Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ OPC dá wàhálà sílẹ̀ níbi ayẹyẹ ọdún Ọlọ́jọ́, èèyàn mẹéjì kú, Ooni Ilé Ifẹ̀ faraya

Oríṣun àwòrán, others
Ọjọ Satide to kọja lajọyọ ajọdun Ọlọjọ nilu Ile Ifẹ eyi to jẹ kan pataki ninu ayẹyẹ iṣẹdalẹ ilẹ Yoruba ti wọn n ṣe nilu Ile Ifẹ.
Amọṣa, bi awọn eeyan ṣe n ṣe ọdun yii, ti wẹjẹwẹmu nlọ lapakan ni iro ibọn ṣadede sọ lagbegbe miran eyi to gbẹmi eeyan meji lọjọ naa.
Ohun ti BBC News Yoruba fidi rẹ mulẹ ni pe, awọn igun ọmọ ẹgbẹ Oodua Peoples’Congress, OPC kan ni wọn doju ija kọ ara wọn eyi to gbẹmi awọn meji naa.
Ohun ti a gbọ ni pe lasiko ti iro ibọn naa n dun, kabiyesi Ọba Adeyẹye Ogunwusi gan ti wa lori ijoko.
Awọn miran to ṣeṣe ninu ikọlu awọn ọmọ OPC naa la gbọ wi pe wọn wa nile iwosan bi a ṣe n sọrọ yii.
Awọn eeyan ti iṣẹlẹ naa ṣe oju wọn sọ fun akọroyin BBC NEWS YORUBA ni awọn igun ọmọ ẹgbẹ OPC ni wọn kọju ija sira wọn eyi to fi di boolọ yago funmi.
Ọmọ igun Fsṣeun lẹgbẹ OPC ni awọn meji ti wọn ku sinu ikọlu yii, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
Inu Ọọni ko dun si awọn to da omi alaafia ru nibi ọdun Ọlọjọ - Agbẹnusọ fun Ọọni

Oríṣun àwòrán, Ooni Adeyeye Enitan Babatunde Ogunwusi - Ojaja II
Agbẹnusọ fun Ọọni ile Ifẹ, Ọtunba Moses Ọlafare ṣalaye pe iṣẹlẹ naa jẹ eyi to ku diẹ kaato ti ko si dun mọ Ọọni ile Ifẹ funrarẹ ninu.
O ni iyalẹnu gba a lo jẹ fun gbogbo eeyan nigba ti wọn ri awọn igun naa ti wọn bẹrẹ si ni doju ibọn kọ ara wọn.
O fidi rẹ mulẹ pẹlu pe awọn ọmọ igun meji kan lẹgbẹ OPC ni ilu Ile Ifẹ ni
O ni ihuwasi awọn ọmọ ẹgbẹ OPC naa ko dun mọ Ọọni ninu gẹgẹbi o ṣe woye pe bawo ni awọn eeyan ti wọn n sọ pe awọn n ja fun idagbasoke ilẹ Yoruba yoo ṣe padi ọrẹ da maa da omi alafia ru nibi ajọyọ ọkan lara awọn ajọdun to lamilaaka julọ nilẹ Yoruba.
Iwadii ti bẹrẹ - Ileeṣẹ ọlọpaa
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọsun ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ to fa iku eeyan meji nibi ayẹyẹ ọdun Ọlọjọ tí ó wáyé lọjọ Abamẹta tó kọjá.
Alukoro awọn Ọlọpaa Ìpínlẹ̀ Osun Arábìnrin Yemisi Opalola fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ pe èèyàn Meji lo pàdánù ẹ̀mí wọn lasiko ìkọlù na.
Agbenusọ fún ilé ìṣe Ọlọpa ni ipinlẹ Yemisi Opalola sọ pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ OPC ni wọn kojú ìjà sí ara wọn.
Opalola tun sọ nínú ọ̀rọ̀ rẹ pe àwọn ènìyàn méjì tí o farapa làkókò ìṣẹ̀lẹ̀ náà ń gbá ìtọ́jú lọ́wọ́ ni Ilé-ìwòsàn.
Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ, Komisana ọlọ́pàá ìpínlè náà tí pàṣẹ pé kí wọn ìwádìí ohùn tó fà ìṣẹ̀lẹ̀ ìjà tó bẹ silẹ láàárín àwọn ọmọ ẹgbẹ́ OPC, tí ó sì rọ àwọn aráàlú pé kí wọn máse fòyà, kí wọ́n sì ma bá ìṣe ojo wọn lọ pẹ̀lú ifọkanbalẹ pe ìwádìí ń lọ lọ́wọ́ lori ìṣẹ̀lẹ̀ na.












