Kélé òfin gbé arákùnrin tó lu ọlọ́pàá ní àlùbami ní'pínlẹ̀ Ondo

Oríṣun àwòrán, Others
Ọwọ ileeṣẹ Ọlọpaa ti tẹ arakunrin Ọlamilekan Afeez, ẹni ọgbọn ọdun ti wọn fi ẹsun kan wi pe o lu Ọlọpa kan n'ipinlẹ Ondo.
Ọkan lara awọn Ọlọpaa to n ṣiṣẹ ni agbegbe Okeigbo ni orita mẹta Jedi lo ṣiwọ lu lasiko ti ifanfa kan waye laarin wọn.
Alukoro ileeṣẹ Ọlọpaa n'ipinlẹ Ondo DSP Funmilayo Odunlami ṣe alaye fun BBC Yoruba pe wọn ti gbe arakunrin naa wa si ilu Akure lati Okeigbo ti rogbodiyan naa ti ṣẹlẹ ki wọn le beere ohun ti o ri l'ọbẹ ti o fi waro ọwọ lọwọ rẹ.
Fọnran iṣẹlẹ naa ti awọn eeyan ti n pin kaakiri ori ayelujara lati ọjọ Aiku ti iṣẹlẹ naa ti waye ṣe afihan bi Afeez ṣe digbaju lu Ọlọpaa naa lai bẹru ponpo to mu lọwọ nibi ti rogbodiyan naa ti waye.
Ileeṣẹ Ọlọpaa ipinlẹ Ondo fi kun ọrọ wọn wi pe ṣẹ iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa.
Saaju asiko yii, ọpọ ẹjọ ti awọn ọmọ orilẹede Naijiria maa n fi sun lori ayelujara ni bi awọn oṣiṣẹ ilẹẹṣẹ Ọlọpaa kan ṣe n ṣi agbara lo lasiko ti wọn ba wa lẹnu iṣẹ, ti nnkan ijagun si wa lọwọ wọn. Kodaa l'ọdun 2020, ifẹhonu awọn ọdọ tako iwa awọn Ọlọpaa kogberegbe, SARS, waye jakejado orilẹede Naijiria nitori ọwọ lile ti wọn fi n mu awọn ọdọ. Ọpọ ẹmi lo ṣofo nipasẹ ifẹhonuhan naa ki ohun gbogbo to rọlẹ.
Ko fi bẹẹ wọpọ ki a gbọ tabi ri ibi ti ẹnikan ti gbojugboya lati ṣiwọ lu Ọlọpaa to wọ aṣọ.
Bi iṣẹlẹ naa ṣe jẹ ohun ti ko fi bẹẹ wọpọ lo mu ki fọnran iṣẹlẹ naa di ohun ti awọn eeyan n pin kaakiri ori ayelujara.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post















