Kàyéèfì! Joseph ṣàdédé yọ sí ìlú padà lẹ́yìn ọdún 50 ‘tó jáde láyé’

Oríṣun àwòrán, NAIROBI NEWS
Ọmọ ọgbọn ọdun ni Joseph jẹ nigba to kuro nile rẹ to wa ni Riva ni Homa Bay lọdun 1972.
Lati nkan bi aadọta ọdun sẹyìn to kuro nile ọjọ kẹrinla oṣu yi l'awọn mọlẹbi ṣẹṣẹ mọ idi to fi kuro nile pẹlu bo ṣe pada de ni ẹni ọdun mọkanlelọgọrin.
Ileeṣẹ iroyin Daily Nation jabọ pe nigba to pada o ri pe gbogbo dukia rẹ to fi mọ eyi t'awọn obi rẹ fun l'awọn mọlẹbi ti pin tori pe wọn ro pe o ti ku.
O ni idi ti oun fi kuro nile fun aadọta ọdun le ni lati ma ba koju ogun idile.
Odongo to wa lati abule Osir Komollo sọ pe ilu Mombasa loun wa ní gbogbo asiko t'awọn mọlẹbi n daamu wa.
O ni ọdọ eeyan kan loun n gbe níbẹ.
"Emi ni mo n mojuto ile naa ti nkan si n rọsọmu fun mi ju igba ti mo wa nile lọ"
Awọn to wa nile ti ọjọ ori wọn ti kọja ọgọta ọdun ko daamọ.
Oun paapa kọju sí awọn Agbaagba ilu to si beere ìbí ti ile rẹ wa.
Odongo loun pinnu lati fi3 ilu silẹ lẹyin ede aiyede laarin oun ati Ibatan rẹ kan ẹni to ti papoda bayii.
O ní lasiko ede aiyede yi l'awọn kan ku ninu ẹbi ti wọn si sọ pe ẹgbọn Odingo lọwọ ninu iku wọn.
Odongo loun sa nile ki wọn ma ba gbẹsan lara oun.
O pinnu lati tẹdo sí ibi to jinna si abule ti wọn bi si ki o ma ba rọrun fawọn mọlẹbi lati sawari rẹ.
Ibode Sikri lo dagbere pe oun n lọ ti ko jinna púpọ si ile wọn.
Mọlẹbi ro pe ko ni pẹ de ni titi ti oṣù fi n di àìmọye ọdun to kuro nile.
Nigba wọn o gburo rẹ ti wọn o sí mọ ibi o wa ni mọlẹbi ba kede iku re.

Oríṣun àwòrán, Nation Media
Daudi Oketch to jẹ alabagbe rẹ sọ pe n'ise l'awọn ara abule rẹ kan sọ pe ọọni lo paa jẹ.
"Adagun omi lo dagbere pe oun lo.Eyi lo mu ka pada ro pe ọọni ti sekupa"
Ana rẹ yi to jẹ ẹni aadọrin ọdun sọ pe tijo tayọ ni ẹbi fi ki kaabọ ki wọn to pe ará abule lati wa bawọn yayọ apejẹ.
O sọ fun wọn pe ilu Mombasa loun wa ní gbogbo ọdun yi.
O ni aye rọrun ni Mombasa debi pe oun gbagbe gbogbo inira to wa ni Homa Bay.
O ní aimọye igba ni ẹni to gba oun sile yoo lọ Irinajo ti yoo sí fi oun nikan sile.
"Kete to wa si mi lọkan lati pada síle, abẹrẹ to kere bayi mi o mu kuro níbẹ to fi mọ owo oṣù iṣẹ ti mo ṣe k'ẹyin"
Iyawo ati ọmọ nkọ?

Oríṣun àwòrán, Nation Media
Ni gbogbo ọdun to lo Odongo kọ pada fẹ iyawo t'ohun ti pe o wu lọkan lati bímọ tori ko bímọ nile to ti kuro ṣaaju.
O ni oun ni lọkan ṣugbọn bi aarun AIDS se gbode lo mu ki oun pinnu lati da nikan wa.
Amọ Ọgbẹni Odongo fi ẹdun ọkan han lori bi wọn ṣe gba dukia rẹ to si ni oun ko fẹ pada si Mombasa amọ oun fẹ gba nkan ini oun pada.
Baalẹ abule wọn sọ pe "O yẹ ki mọlẹbi rẹ baa wa iyawo ki o ma ba da nikan gbe.Ko si ọna ijẹ ati mu fun tori naa gbogbo ọna lo ye ki wọn fí ṣe iranwọ fun un"












