Akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ Nàìjíríà tó lé ní 99,000 ni wọ́n lọ kàwé ní UK láàárín ọdún márùn ún – Ìjọba apapọ̀

Oríṣun àwòrán, getty images
Minisita fun ọrọ abẹle ni Naijiria, Ọmọwe Olubunmi Tunji-Ojo ti sọ pe awọn akẹkọọ Naijiria to din diẹ ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun (99,985) ni wọn ti fi orilẹ-ede naa silẹ lati lọ kawe nilẹ gẹẹsi laaarin ọdun 2017 si 2022.
Ọmọwe Tunji-Ojo lo sọ eyi di mimọ niluu Eko, nibi eto kan ti wọn pe ni ‘University of Lagos International Week’ ti ọdun 2023.
Nibi ipade baa lo ti sọ pe awọn akẹkọọ Naijiria to le ni ọgọrun lo n jẹ anfaani eto ẹkọ ọfẹ lati lọ kawe siwaju sii loke okun.
O ni “Lọdọọdun, awọn akẹkọọ Naijiria to le ni ọgọrun ni wọn n jẹ anfaani eto ẹkọ ọfẹ lati lọ kẹkọọ gboye.”
“Mo n ba awọn akẹkọọ sọrọ funra mi; a ni awọn to le ni ọgọrun ọjọgbọn ati onimọ to fi mọ awọn olokoowo kekeke ti wọn n fi agbegbe wa silẹ lati lọ tẹpa mọ iṣẹ kaakiri ilẹ wa.
“Ati pe ni ti wa, a gbọdọ rii daju pe a n ṣe ojuṣe wa lati le jẹ ki ala rere wọn wa si imuṣẹ.
“Ami idanimọ wa ni wọn gbe dani, eyi ti kii ṣe pe yoo jẹ ki ipinu wọn wa si imuṣẹ nikan, bi ko ṣe pe o tun sọ iru ẹni ti wọn jẹ.
“Gẹgẹ bi akọsilẹ ajọ to n ri sọrọ eto ẹkọ giga, HESA, iwadii fi han pe awọn akẹkọọ Naijiria to din diẹ ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun (99,985) ni wọn ti fi orilẹ-ede yii silẹ lati forukọ silẹ l’awọn ile-ẹkọ giga fasiti ni UK laaarin ọdun 2017 si 2022.
“Bi awọn kan ṣe n ro pe pupọ wọn lo ti ‘japa’ fun nnkan miran, a ko le pa otitọ ti wi pe pupọ ninu wọn ni wọn lọ lati kẹkọọ siwaju sii fun imọ kikun ara wọn.”
Ọmọwe Tunji-Ojo wa kọminu lori bi awọn akẹkọọ ṣe n la kaka lati gba iwe irinna oke ilẹ okere ti wọn n san owo fun, to si ni gbogbo eto lo ti n lọ lati rii pe awọn ọmọ Naijiria ko tun ni nilo lati maa lọ to, tabi duro kọja ọsẹ meji ko to di pe iwe irinna wọn jade lẹyin ti wọn ba ti san owo.














