Wo ìdí tí Stoneman Willy ṣe ń wọ káà ilẹ̀ sùn lẹ́yìn ọdún 128 tó jáde láyé

Oríṣun àwòrán, Stoneman Willy
Ile isinku kan niluu Pennsyvania, nilẹ Amẹrika ti kede pe awọn ti mọ orukọ oloogbe kan to jẹ ole nigba aye rẹ amọ ti apẹle rẹ n jẹ "Stoneman Willie.”
"Stoneman Willie” jẹ ọkan lara awọn oku gbigbẹ to pẹ julọ ninu itan ilẹ Amẹrika, eyii ti wọn n ṣafihan rẹ gẹgẹ bii iṣẹ ọna niluu reading.
Iroyin ni ṣe ni wọn ṣeṣi sọ oku rẹ di oku gbigbẹ lọdun 1895 ki awọn oṣiṣẹ ile igbokusi naa le gbe oku naa fun awọn mọlẹbi rẹ.
Ṣaaju iku rẹ, orukẹ ofege lo fi silẹ lagọ ọlọpaa lẹyin ti wọn fi ọwọ ofin mu u, lẹyin naa lo dagbare faye ni ahamọ lẹyin aisan kidinrin to n ba finra tẹlẹ.
To n tumọ si pe ọlopaa ko mọ orukọ abisọ rẹ, bẹẹni wọn ko mọ ẹni pato to jẹ.
Olori awọn oṣiṣẹ ile isinku naa, Kyle Blankenbiller, ṣalaye pe gbogbo igbiyanju awọn lati mọ irufẹ ẹni ti "Stoneman Willie” jẹ lo ja si pabo.
Amọ awọn eeyan agbegbe ibi ti ile isiniku naa wa ti ṣetan lati ṣe ẹyẹ ikẹyin fun un bayii.
Ogunlọgọ eeyan kaakiri agbegbe naa lo ti n ṣabẹwo si ọhun naa wa lati foju ganni oku ‘Willie’ latari pe ọjọ isinku rẹ naa tun ni ayajọ ajọdun ọlọdọdun ti wọn maa n ṣe ninu ilu naa.
Bi wọn ṣe sọ oku ‘Willie’ di oku gbigbẹ fun opọ ọdun
Blankenbiller ṣalaye pe ṣe ni wọn ṣeṣi sọ oku naa di oku gbigbẹ latari pe ile igbokusi to ṣiṣẹ ọhun lo kọja iye iwọn awọn kẹmika to yẹ ki wọn lo.
O ni lẹyin oṣu mẹfa ni oku naa ti gbẹ lai gbe sinu yinyin.
Lara awọn ilana ti wọn fi n sọ oku di gbigbẹ lai gbe sinu yinyin nilẹ Egupt laye atijọ ni ki wọn yọ opọlọ, ifun ati ẹdọforo to wa ninu rẹ, lẹyin naa ni wọn yoo gbe sinu iyọ titi ti yoo fi gbẹ.
Awọn ilana wọnyii kii jẹ ki oku jẹra fun ọpọ ọdun, bẹẹ si ni awọ kokoro aifojuri ko ni wọ inu rẹ.












