Kò sí ikú lójú mi, digbí ni mo wà láàyè - Gowon

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK/NTA
Olori ijọba ologun nigba kan ri lorilẹede Naijiria, Ọgagun fẹyinti, Yakubu Gowon ti kede pe oun ṣi wa laaye lẹyin ti iroyin kan jade lori ayelujara lọjọ Aje pe iku ti pa oju rẹ de.
Ọgagun Gowon ṣalaye ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ rẹ, Adeyeye Ajayi fi sita lalẹ ọjọ Aje, pe alaafia loun wa 'oun ko si kanju lọ si ibikibi."
Atẹjade naa ṣalaye siwaju sii pe: " ko si iku kankan loju Gowon ati pe alaafia ni Aarẹ ologun tẹlẹ wa."
Ki lawọn eekan ilu ni Naijiria n sọ nipa iroyin yii?
Bakan naa, oludije gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Social Democratic Party ninu eto idibo Gomina nipinlẹ Delta , Olorogun Gbagi naa wọgile iroyin ofege ọhun, to si fidi rẹ mulẹ pe saaka ni Gowon wa ninu alaafia.
Minisita fun eto ẹkọ tẹlẹri lorilẹede Niajiria ọhun, ninu atẹjade ti agbẹnusọ rẹ Orusi Kenneth buwọlu ni isẹ awọn eeyan kan bi ọta ni iroyin naa.
Gbagi ni Aarẹ ologun tẹlẹri wa ni niluu London, to si wa ni alaafia.
“Ọgagun Gowon wa pẹlu wa ni alaafia. Ko kanju lọ si ibi kankan
“Emi, Gbagi, sẹsẹ ba sọrọ ni. Mo fidi rẹ mulẹ pe iroyin ofege ni iroyin to kede pe iku ti pa ọrẹ mi, Ọgagun Gowon.
“Gowon ti ba gbogbo ọmọ Naijiria sọrọ pe oun si wa pẹlu wọn ninu alaafia. Gowon ko ku o.”















