DPO àtàwọn ọlọ́pàá míì fara gbọta níbí aáwọ̀ tó tún bẹ́ sílẹ̀ láàrin Ifon àti Ilobu l'Osun

Rogbodiyan to n ṣẹlẹ laarin Ilobu ati Ifon nipinlẹ Osun tun bẹyin yọ lẹyin ti DPO ọlọpaa atawọn akẹgbẹ rẹ fara gbọta nigba ti aawọ mii tun bẹ silẹ ni Ọjọrọ.
O ti to bi ọjọ mẹta tawọn eeyan ilu mejeeji ti n ba ara wọn ja lori ilẹ.
Iroyin fidi rẹ mulẹ pe ọpọ ile niluu mejeeji ni wọn ti dana sun, koda wọn sun ọkọ ọlọpaa bakan naa.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun, Yemisi Opalola ṣalaye pe DPO agọ ọlọpaa to wa ni ilu kan lara ilu mejeeji fara gba ọta, nigba tawọn ọlọipaa mẹrin mii si n gba itọju lọwọ nile iwosan lẹyin tawọn naa fara gbọta.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa fidi rẹ mulẹ pe awọn eeyan kan lo lọ gẹgun de awọn ọlọpaa to n lọ pẹtu sija nibẹ ti wọn si ṣina ibọn fun wọn.
Opalola ni ‘’wọn ti dana sun ọkọ ọlọpaa tuntun, ọwọ ni wọn si ti yinbọn fun DPO ọlọpaa.
Oun naa si wa ni ile iwosan nibi ti o ti n gba itọju.
Ohun ti awọn eeyan ti iṣẹlẹ ọhun ṣoju wọn sọ ni pe aawọ bẹ silẹ ni Ọjọru nigba ti iroyin kan gbalẹ pe awọn eeyan Ilobu ti gbẹmi ẹnikan ni Ifon.
Lẹyin naa ni a gbọ pe awọn ara Ilobu naa ko oriṣiriiṣi ohun ija oloro ti wọn si lọ kọju ija si awọn eeyan Ifon.
Iroyin kan tiẹ sọ pe ko din ni eeyan meji to ba iṣẹlẹ naa lọ nigba ti ọpọ eeyan si ti sa kuro ni ilu ti wọn si ti morile awọn ilu to sun mọ bii Osogbo, Ilajue, Erin-Osun, Agunbelewo atawọn ilu mii lagbegbe.
Ijọba Osun gba ilẹ ti Ifon ati Ilobu n ja si
Ẹwẹ, gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke ti sẹ ipade pọ pẹlu awọ ẹṣọ eleto abo atawọn adari ilu Ifon ati Ilobu lati wa ojutuu si aawọ to n ṣẹlẹ laarin ilu mejeeji.
Iroyin kan tun fidi rẹ mulẹ pe gomina Adeleke ni ijọba ipinlẹ Osun ti gba ilẹ tawọn ilu mejeeji n ja le lori.
Gomina ipinlẹ Osun sọ ninu ‘’ipade imọlẹ’’ naa to waye niluu Osogbo pe igbesẹ yii ṣe pataki ki asọyepọ le waye laarin gbogbo eeyan tọrọ kan.
Bakan naa ni gomina ipinlẹ Osun sọ pe olori ọmogun oriilẹ, Ọgagun Taoreed Lagbaja ti ṣeleri pe gbogbo awọn to wa nidi aawọ yii ni yoo jẹ iyan wọn ni iṣu.
‘’Awọn ẹṣọ eleto abo yoo da ṣeria fun ẹnikẹni to ba tun fẹ da rogbodiyan silẹ.
Mi o le maa wo kawọn kan maa fẹmi awọn eeyan mi ṣofo.
Ẹnikẹni ti a ba ri ni ori ilẹ ti a n sọrọ rẹ yii yoo dara rẹ lẹbi,’’ Adeleke lo sọ bẹẹ.
Gomina ipinlẹ Osun wa kepe awọn ọba nipinlẹ naa lati kilọ fawọn eeyan wọn.
Bakan naa ni gomina tun fidi rẹ mulẹ pe ofin konle o gbele ti ijọba kede si wa sibẹ.












