni bi awọn araalu ṣe n to lati ra epo ko ṣẹyin awọn ariwo ti wọn ti n pa tipẹ nipa nnkan to le fa wahala ọjọ iwaju.

“Forex lo n ṣakoso eto ọrọ aje wa bayii. Fun idi eyi, ohunkohun to ba ṣẹlẹ nile itaja agbaye yoo kan wa, ko si bo tile wu ko ri. Ṣugbọn ohun to banilọkanjẹ julọ ni pe gẹgẹ bi orileede to n pese epo rọbii, a ko le fọ ọ funra wa nitori bi wọn yoo ṣe ko owo rẹ jẹ.

“NNPCL ko ko epo ti yoo to wọle. Ati pe nibi ti a ba de bayii, tani ẹni naa to le da gbe epo wọle funra rẹ? Koda, niṣe lo dabi ẹni pe ọrọ naa ti daru mọ ijọba apapọ loju. Ju gbogbo rẹ lọ, bi wọn ba fun wa ni Forex, a maa gbe epo wọle. Ṣugbọn titi di igba naa, awọn eeyan yoo ṣi tubọ maa lọ to fun epo, nitori pe nnkan ti awọn alagbata ri ni wọn n ta.”

Siwaju sii lo fi kun ọrọ rẹ pe ojuṣe ijọba ni lati mu adinku ba iṣoro ati iya to n jẹ araalu, kii ṣe pe ki wọn tun da kun un. O ṣeni laanu nipa iru ipo a ba ara wa lonii, to si nilo awọn ọjọgbọn ati awọn onimọ lati da sii.