Ó ní ìdí tí mo fi ní kí wọ́n sin òkú ọmọ mi ní kíákíá, Bàbá Mohbad ṣàlàyé
Ó ní ìdí tí mo fi ní kí wọ́n sin òkú ọmọ mi ní kíákíá, Bàbá Mohbad ṣàlàyé

Oríṣun àwòrán, BBC/other
Kii ṣe iroyin mọ pe gbajumọ akọrin takasufe ni, IleriOluwa Aloba ti ọpọ mọ si Mohbad jade laye ati pe iku rẹ ti fa ọpọlọpọ ariyanjiyan kaakiri agbaye.
Amọṣa ohun ti ọpọlọpọ n kọ haahin le lori ni bi wọn ṣe ku giri sin oku rẹ niwọn igba ti awọn to sun mọ ọ mọ pe oniruru okunkun lo ṣu yi iku rẹ ka.
Baba Mohbad, Alagba Joseph Alọba ṣalaye fun BBC ninu ifọrọwerọ yii idi to fi ni ki wọn tete lọ gbe oku rẹ sin.
Alagba Alọba ṣalaye pe aitete ri iwe aṣẹ lori iku Mohbad gba lọdọ awọn ọlọpaa ti ko si si idi fun oun lati gbe oku ọfọ bẹẹ lọ pamọ si ile igbokupamọsi Mọṣuari lo mu ki oun ni ki wọn lọ sin oku rẹ lẹsẹkẹsẹ.






