'Olùkọ́ tó lé ní 10,000 ló ti jápa lọ sí UK lọ́dún 2023, ọ̀pọ̀ àwọn míì ṣì ń lọ'

Oríṣun àwòrán, getty images
- Author, Komla Adom
- Role, Senior Journalist
- Reporting from, Ghana
Ko din ni ẹgbẹrun mẹwaa olukọ lorilẹ-ede Ghana ti wọn ti ba ẹsẹ wọn sọrọ kuro nilẹ naa lọ si UK lati wa ọjọ iwaju rere lọ.
Gẹgẹ bii a ṣe gbọ, ko si nnkan meji to fa igbesẹ naa to kọja owo oṣu ti wọn n gba, eyi ti ko to wọn, ati bi ijọba ko ṣe kọbi ara si igbe aye idẹrun fun awọn oṣiṣẹ, paapaa awọn olukọ.
Ọkan lara awọn to ti japa naa ni Theophilus Akrofi, ẹni to ti ṣiṣẹ olukọ fun ọdun mẹfa ni Ghana lai ni ohun rere kan to le tọka si pe oun ti gbe ṣe lẹnu iṣẹ ọhun.
Bo tilẹ jẹ pe Theophilus ni Kẹkẹ ẹlẹsẹ meji to fi n ṣe ẹsẹ rin lọ si ibi iṣẹ rẹ ti ko din ni maili meje lojoojumọ, sibẹ ko le tọka si aṣeyọri kan ṣoṣo to ti fi owo ọya rẹ gbe ṣe.
Lara awọn ohun to tun n fa a ni bi ijọba ko ṣe ki n pese awọn irinṣẹ to n mu ki eto ẹkọ rọrun, bii iwe ikẹkọọ ati awọn ohun ikọṣẹ.
Theophilus, nigba to n ba akọroyin BBC sọrọ ṣalaye pe “Yatọ si opopona ti ko dara ati owo ọya ti ko ṣee gbọ s’eti ti a n gba, mo tun maa n fi owo ara mi ra awọn ohun elo ti a n lo lati fi kẹkọọ.”
O sọ pe igba toun ti rii pe ko si ọjọ iwaju rere f’oun lorileede abinibi oun, lo jẹ k’oun bẹrẹ igbesẹ lati gba orilẹ-ede t’oun yoo ti ri ọjọ ọla rere lọ.
Gbogbo eto lati japa rẹ pada pari ninu oṣu Kẹsan an, nigba ti Theophilus balẹ si UK lẹyin to ti gba iwe aṣẹ lati ṣiṣẹ gẹgẹ bii olukọ.
“Ni ibi yii, ohun gbogbo lo n lọ bo ṣe yẹ ko lọ. Ohun ti eeyan kan nilo ni lati ma ṣe fi akoko ṣofo, ko le ba ilana awọn ohun ti wọn n fẹ.”
A gbọ pe kii ṣe Theophilus nikan lo japa, bẹẹ si ni kii ṣe oun nikan lo n gbadun igbe aye ọtun ni UK, awọn miran naa wa pẹlu rẹ.
Lara wọn ni Caroline Ampah, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn toun naa fi orilẹ-ede Ghana silẹ ni nnkan bi oṣu mẹrin sẹyin, a gbọ pe pupọ awọn to n japa yii ni wọn tun n ran awọn akẹgbẹ wọn lọwọ lati wọle si UK fun iṣẹ.
Caroline ninu ọrọ to ba akọroyin BBC sọ ṣalaye pe “anfaani ọtun to n yi igbesi aye ẹni pada loun fi ọwọ mejeeji gbamu, lai fi akoko ṣofo.”
O tẹsiwaju pe ile-ẹkọ toun ti n ṣiṣẹ tẹlẹ lagbegbe East Gonja, ti ẹkun Savannah ko ni kilaasi ikẹkọọ rara, ati abẹ igi l’awọn akẹkọọ ti n gba idanilẹkọọ wọn.
Bẹẹ lo sọ pe ko si ile gbigbe fun awọn olukọ, ko si omi ẹrọ igbalode to ṣee mu, ko si ina mọnamọna, ati pe niṣe ni ọdun meji toun lo nibẹ dabi ọrun apaadi.
Ọdọọdun la gbọ pe awọn olukọ n dinku lorilẹ-ede Ghana, ti Theophilus ati Caroline si wa lara awọn ẹgbẹrun mẹwaa le diẹ to ti ba ẹsẹ wọn sọrọ laaarin oṣu kinni si asiko yii.
Akọsilẹ inu ẹrọ to n ṣakoso akọsilẹ awọn olukọ ni Ghana, Education Management Information System (EMIS) fi han pe awọn olukọ ti ko din ni 293 ni wọn kọ iwe lati fi iṣẹ silẹ lọdun 2021 nikan.
EMIS ninu akọsilẹ rẹ tun fi han gbangba pe awọn ẹgbẹrun mẹjọ le ni igba ati mẹsan an (8,209) ni wọn fi iṣẹ silẹ l’ọdun naa.
