Àwọn akọrin ìjọ CAC gba ìtúsílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ajínigbe ní ìpínlẹ̀ Ondo

Aworan ijọ ati ọkọ bọọsi

Awọn akọrin ijọ CAC Oke-Igan nilu Akure nipinlẹ Ondo to ku sọdọ awọn ajinigbe lo ti gba itusilẹ.

Awọn ajinigbe ji awọn akọrin naa gbe lagbegbe Ẹlẹgbẹka nijọba ibilẹ Ọsẹ lọjọ Ẹti to kọja.

Ibi isinku obi aluduru ijọ naa ni wọn n lọ ki awọn agbebọn o too dawọn lọna ti wọn si ko awọn mọkandinlogun to wa ninu ọkọ ijọ naa lọ.

Ẹwẹ, mẹjọ ninu wọn moribọ loru ọjọ naa mọju to si ku awọn mọkanla.

Owurọ ọjọ Abamẹta lawọn ajinigbe naa pe alufaa ijọ, Benjamin Akanmu, lati beere fun aadọta miliọnu naira owo idande.

Lati ọjọ naa ni awọn agbofinro ti bẹrẹ iṣẹ takuntakun lati le doola ẹmi awọn mọkanla naa.

Ni nkan bii aago mọkanla alẹ Ọjọbọ ni iroyin jade pe awọn ajinigbe ọun ti tu awọn mọkanla naa silẹ, ti wọn si pada de ijọ wọn nilu Akure ni nkan bii aago mejila oru.

Alufaa Akanmu ṣalaye fun BBC News Yoruba wi pe awọn ajinigbe ọun lo fi awọn mọkanla to ku naa silẹ ki wọn maa lọle layọ.

Se awọn ajinigbe naa gba owo fun itusilẹ awọn akọrin naa?

Aworan ṣọọṣi naa

Lakoko to n fesi si ibeere boya wọn san aadọta miliọnu tawọn agbebọn naa beere fun, Alufaa Akanmu wi pe “ẹ jẹ ka ṣaa maa dupẹ pe wọn pada sile layọ. Ẹ jẹ ka mẹnu kuro nibi ọrọ owo.

“Kii ṣe pe awọn ọlọpaa ko ṣe iṣẹ wọn, amọ awọn ajinigbe lo tu wọn silẹ funra wọn.

“Nigba ti wọn de, a rii wipe wọn ti jẹya lọdọ awọn ajinigbe naa ti ara wọn ko si mokun mọ.

“Aago mejila geerege ni wọn de sinu ijọ nibi, a si ti ko awọn mọkanla naa lọ ile iwosan lati aago kan oru ki wọn le gba itọju to peye ti ara wọn yoo fi mokun pada.”

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Funmilayo Odunlami-Omisanya, jẹri sii pe ni tootọ ni awọn ti wọn jigbe naa ti gbominira amọ oun ko le sọ ni pato boya wọn san owo itusilẹ.

Awọn mọkanla naa ni wọn lo ọjọ meje lakata awọn ajinigbe ki wọn to ri idande.