Bí owó afẹ́fẹ́ gáàsì ìdáná ṣé ń lọ sókè ń kọ àwọn ọmọ Nàìjíríà lóminú

Aworan gaasi idana

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bi owo afẹfẹ gaasi idana ṣe n fi ojoojumọ lọ soke lasiko yii, ni awọn ọmọ orilẹede Naijiria ti bẹrẹ sii ṣe aniyan lorisirisi, pẹlu bo ṣe n ba wọn lọkan jẹ.

Ni awọn agbegbe kan lorileede Naijiria, wọn ti n ta afẹfẹ gaasi idana kilo kan ni ẹgbẹrun kan naira, bẹẹ ni awọn agbegbe miran, ẹgbẹrun kan le ni ọgọrun (N1,100) ni wọn n ta a.

Eyi ni wọn lo jẹyọ latari awọn idi pataki kan ti wọn lo fa ti owo afẹfẹ gaasi naa fi lọ soke, to si tun fa bi ko ṣe pọ nita mọ.

Ohun ti a gbọ ni pe ẹgbẹrun mejila naira ni wọn n ta kilo mejila afẹfẹ gaasi, to si tun ju bẹẹ lọ ni awọn agbegbe miiran.

Niluu Kano, ipinlẹ Kano, ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Sanusi Mannir Garba, to ṣẹṣẹ ra afẹfẹ gaasi tan, ẹni to ba BBC sọrọ ṣalaye ipenija to n koju nipa rira afẹfẹ gaasi.

Garba sọ pe “mo wa ra afẹfẹ gaasi nibi ni.

Mo si ra a ni ẹgbẹrun mọkanla din ni ọgọrun kan (N10,900) naira, eyi to le ni ẹgbẹrun mẹjọ din ni ọgọrun kan (N8,900) naira ti a n ra a tẹlẹ.

Afẹfẹ gaasi la n lo fun ẹrọ amunawa jẹnẹretọ wa ni ṣọọbu, nitori owo epo bẹntiroolu to lọ soke.

Ọjọ meji si mẹta la maa n lo kilo gaasi ti a ba ra, nitori pe masiini ti a n lo tobi gidi gan-an.”

Abdullahi Muhammad ninu ọrọ tiẹ to ba BBC sọ jẹ ko di mimọ pe awọn ti bẹrẹ sii lo eedu bayii, nitori pe kii pẹ rara ti gaasi ti awọn n ra fi n jo tan.

"Ẹgbẹrin naira di aadọta (N750) ni a n ra afẹfẹ gaasi idana tẹlẹ, ṣugbọn ni bayii, o ti di ẹgbẹrun kan naira.

Kilo marun-un ni mo ni, ṣugbọn owo kilo mẹta pere lo wa lọwọ mi,'' Muhammad lo sọ bẹẹ.

Ki lo fa a ti owo gaasi idana fi lọ soke?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Basiru Sulaiman Iliyasu, ọkan lara awọn to n ta afẹfẹ gaasi idana niluu Kano nigba toun naa n sọrọ ṣalaye ipenija ati idojukọ ti wọn n ri, ko to di pe wọn n ri i ra lọdọ awọn alagbata nla.

“Ohun to n ṣẹlẹ bayii ni pe a ni lati jiya ka too ri gaasi naa ra, owo rẹ tun ti wa lọ soke kọja ohun ti a ko lero.

Ti a ba lọ si ileeṣẹ ti a ti n ra a, o maa n ṣoro lati ri ra nibẹ, a ni lati jiya fun un, ayafi ti a ba tun gbadura lo maa n jẹ ko ya.

Ẹgbẹrun kan naira la n ta kilo kan, ti kilo mejila si jẹ ẹgbẹrun mejila naira.

Ni awọn agbegbe kan, ẹgbẹrun kan le ni ọgọrun kan naira (N1,100) ni wọn ta a, ti awọn miran si n fi aadọta naira sori ẹgbẹrun kan (N1,050) ti wọn n ta a.

Ko si nkan meji to fa a, to kọja iṣoro ti a n koju ko to di pe a rii ra ati owo ti a tun maa fi gbe de ṣọọbu.

Ibi to jinna la ti maa n lọ ra a, Iliyasu ṣalaye.”

Ọkan lara awọn alagbata nla lẹkun ariwa Naijiria, Bashir Ahmad ọmọ Malaamu, nigba to n ba BBC sọrọ tun ṣalaye pe opopona ti ko dara lo tubọ n jẹ k’awọn maa koju iṣoro to pọ.”

Iwadii fihan pe o ṣeeṣe ki afẹfẹ gaasi tun gb’owo lori ju bayii lọ latari bi ko ṣe si pupọ nita mọ bayii.

Pẹlu bi nnkan tun ṣe ri lasiko yii, afaimọ kawọn ọmọ Naijiria ma tun ko aya soke, paapaa julọ awọn to ku diẹ kaato fun.