Awọn olukọ to fi iṣẹ silẹ gẹgẹ bii akọsilẹ EMIS
- 2016/17 - olukọ 242,786
- 2017/18 - olukọ 243,312
- 2018/19 - olukọ 243,442
- 2019/20 - olukọ 283,430
- 2020/21 - olukọ 239,180

Oríṣun àwòrán, bbc
Bi o tilẹ jẹ pe EMIS ko gbe esi ọdun 2022 si 2023 sita, sibẹ awọn alakoso ileeṣẹ to n ri sọrọ eto ẹkọ sọ pe iye awọn olukọ wọn ko din ni ẹgbẹrun lọna ọọdunrun (300,000).
Lawọn ile-ẹkọ to wa ni igberiko, ko si olukọ nibẹ rara, bẹẹ lo si jẹ pe awọn to ni olukọ, wọn ko pọ rara.
Idi rẹ si ni pe bi nnkan ṣe ri lawọn agbegbe naa lo fa a – bii aisi ohun amayẹdẹrun, ohun elo ikẹkọọ, ọna ti ko ja geere ati awọn nnkan miiran lo fa a to fi n ri bẹẹ.
Àwọn olùkọ́ tó lé né ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ló ti japa lọ sí UK
Bi awọn olukọ ṣe kere to si awọn akẹkọọ ti wọn n kọ, sibẹ, ọpọ awọn olukọ ni wọn n japa loore-koore.
Alakoso eto igbaniwọle ninu ẹgbẹ ajọ to n ri sọrọ olukọ, National Teaching Council (NTC), Ọmọwe Christian Addai-Poku ninu ọrọ rẹ jẹ ko di mimọ pe “awọn olukọ Ghana to le ni ẹgbẹrun mẹrindinlogun (16,000) ni wọn ti kọ iwe igbanisiṣẹ ni ẹka eto ẹkọ ni UK l’ọdun yii nikan ṣoṣo.”
Ọmọwe Addai-Poku tẹsiwaju pe “nigba to maa fi di ọjọ kẹtala, oṣu keje, awọn olukọ to le ni ẹgbẹrun mẹwaa pẹlu iwe ẹri olukọ ijọba Ghana ni wọn ti gba iwe aṣẹ lati lọ ṣiṣẹ olukọ ni UK lai jẹ pe ijọba UK ṣe ayẹwo wọn.”
O ni awọn olukọ orileede Ghana ti di ohun awo ma lee mojukuro fun ijọba UK, idi ree to fi ni wọn fun awọn orilẹ-ede mẹrin lanfaani lati kọwọ fun iṣẹ olukọ ni Ghana, awọn orilẹ-ede naa ni Ghana, Nigeria, South Africa ati Zimbabwe.
Pupọ awọn olukọ naa ti wa n gbe igbesẹ lati kuro lorilẹ-ede wọn gẹgẹ bi awọn nọọsi ati dọkita ṣe n lọ, ti awọn ileeṣẹ to n ṣe iwe irin ajo si n pa owo gidi wọle si apo ara wọn.
Ọkan lara awọn ileeṣẹ naa ni Achilinks Travel Consultancy to jẹ ti Ọgbẹni Felix Agyabeng, ẹni ti wọn lo ti fi ileeṣẹ rẹ ko awọn olukọ ti ko din ni aadọta wọle si UK laarin oṣu kinni si asiko yii.
Felix nigba to n ba BBC sọrọ, ni “A ni gbagede eto IELTS ti a n lo lati fi ran awọn olukọ ati awọn ọjọgbọn miran lọwọ lati fi wọle si UK nipaṣẹ ile-ẹkọ ati ọna miran.”
Gbogbo awọn to n japa yii ni wọn n wa oriṣiriṣi ọna lati fi wa owo ti wọn yoo lo lati fi rin irin ajo wọn.
Caroline Ampah, ọkan lara wọn to lọ l’oṣu mẹrin sẹyin ṣalaye bo ṣe ri owo to fi rin irin ajo naa.
“Ohun ti emi ati awọn yooku mi ṣe ni pe a lọ ya owo lọwọ awọn ọrẹ ati mọlẹbi wa. Awọn kan ti mo tiẹ mọ ta ile ati dukia wọn, nigba ti awọn miran naa tun gba owo ele.”
Ìdí tí àwọn olùkọ àti àwọn mìírà ṣe n japa

Oríṣun àwòrán, bbc
Bi nnkan ṣe gbe owo lori lo n jẹ ibanujẹ fun ọpọ awọn ọmọ orilẹ-ede Ghana, ati pe ojoojumọ ni ounjẹ atawọn nnkan mii n gbe owo lori.
Fun awọn olukọ, igbe aye ko rọrun fun wọn, ati pe ọna ti wọn n gba lati fi kọ ẹkọ ko rọrun fun wọn.
Lara awọn olukọ to n gbe ni igberiko ṣalaye pe awọn ati awọn ẹranko buruku bii adan, ejo ati bẹẹbẹẹ lọ ni wọn jọ n gbe inu yara kan naa, ti eyi si lewu fun ẹmi awọn.
