A kò fìgbà kankan fi Mohbad sí àhámọ́ – NDLEA sí iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá

Oríṣun àwòrán, Instagram/iamMohbad
Ajọ NDLEA ti fesi fun ẹsun ti ileeṣẹ Ọlọpaa fi kan wọn lori ohun to ṣekupa gbajugbaja olorin takasufe, Ilerioluwa Aloba, pe ajọ oun ko figba kankan fi si ahamọ lasiko to wa laye.
Fọnran kan to wa lori ayelujara lo safihan Mohbad lori ibusun nile iwosan, to si ni awọn osisẹ NDLEA fun oun ni nnkan mu, eyi to ni o gba odi lọ lara oun.
Agbẹnusọ fun NDLEA, Femi Babafemi, ninu atẹjade to fi lede salaye pe ajọ ọhun ko fi igba kankan mu Mohbad si ahamọ dipo pe wọn yoo fun ni nnkan mu.
O ni “A wa naa gbọ si ẹsun ti ko ni idaniloju lori ayelujara pe Ilerioluwa Aloba ti ọpọ mọ si Mohbad, fẹsun kan ajọ NDLEA pe o mu oun, ti wọn si ti oun mọle lọjọ kẹrinlelogun, oṣu Keji, ọdun 2022, pe wọn si fun oun ni nnkan lati mu.
“Sugbọn ni idahun si ẹsun yii, a fẹ jẹ ko di mimọ pe a ko mu Mohbad rara; bẹẹni ko ṣun atimọle NDLEA ni ọjọ ti wọn sọ tabi eyikeyi ọjọ miiran ṣaaju tabi lẹyin akoko naa.
“Ki n se lọdọ wa ni o ti mu ohun to ni o mu’’.
Babafemi tun ṣalaye pe ọrọ kan ti Komisona ọlọpa ni Ipinle Eko, Idowu Owohunwa, sọ pe awọn ọlọpasi n reti esi lati ọdọ NDLEA lori iwadii wọn lati mọ ohun to sekupa olorin naa, pe awọn ko ti fọhun si ibeere ọlọpaa lati ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹsan an, 2023.
Ninu lẹta kan to jade ni ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹsan, ti igbakeji alakoso gbogbogbo fun ẹka 'Narcotics' ni NDLEA, Josephine Obi buwọlu fun awọn akọroyin, NDLEA ṣe alaye lẹkunrẹrẹ fun ileesẹ ọlọpaa pe wọn ko mu Mohbad tabi fi si atimole.
Babafemi ṣafikun pe “ Lẹyin ọpọlọpọ awọn ibeere lọdọ awọn akọroyin lori ọrọ ti ileesẹ ọlọpaa ipinle Eko sọ pe awọn ko tii gbọ esi kankan lati ọdọ NDLEA lori fọnran kan ti oloogbe ti fẹsun kan wa lori ayelujara."
"Ileesẹ wa yoo fẹ lati ṣalaye pe nitootọ, ti fesi ranṣẹ si ileesẹ ọlọpaa lati Ọjọbọ, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹsan, ọdun 2023.
A ṣì ń retí èsì àyẹ̀wò òkú Mohbad - Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá

Oríṣun àwòrán, Instagram/iamMohbad, Lagos Police command
Ileeṣẹ Ọlọpaa ipinlẹ Eko ti jẹ ko di mimọ pe awọn si n retí esi ayẹwo Autopsy ti wọn ṣe lati mọ ohun to sekupa pa gbajugbaja olorin takasufe, Ilerioluwa Aloba, tí ọpọ eeyan mọ si Mohbad.
Mohbad, ẹni to jade laye lọjọ Kejila oṣu Kẹsan an ní ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn, ti ipapoda rẹ si da ọpọlọpọ awuyewuye silẹ, eyi to jẹ ki ileeṣẹ Ọlọpaa hu oku rẹ jade fun ayẹwo.
Bakan naa ni Ileeṣẹ Ọlọpaa tí ransẹ pe awọn afurasi lori iku olorin naa lati le tan imọlẹ si iwadii wọn.
Kọmisana fun ileeṣẹ Ọlọpaa nipinlẹ Eko, Idown Owohunwa ni esi ayẹwo naa ko ti jade.
"Lẹyin tí a gbe igbimọ kalẹ lọjọ kọkanlelogun oṣu Kẹsan an, a hu oku naa sita, ti a si ṣe ayẹwo lẹsẹ ẹsẹ.
"Gbogbo ohun tí a fi ṣe ayẹwo ni ti fi ransẹ ile iwosan, ti a si n duro de esi.
"Bakan naa ni a n duro de esi lati ọdọ ajọ NDLEA lori fọnran kan to lori ayelujara ni bi ti oloogbe ti fẹsun kan wọn lọdun 2022."
Kọmisana jẹ ko di mimọ pe diduro esi ayẹwo Autopsy ko da iwadii duro ati pe igbimọ iwadii ti fi ẹri silẹ lati ṣe iranlọwọ fun iwadii.
"Bi a ń ṣe duro de esi ayẹwo Autopsy, a ti ṣe awọn iwadii kan silẹ lati ṣe iranlọwọ fun ayẹwo naa
O wa jẹ ko dimọ pe Ileeṣẹ Ọlọpaa yoo gbe gbogbo igbesẹ lati fidi otitọ mulẹ ninu iwadi wọn












