Ìlànà tó yi bóbó nílé ẹjọ́ fún wa lórí béèlì Tani Ọlọ́run, a kò leè rii - Agbẹjọ́rọ̀

Oríṣun àwòrán, Tani Olohun/bbc
Asaaju ikọ agbẹjọro fun Abdulazeez Adegbọla, ti ọpọ eeyan mọ si Tani Ọlọrun, Amofin Ademola Bank, ti fesi si awuyewuye to n lọ lọwọ lori pe ki onibara oun bẹ ikọ olupẹjọ tabi ki o ma bẹ wọn.
Nibi igbẹjọ to waye nile ẹjọ lọjọ Ẹti nile ẹjọ Upper Area nilu Ilorin ni amofin Bank ti sọ ero rẹ naa.
Ẹgbẹ Ogo Ilọrin ti o pe Tani Ọlọrun lẹjọ fun ẹsun ibanilorukọjẹ ati awọn agbẹjọro ẹgbẹ ọhun, ti sisọ loju rẹ pe awọn setan lati jami lori ẹjọ naa, ti olujẹjọ ba tọrọ aforiji, to si ko ọrọ rẹ jẹ.
"A ti fapa janu nile ẹjọ pe a ko le tẹle ilana beeli to le koko fun Tani Olorun, Adajọ seleri lati fun wa ni eyi to"
Amọ nigba to n fesi lori ibeere ikọ olupẹjọ naa, agbẹjọro fun olujẹjọ naa ni pipari aawọ naa nitunbi n nubi laarin awọn ti ọrọ kan jẹ eyi ti ile ẹjọ faramọ.
O fikun pe awon agbẹjọro naa ko lee tako igbesẹ ọhun nitori pe, ẹjọ ko gbọdọ ka awọn agbẹjọro lara ju awọn ẹlẹjọ lọ.
Ẹwẹ, Amofin Bank tun yan pe ti o ba di asiko ti wọn gbé awọn ilana kalẹ fun yiyanju aawọ naa nilana alaafia, Tani-Ọlọhun ati awọn ẹbi rẹ yoo gbe ilana naa yẹwo.
Bank ni awọn ilana naa gbọdọ jẹ eyi ti yoo ba igun mejeeji lara mu, ti onikaluku yoo si fi ayọ pada sile.
Agbẹjoro naa tun sọrọ lori gbendeke ti ile ẹjọ Upper Area gbe kalẹ fun gbigba beeli tabi oniduro fun Tani-Ọlọhun.
O salaye pe awọn ilana to rọ mọ beeli gbigba naa jẹ eyi to le gan, to sì soro lati ko ofin rẹ ja.
"Gbendeke to yi bobo ni ile ẹjọ gbekalẹ, to si fihan pe akole ko ofin rẹ ja, sugbon a ti n gbe igbesẹ ti ofin faye gba lati pada lọ si ile ẹjọ ni Ọjọru.
"Ile ẹjọ gbọ alaye wa, o si ni ki a pada wa ni ọjọ kẹsan-an osu yii, wi pe wọn yoo tun awọn ilana beeli gbe yẹwo.
Adajọ ni wọn yoo si tun fun wa ni gbendeke mii, ti o rọrun ju ti akọkọ lọ"
"Ko ba ofin mu bi Tani Olorun se n jẹjọ ni ọna meji nitori ẹjọ kan soso ni wọn pin siwaju adajọ meji"
Agbẹjọro naa tun salaye pe ohun ti ofin lodi si ni ki olujẹjọ kan maa jẹjọ kan naa ni ile ẹjọ meji.
"Ọrọ yii, ọkan naa ni, wọn kan ya a si ọna meji ni, se o wa yẹ ko ri bẹẹ?
Ofin ko si fi aye gba a, olujẹjọ kan, ẹjọ kan, niwaju adajọ meji, ko tọna.
"Eleyi jẹ ki ẹjọ naa ya ni lẹnu diẹ nitori o yatọ si ohun ti a ti n ri ninu ilana ofin tẹlẹ"
Tani Olohun tún padà sí ilé ẹjọ́ Májísírétì lónìí, lẹ́yìn àhámọ́ ọjọ́ 50 tí adájọ́ fún un
Gbajumọ agbẹsin iṣẹṣe ga, Abdulazeez Adegbọla ti ọpọ mọ si ‘Tani Ọlọhun’ yoo pada si ile ẹjọ loni ni itẹsiwaju igbẹjọ rẹ lori ẹsun ibanilorukọ jẹ ti wọn fi kan an.
Ọjọbọ lo pe aadọta ọjọ ti ile ẹjọ Majisireeti pasẹ ahamọ fun un ki igbẹjọ rẹ to le bẹrẹ.
Ti ẹ ko ba gbagbe, ọjọ kẹtadinlogun osu kẹsan an ọdun yii ni won kọkọ wọ olujẹjọ ọhun wa si iwaju, ile ẹjọ Majisireti kan ni ilu Ilọrin nibi ti adajọ Majisireti, Muhammed Ibrahim ti paṣẹ ki wọn fi si ahamọ fun aadọta ọjọ.
Lati igba naa ni awon agbẹjọro rẹ ti n pe fun orisirisi awon ẹbẹ ni Ile ẹjọ ọhun ati ni ile ẹjọ Upper Area ti wọn wọ olujẹjọ naa lọ fun ẹsun ibanilorukọ jẹ.
Ninu awon ẹbẹ ọhun ni, ẹbẹ fun beeli tabi oniduro, iwe atako si ofin ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Gbogbo awọn ẹbẹ ọhun ni ile ẹjọ mejeeji n wọgile titi di ọjọ kẹẹdọgbọn osu kẹẹsan an ti adajọ Sunday Adeniyi ti Upper Area fi fun un ni beeli pẹlu awọn gbendeke marun un kan.
Igbẹjọ yoo tẹsiwaju ni pẹrẹu lonii lori ẹsun ibanilorukọ jẹ ti wọn fi kan an.