Pẹlu ilakaka ni awọn miran fi n gbe agbegbe ti ko si ina mọnamọna ati awọn ohun amayedẹrun, to fi mọ omi.
Ni awọn abule kan l’awọn igberiko wọnyi, ko si nẹtiwọọki fun ipe, depodepo wi pe wọn yoo mọ nnkan to n ṣẹlẹ lagbaye lati ori ayelujara, paapaa bi wọn ba fẹ ṣe iwadii.
Bi wọn ṣe n la awọn ipenija wọnyi kọja, sibẹ, owo ọya wọn ni ipari oṣu ko dara rara, sibẹ, ijọba ko pese awọn ohun amayedẹrun fun wọn gẹgẹ bi ileri ti wọn ṣe f’awọn olukọ to wa l’awọn igberiko.
Caroline Ampah tẹsiwaju pe pẹlu gbogbo wahala ati ilakaka nipa ọkan akikanju wọn to, sibẹ awọn eeyan kii bọwọ fun awọn.
Bẹẹ lo ni lati igba toun ti kuro ni Ghana, loun ti n ṣe iranlọwọ fun awọn mọlẹbi oun yooku.
Ọ̀pọ̀ àwọn olùkọ́ ló ṣì maa japa
Ẹgbẹ awọn olukọ ti wa a f’idi rẹ mulẹ pe ọpọ awọn olukọ lo ṣi tun maa ba ẹsẹ wọn sọrọ lọ sibi ti aye yoo ti dẹrun fun wọn, bi ijọba ko ba tete gbe igbesẹ lati gbajumọ ọrọ igbayegbadun awọn olukọ.
Agbẹnusọ ẹgbẹ awọn olukọ ni Ghana, Tanko Musah ṣalaye pe “awọn olukọ kan n fi ara wọn jin lasan lori ofo ni.”
O ni awọn olukọ miran maa n rin irin ajo lori omi lai ni aṣọ idaabobo, ko to di pe wọn lọ si ibi ti wọn yoo ti lọ kọ awọn akẹkọọ nile-ẹkọ.
“Ijọba sọ pe oun yoo pese awọn ohun amayedẹrun fun awọn olukọ to wa ni igberiko, ṣugbọn ti wọn ko tii mu ileri wọn ṣẹ gẹgẹ bi wọn ṣe sọ.”
Musah wa fi kun ọrọ rẹ pe pẹlu bi ipenija naa ṣe pọ to, “awọn olukọ kan n fi anfaani iṣẹ naa ṣe atẹgun lasan ni, nitori pe igbakugba ti anfaani iṣẹ gidi ba ti yọ, ni ṣe ni wọn n lọ.”
Ju gbogbo rẹ lọ Aarẹ Nana Akufo-Addo ti ti wa a sọ pe gbogbo eto l’awọn ti n ṣe lati rii pe ipenija ati iṣoro naa dopin.
Akufo-Addo lo sọrọ naa nibi eto ayẹyẹ fun awọn olukọ Ghana lati fi sami ayẹyẹ awọn olukọ lagbaye, eyi to waye ni Takoradi.
Nibẹ lo ti sọ pe “a maa ro awọn olukọ lagbara lati rii pe wọn n ṣiṣẹ wọn nibi to rọrun, ati pe a maa pese awọn ohun amayedẹrun fun wọn.”
Kii ṣe igba akọkọ ree ti Aarẹ naa yoo maa ṣe ileri yii nita gbangba pe oun yoo yanju iṣoro ati ipenija to n doju kọ wọn.
Minisita fọrọ eto ẹkọ lorilẹ-ede Ghana, Ọmọwe Yaw Adutwum nibi eto ayẹyẹ naa ni igbayegbadun awọn olukọ jẹ ileeṣẹ naa logun gidi.
Ninu ọrọ rẹ lo ti sọ pe “o ti di dandan lati san owo fun awọn olukọ ti a ba gbe lọ si igberiko, a si maa ṣe e.”
Ṣugbọn nigba ti awọn naa n sọrọ lori awọn ileri wọnyi, ẹgbẹ awọn olukọ sọ pe ọrọ oṣelu lasan ni ijọba sọ, nitori pe awọn ko ni igbagbọ ninu ọrọ ti ijọba ba sọ.
Wọn ni o ti le ni ọdun mẹwaa ti ijọba ti n ṣe ileri fun awọn, ti wọn ko si tii muṣẹ titi di asiko yii.
Siwaju sii ni wọn jẹ ko di mimọ pe bi ijọba ko ba mu ileri rẹ ṣẹ fun awọn olukọ, awọn yoo ṣi maa japa lọ sibi ti igbe aye yoo ti dẹrun wọn.
Wọn ni koda, awọn to ṣi wa ni ile-ẹkọ awọn olukọ gan-an ti n gbgero ọna ti wọn yoo gba lati japa nigba ti wọn ba ṣetan.












