Iléẹjọ́ ní kí Ọ̀gá ológun san N3.7bn, kó sì tún lo sáà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n fún ọdún meje

Oríṣun àwòrán, The Punch
Ileẹjọ ologun to joko niluu Abuja lọjọ isẹgun ti ni ki Ọgagun kan lorilẹede NAijiria, Umaru Mohammed lọ si ẹwọn ẹwọn ọdun meje, ko si tun san owo to le bilọnu mẹta naira pada fun ileeṣẹ ọlọgun
Gẹgẹ bi Ileeṣẹ iroyin kan lorilẹede Naijiria, The Punch ṣe gbe jade, Umaru Mohammed, ẹni to n ṣe akoso ileeṣẹ ologun Naijiria to n ri si dukia, ni ileeṣẹ ọmọogun oriilẹ ni Naijiria jẹbi ẹsun sise owo mọkumọku lẹyin ti ileeṣẹ ologun fi ẹsun mejidinlogun kan an.
Lara awọn ẹsun yii ni gbigba riba, sise owo mọkumọku, lilẹdiapopọ ati awọn ẹsun mii.
Ileẹjọ ni ki Mohammed san owo to le ni miliọnu meji dọla, i paṣipaarọ rẹ si owo Naira le ni bilọnu mẹta naira.
Lasiko to n sọrọ ni ileẹjọ, Mohammed jẹ ko di mimọ pe oun ko jẹbi gbogbo ẹsun ti wọn fi kan oun.
Amọṣa nigba ti ile ẹjọ ologun naa yoo gbe idajọ rẹ kalẹ, o ni ọgagun Mohammed jẹbi ẹsun mẹrinla ninu mejidinlogun ti wọn fi kan an .
Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, igbimọ ẹlẹni mẹjọ ti Ọgagun James Myam lewaju ni ki Mohammed lọ lo ọdun marun un fun ẹsun akọkọ, ko si tun san owo to le miliọnu kan dọla pada fun Ileeṣẹ ologun.
Bakan naa ni Ileẹjọ tun ni ko san owo to to ẹgbẹrun lọna ọgọrinlenirinwo owo dọla fun NAPL.
Ẹsun kẹta, Ileẹjọ ni ki Ọgagun naa tun lọ lo ọdun marun un lẹwọn, ko si tun san owow toto ẹgbẹrun lọna marundinlaadọrun owo dọla fun NAPL.
Ko tan sibẹ, Ileẹjọ ni o jẹbi ẹsun kẹrin, karun un, kẹfa ati ikẹsan, ti wọn si tun fun ẹwọn ọdun marun un, ko si tun san owo, $35,300, $55,500, $46,500 ati $430,800 fun awọn ẹsun naa.
Ileẹjọ ni idajọ ni awọn ẹwọn yii ni yoo ṣe papọ, ti wọn alasẹ yoo si ni lati buwọlu.












