Wo àwọn gbèǹdéke béèlì tuntun tí ilé ẹjọ́ gbé kalẹ̀ fún Tani Olohun níbi ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ lónìí

Tani Ọlọhun ati aworan ileẹjọ

Agbẹjọro Tani-Ọlọhun, Ademọla Bank, lo kọ iwe kan si kootu pe ki wọn ba wọn ṣe agbeyẹwo beeli onibaara oun latari pe awọn ko le ri awọn ilana beeli ti ileẹjọ ni ki wọn lọọ wa mu ṣẹ.

O tẹsiwaju pe o ṣoro fun Tani Ọlọhun lati ri oniduro to jẹ olori agbegbe niluu Ilọrin, nitori pe ko si oniṣẹṣe ti yoo jẹ olori agbegbe kan niluu Ilọrin, eyi ni yoo jẹ ko ṣoro fun onibara oun.

Agbẹjọro Umar Saad Imam, to jẹ agbẹjọro fun olupẹjọ ko tako ẹbẹ naa, o sọ pe ominira olujẹjọ dun mọ awọn ninu nitoripe yoo fun un ni anfani lati ṣe awọn atunse ti awọn n beere.

Ninu idajọ rẹ, Onidajọ Sunday Adeniyi, gba si wọn lẹnu lori ẹbẹ naa

O fi kun un pe ọkan lara awọn oniduro rẹ gbọdọ tun ni ile tabi ilẹ to ni iwe ijọba niluu Ilọrin.

Bakan naa ni o ni ki Tani Ọlọhun mu iwe irinna rẹ wa si ileẹjọ, ti ko ba si ni iwe irinna, o ni o gbọdọ maa yọju si ileẹjọ ni gbogbo ọjọ Ẹti to kẹyin oṣu.

Lẹyin eyi lo sun igbẹjọ mi-in si ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹwaa, ọdun 2023 yii.

Iléẹjọ́ Upper Area yóò jókòó lónìí láti gbé ìlànà tuntun yèwò fún béèlì Tani Ọlọhun
Aworan Tani Olorun

Oríṣun àwòrán, Facebook/Tani Olorun

Ile ẹjọ Upper Area niluu Ilorin, lonii ọjọ Aje, ọjọ kẹsan-an, oṣu kẹwaa ọdun 2023, yoo tun gbọ ẹjọ gbajugbaja onisẹse ni, Abdulazeez Adegbọla ti ọpọ mọ si Tani Ọlọhun, lori awọn ilana beeli ati gbigba oniduro ti ile ẹjọ naa gbe kalẹ fun un.

Awọn ti ọrọ naa kan ko si tii rojutu si awọn ilana yii titi di akoko yii.

Ni ọsẹ to kọja ni Ademola Bank ti o jẹ olori agbẹjọro fun Tani-Ọlọhun sọ pe gbendeke to nira ni ile ẹjọ naa gbe kalẹ to si fihan gbangba pe awon ko le tẹle, ayafi ki ile ẹjọ tun gbe yẹwo.

Fun idi eyi, awọn agbẹjọro fun olupẹjọ ati olujẹjọ yoo pade ni iwaju Honourable Sunday Adeniyi ti o jẹ adajọ agba ile ẹjọ naa fun agbeyẹwo awon ilana ọhun.

Loni ni a o mo awọn ilana tuntun ti ile ẹjọ yoo tun gbe kalẹ boya yoo dẹ abi yoo tun yi bobo.